Fò sí àkóónú

circa 1446–1406 BC

The Wilderness Years

Forty years of wandering in the desert test Israel's faith and prepare a new generation to enter the promised land.

2,247 ẹsẹ · 2 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Numeri 10:17nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni wọ́n sọ tabanaku kalẹ̀ àwọn ọmọ Gerṣoni àti Merari tó gbé àgọ́ sì gbéra.

  2. Numeri 10:18nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Àwọn ìpín ti ibùdó ti Reubeni ló gbéra tẹ̀lé wọn, lábẹ́ ọ̀págun wọn. Elisuri ọmọ Ṣedeuri ni ọ̀gágun wọn.

  3. Numeri 10:19nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai ni ọ̀gágun ti ẹ̀yà Simeoni.

  4. Numeri 10:20nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Eliasafu ọmọ Deueli ni ọ̀gágun ìpín ti ẹ̀yà Gadi.

  5. Numeri 10:21nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni àwọn ọmọ Kohati tí ń ru ohun mímọ́ náà gbéra. Àwọn ti àkọ́kọ́ yóò sì ti gbé tabanaku dúró kí wọn tó dé.

  6. Numeri 10:22nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Àwọn ìpín tó wà ní ibùdó Efraimu ló tún kàn lábẹ́ ọ̀págun wọn. Eliṣama ọmọ Ammihudu ni ọ̀gágun wọn.

  7. Numeri 10:23nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Gamalieli ọmọ Pedasuri ni ọ̀gágun ìpín ti ẹ̀yà Manase.

  8. Numeri 10:24nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Abidani ọmọ Gideoni ni ọ̀gágun ìpín ti ẹ̀yà Benjamini.

  9. Numeri 10:25nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Lákòótan, àwọn ọmọ-ogun tó ń mójútó ẹ̀yìn ló tún kàn, àwọn ni ìpín ti ibùdó Dani lábẹ́ ọ̀págun wọn. Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai ni ọ̀gágun wọn.

  10. Numeri 10:26nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Pagieli ọmọ Okanri ni ìpín ti ẹ̀yà Aṣeri,

  11. Numeri 10:27nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ahira ọmọ Enani ni ọ̀gágun ti ẹ̀yà Naftali.

  12. Numeri 10:28nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Báyìí ni àwọn ọmọ Israẹli ṣe tò jáde gẹ́gẹ́ bí ogun nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò wọn.

  13. Numeri 10:29nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Mose sì sọ fún Hobabu ọmọ Reueli ará Midiani tí í ṣe àna rẹ̀ pé, “A ń gbéra láti lọ sí ibi tí Olúwa sọ pé, ‘Èmi ó fi fún un yín.’ Bá wa lọ, àwa ó ṣe ọ́ dáradára nítorí pé Olúwa ti ṣèlérí ohun rere fún Israẹli.”

  14. Numeri 10:30nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ó sì dáhùn pé, “Rárá, èmi kò ní bá yín lọ, mò ń padà lọ sí ilẹ̀ mi àti sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn mi.”

  15. Numeri 10:31nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Mose sì sọ pé, “Jọ̀wọ́ ma fi wá sílẹ̀, ìwọ mọ ibi tí a lè pa ibùdó sí nínú aginjù, ìwọ yóò sì jẹ́ ojú fún wa.

  16. Numeri 10:32nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Bí o bá bá wa lọ, a ó sì pín fún ọ nínú ohun rere yówù tí Olúwa bá fún wa.”

  17. Numeri 10:33nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Wọ́n sì gbéra láti orí òkè Olúwa ní ìrìn ọjọ́ mẹ́ta. Àpótí ẹ̀rí Olúwa ń lọ níwájú wọn fún gbogbo ọjọ́ mẹ́ta yìí láti wá ibi ìsinmi fún wọn.

  18. Numeri 10:34nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Ìkùùkuu Olúwa wà lórí wọn lọ́sàn nígbà tí wọ́n gbéra kúrò ní ibùdó.

  19. Numeri 10:35nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Nígbàkígbà tí àpótí ẹ̀rí bá gbéra Mose yóò sì wí pé, “Dìde, Olúwa! Kí a tú àwọn ọ̀tá rẹ ká, kí àwọn tí ó kórìíra rẹ sì sálọ níwájú rẹ.”

  20. Numeri 10:36nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Nígbàkígbà tí àpótí ẹ̀rí bá sinmi yóò wí pé, “Padà, Olúwa, sọ́dọ̀ àwọn àìmoye ẹgbẹẹgbẹ̀rún Israẹli.”

  21. Numeri 11:1nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Àwọn ènìyàn ń ṣe àròyé nípa wàhálà wọn sí etí ìgbọ́ Olúwa. Ìbínú Olúwa sì ru sókè nígbà tí ó gbọ́ àròyé yìí. Nígbà náà ni iná jáde láti ọ̀dọ̀ Olúwa bọ́ sí àárín wọn, ó sì run àwọn tó wà ní òpin ibùdó.

  22. Numeri 11:2nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni àwọn ènìyàn kígbe sí Mose, Mose sì gbàdúrà sí Olúwa iná náà sì kú.

  23. Numeri 11:3nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Wọ́n sì ń pe ibẹ̀ ní Tabera nítorí pé, iná láti ọ̀dọ̀ Olúwa jó láàrín wọn.

  24. Numeri 11:4nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn aláìníláárí tó wà láàrín àwọn ọmọ Israẹli pẹ̀lú ọkàn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn fi ìtara béèrè fún oúnjẹ mìíràn, àwọn ọmọ Israẹli náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í sọkún wí pé, “Bí i pé kí á rí ẹran jẹ báyìí!

  25. Numeri 11:5nǹkan bí 1490 ṣáájú Kristi

    Àwa rántí ẹja tí à ń jẹ lọ́fẹ̀ẹ́ ní Ejibiti, apálà, bàrà, ewébẹ̀, àlùbọ́sà àti àwọn ẹ̀fọ́ mìíràn.