Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Revenge

75 ẹsẹ · 32 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Lẹ́yìn ọjọ́ kẹta, nígbà tí gbogbo wọn sì wà nínú ìrora. Àwọn ọmọ Jakọbu méjì, Simeoni àti Lefi tí ó jẹ́ ẹ̀gbọ́n fún Dina, sì mú idà wọn pẹ̀lú ìgboyà, wọ́n sì pa gbogbo ọkùnrin ìlú náà.

  2. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ gbẹ̀san: má sì ṣe bínú sí èyíkéyìí nínú àwọn ènìyàn rẹ. Ṣùgbọ́n, kí ìwọ kí ó fẹ́ ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ. Èmi ni Olúwa.

  3. Samsoni sọ fún un pé, “Nítorí pé ẹ̀yin ṣe èyí, èmi ó gbẹ̀san lára yín, lẹ́yìn náà èmi yóò sì dẹ́kun.”

  4. Ó kọlù wọ́n pẹ̀lú ìbínú àti agbára ńlá, ó sì pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wọn. Lẹ́yìn náà ni ó lọ, ó sì dúró nínú ihò àpáta kan nínú àpáta Etamu.

  5. Nígbà náà ni Samsoni ké pe Olúwa wí pé, “Olúwa Olódùmarè, rántí mi. Háà Ọlọ́run jọ̀wọ́ fi agbára fún mi lẹ́ẹ̀kan yìí sí i, kí èmi lè gbẹ̀san lára àwọn Filistini nítorí àwọn ojú mi méjèèjì.”

  6. Samsoni sì na ọwọ́ mú àwọn òpó méjèèjì tí ó wà láàrín gbùngbùn, orí àwọn tí tẹmpili náà dúró lé, ó fi ọwọ́ ọ̀tún mú ọ̀kan àti ọwọ́ òsì mú èkejì, ó fi ara tì wọ́n,

  7. Samsoni sì wí pé, “Jẹ́ kí èmi kú pẹ̀lú àwọn Filistini!” Òun sì fi agbára ńlá tì wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni ilé náà wó lu àwọn ìjòyè àti gbogbo àwọn tí ó wà nínú rẹ̀. Báyìí ni ó pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ nígbà ikú rẹ̀ ju ìgbà ayé rẹ̀ lọ.

  8. Wò ó, ojú rẹ́ rí i lónìí, bí Olúwa ti fi ìwọ lé mi lọ́wọ́ lónìí nínú ihò, àwọn kan ní kí èmi ó pa ọ, ṣùgbọ́n èmi dá ọ sí, ‘Èmi sì wí pé, èmi kì yóò nawọ́ mi sí olúwa mi, nítorí pé ẹni àmì òróró Olúwa ni òun jẹ́.’

  9. Ó sì wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀, ó wí pé, “Olúwa mi, fi ẹ̀ṣẹ̀ yìí yá mi: kí ó sì jẹ́ kí ìránṣẹ́bìnrin rẹ, èmi bẹ̀ ọ́, sọ̀rọ̀ létí rẹ, kí ó sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́bìnrin rẹ.

  10. Olúwa mi, èmi bẹ̀ ọ́ má ka ọkùnrin Beliali yìí sí, àní Nabali. Nítorí pé bí orúkọ rẹ̀ ti jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni òun náà rí. Nabali ni orúkọ rẹ̀, àìmoye si wà pẹ̀lú rẹ̀; ṣùgbọ́n èmi ìránṣẹ́bìnrin rẹ kò ri àwọn ọmọkùnrin olúwa mi, ti ìwọ rán.

  11. Ǹjẹ́ olúwa mi, bi Olúwa ti wà láààyè, àti bí ẹ̀mí rẹ̀ si ti wà láààyè, bi Olúwa sì ti dá ọ dúró láti wá ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, àti láti fi ọwọ́ ara rẹ gba ẹ̀san; ǹjẹ́, kí àwọn ọ̀tá rẹ, àti àwọn ẹni tí ń gbèrò ibi sí olúwa mi rí bi i Nabali.

  12. Ǹjẹ́ èyí ni ẹ̀bùn tí ìránṣẹ́bìnrin rẹ mú wá fún olúwa mi, jẹ́ kí a sì fi fún àwọn ọmọkùnrin ti ń tọ olúwa mi lẹ́yìn.

  13. “Èmi bẹ̀ ọ́, fi ìrékọjá arábìnrin rẹ jìn ín, nítorí Olúwa yóò sá ṣe ilé òdodo fún olúwa mi, nítorí pé ó ja ogun Olúwa. Nítorí náà kí a má ri ibi kan ni ọwọ́ rẹ níwọ̀n ìgbà tí ó wà láààyè.

  14. Bí ọkùnrin kan bá sì dìde láti máa lépa rẹ, àti máa wá ẹ̀mí rẹ, a ó sì di ẹ̀mí olúwa mi nínú ìdì ìyè lọ́dọ̀ Olúwa Ọlọ́run rẹ; àti ẹ̀mí àwọn ọ̀tá rẹ ni a ó sì gbọ̀n sọnù gẹ́gẹ́ bí kànnàkànnà jáde.

  15. Yóò sì ṣe, Olúwa yóò ṣe sí olúwa mi gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìre tí ó ti wí nípa tirẹ̀, yóò sì yàn ọ́ ni aláṣẹ lórí Israẹli.

  16. Èyí kì yóò sì jásí ìbànújẹ́ fún ọ, tàbí ìbànújẹ́ ọkàn fún olúwa mi, nítorí pé ìwọ ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀, tàbí pé olúwa mi gba ẹ̀san fún ara rẹ̀, ṣùgbọ́n nígbà tí Olúwa ba ṣe oore fún olúwa mi, ǹjẹ́ rántí ìránṣẹ́bìnrin rẹ!”

  17. Dafidi sì wí fún Abigaili pé, “Alábùkún fún ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli, tí ó rán ọ lónìí yìí láti pàdé mi.

  18. Ìbùkún ni fún ọgbọ́n rẹ, alábùkún sì ni ìwọ, tí ó da mi dúró lónìí yìí láti wá ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, àti láti fi ọwọ́ mi gba ẹ̀san fún ara mi.

  19. Dafidi sì wí fún Abiṣai pé, “Má ṣe pa á nítorí pé ta ni lè na ọwọ́ rẹ̀ sí ẹni àmì òróró Olúwa kí ó sì wà láìjẹ̀bi?”

  20. Abneri sì padà sí Hebroni, Joabu sì bá a tẹ̀ láàrín ojú ọ̀nà láti bá a sọ̀rọ̀ ní àlàáfíà, ó sì gún un níbẹ̀ lábẹ́ inú, ó sì kú, nítorí ẹ̀jẹ̀ Asaheli arákùnrin rẹ̀.

  21. Ó sì ṣe, lẹ́yìn ọdún méjì, Absalomu sì ní olùrẹ́run àgùntàn ní Baali-Hasori, èyí tí ó gbé Efraimu, Absalomu sì pe gbogbo àwọn ọmọ ọba.

  22. Absalomu sì tọ ọba wá, ó sì wí pé, “Wò ó, jọ̀wọ́, ìránṣẹ́ rẹ ní olùrẹ́run àgùntàn, èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ọba, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bá ìránṣẹ́ rẹ lọ.”

  23. Ọba sì wí fún Absalomu pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ, ọmọ mi, mo bẹ̀ ọ́, má ṣe jẹ́ kí gbogbo wa lọ, kí a má bá à mú ọ náwó púpọ̀.” Ó sì rọ̀ ọ́ gidigidi, ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ lọ, òun sì súre fún un.

  24. Absalomu sì wí pé, “Bí kò bá le rí bẹ́ẹ̀, èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí Amnoni ẹ̀gbọ́n mi bá wa lọ.” Ọba sì wí pé, “Ìdí rẹ̀ tí yóò fi bá ọ lọ.”

  25. Absalomu sì rọ̀ ọ́, òun sì jẹ́ kí Amnoni àti gbogbo àwọn ọmọ ọba bá a lọ.