Skip to content

Herod

23 ẹsẹ · 5 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Herod

  1. Ní àkókò náà ni Herodu ọba tetrarki gbọ́ nípa òkìkí Jesu,

  2. Nísinsin yìí Herodu ti mú Johanu, ó fi ẹ̀wọ̀n dè é, ó sì fi sínú túbú, nítorí Herodia aya Filipi arákùnrin rẹ̀,

  3. Ní ọjọ́ àsè ìrántí ọjọ́ ìbí Herodu, ọmọ Herodia obìnrin jó dáradára, ó sì tẹ́ Herodu lọ́run gidigidi.

  4. Láìpẹ́, ọba Herodu gbọ́ nípa Jesu, nítorí níbi gbogbo ni a ti ń sọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìyanu rẹ̀. Ọba náà rò pé, “Johanu Onítẹ̀bọmi jíǹde kúrò nínú òkú, nítorí náà ni iṣẹ́ ìyanu ṣe ń ṣe láti ọwọ́ rẹ.”

  5. Ṣùgbọ́n nígbà tí Herodu gbọ́ èyí, ó wí pé “Johanu tí mo tí bẹ́ lórí ni ó ti jíǹde kúrò nínú òkú.”

  6. Herodu fúnra rẹ̀ sá ti ránṣẹ́ mú Johanu, tìkára rẹ̀ sínú túbú nítorí Herodia aya Filipi arákùnrin rẹ̀ nítorí tí ó fi ṣe aya.

  7. Johanu sì ti wí fún Herodu pé, “Kò tọ́ sí ọ láti fi ìyàwó arákùnrin rẹ ṣe aya.”

  8. Nítorí Herodu bẹ̀rù Johanu, ó sì mọ̀ ọ́n ni olóòtítọ́ ènìyàn àti ẹni mímọ́, ó sì ń tọ́jú rẹ̀. Nígbà tí Herodu ba gbọ́rọ̀ Johanu, ó máa ń dààmú síbẹ̀, ó sì fi ayọ̀ gbọ́rọ̀ rẹ̀.

  9. Níkẹyìn Herodia rí ààyè. Àkókò yìí ni ọjọ́ ìbí Herodu, òun sì pèsè àsè ní ààfin ọba fún àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀: àwọn balógun àti àwọn ènìyàn pàtàkì ní Galili.

  10. Nígbà náà, ni ọmọbìnrin Herodia wọlé láti jó. Inú Herodu àti àwọn àlejò rẹ̀ dùn tó bẹ́ẹ̀. Ọba sọ fún ọmọbìnrin náà pé, “Béèrè ohunkóhun tí ìwọ bá fẹ́ lọ́wọ́ mi, èmi ó sì fi fún ọ.”

  11. Bí wọ́n sì ti ń rékọjá, Jesu kìlọ̀ fún wọn pé, “Ẹ máa ṣọ́ra nítorí ìwúkàrà àwọn Farisi àti ìwúkàrà Herodu.”

  12. Ní ọdún kẹ́ẹ̀dógún ìjọba Tiberiu Kesari, nígbà tí Pọntiu Pilatu jẹ́ baálẹ̀ Judea, tí Herodu sì jẹ́ tetrarki Galili, Filipi arákùnrin rẹ̀ sì jẹ́ tetrarki Iturea àti ti Trakoniti, Lisania sì jẹ́ tetrarki Abilene,

  13. Ṣùgbọ́n nígbà ti Johanu bú Herodu tetrarki, tí ó bá wí nítorí Herodia aya Filipi arákùnrin rẹ̀, àti nítorí ohun búburú gbogbo tí Herodu tí ṣe,

  14. Herodu tetrarki gbọ́ nǹkan gbogbo èyí tí a ṣe láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá: ó sì dààmú, nítorí tí àwọn ẹlòmíràn ń wí pé, Johanu ni ó jíǹde kúrò nínú òkú,

  15. Herodu sì wí pé, “Johanu ni mo ti bẹ́ lórí, ṣùgbọ́n ta ni èyí tí èmi ń gbọ́ irú nǹkan wọ̀nyí sí?” Ó sì ń fẹ́ láti rí i.

  16. Ní wákàtí kan náà, díẹ̀ nínú àwọn Farisi tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Jáde, kí ìwọ sì lọ kúrò níhìn-ín yìí: nítorí Herodu ń fẹ́ pa ọ́.”

  17. Nígbà tí ó sì mọ̀ pé ará ilẹ̀ abẹ́ àṣẹ Herodu ni, ó rán an sí Herodu, ẹni tí òun tìkára rẹ̀ wà ní Jerusalẹmu ní àkókò náà.

  18. Nígbà tí Herodu, sì rí Jesu, ó yọ̀ gidigidi; nítorí tí ó ti ń fẹ́ rí i pẹ́ ó sá à ti ń gbọ́ ìròyìn púpọ̀ nítorí rẹ̀; ó sì ń retí láti rí i kí iṣẹ́ àmì díẹ̀ ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe.

  19. Àti Herodu pẹ̀lú àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, wọ́n kẹ́gàn rẹ̀, wọ́n sì ń fi í ṣẹ̀sín, wọ́n wọ̀ ọ́ ní aṣọ dáradára, ó sì rán an padà tọ Pilatu lọ.

  20. Pilatu àti Herodu di ọ̀rẹ́ ara wọn ní ọjọ́ náà, nítorí látijọ́ ọ̀tá ara wọn ni wọ́n ti jẹ́ rí.

  21. Àti Herodu pẹ̀lú; ó sá rán an padà tọ̀ wá wá; sì kíyèsi i, ohun kan tí ó yẹ sí ikú ni a kò ṣe láti ọwọ́ rẹ̀.

  22. Àní nítòótọ́ ní Herodu àti Pọntiu Pilatu, pẹ̀lú àwọn aláìkọlà àti àwọn ènìyàn Israẹli kó ara wọn jọ ní ìlú yìí láti dìtẹ̀ sí Jesu Ìránṣẹ́ mímọ́ rẹ, ẹni tí ìwọ ti fi àmì òróró yàn,

  23. Àwọn wòlíì àti àwọn olùkọ́ni sì ń bẹ nínú ìjọ ti ó wà ni Antioku; Barnaba àti Simeoni tí a ń pè ni Nigeri, àti Lukiu ará Kirene, àti Manaeni (ẹni tí a tọ́ pọ̀ pẹ̀lú Herodu tetrarki) àti Saulu.