- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 1380–1050 BC
The Judges & Ruth
Israel cycles through rebellion, oppression, and rescue under charismatic leaders—culminating in Ruth's faithful love story.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Onidajọ 18:17nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi
Àwọn ọkùnrin márùn-ún tí wọ́n lọ yọ́ ilẹ̀ náà wò wọlé lọ wọ́n sì kó ère gbígbẹ́ náà, efodu náà, àwọn òrìṣà ìdílé àti ère dídà náà nígbà tí àlùfáà náà àti àwọn ẹgbẹ̀ta (600) ọkùnrin tí ó hámọ́ra ogun dúró ní à bá wọ ẹnu odi náà.
- Onidajọ 18:18nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi
Nígbà tí àwọn ọkùnrin yìí wọ ilé e Mika lọ tí wọ́n sì kó ère fínfín náà, efodu náà, àwọn òrìṣà ìdílé mìíràn àti ère dídà náà, àlùfáà náà béèrè lọ́wọ́ wọn wí pé, “Kí ni ẹ̀yin ń ṣe?”
- Onidajọ 18:19nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi
Wọ́n dá a lóhùn pé, “Dákẹ́! Ma sọ nǹkan kan, tẹ̀lé wa kí o sì di baba àti àlùfáà wa. Kò ha sàn fún ọ láti máa ṣe ìránṣẹ́ ẹ̀yà àti ìdílé kan tí ó wá láti Israẹli bí àlùfáà ju ilé ẹnìkan ṣoṣo lọ?”
- Onidajọ 18:20nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni inú àlùfáà náà sì dùn, òun mú efodu náà, àwọn òrìṣà ìdílé mìíràn àti ère fínfín náà, ó sì bá àwọn ènìyàn náà lọ.
- Onidajọ 18:21nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi
Wọ́n kó àwọn ọmọdé wọn, àwọn ohun ọ̀sìn wọn àti gbogbo ohun ìní wọn síwájú, wọ́n yípadà wọ́n sì lọ.
- Onidajọ 18:22nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi
Nígbà tí wọ́n ti rìn jìnnà díẹ̀ sí ilé Mika, àwọn ọkùnrin tí ó wà ní agbègbè Mika kó ara wọn jọ, wọ́n sì lé àwọn ará Dani bá.
- Onidajọ 18:23nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi
Bí wọ́n ṣe ń pariwo tẹ̀lé wọn lẹ́yìn, àwọn ará Dani yípadà wọ́n sì bi Mika pé, “Kí ló ṣe ọ́ tí o fi pe àwọn ọkùnrin rẹ jáde láti jà?”
- Onidajọ 18:24nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi
Ó dáhùn pé, “Ẹ̀yin kó àwọn ère tí mo ṣe, àti àlùfáà mi lọ. Kí ni ó kù tí mo ní? Báwo ni ẹ̀yin ò ṣe béèrè pé, ‘Kí ló ṣe ọ́?’ ”
- Onidajọ 18:25nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi
Àwọn ọkùnrin Dani náà dáhùn pé, “Má ṣe bá wa jiyàn, tàbí àwọn oníbìínú fùfù ènìyàn lè kọlù yín, ìwọ àti àwọn ìdílé yóò sì sọ ẹ̀mí yín nù.”
- Onidajọ 18:26nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi
Àwọn ọkùnrin Dani náà sì bá ọ̀nà wọn lọ. Nígbà tí Mika rí í pé wọ́n lágbára púpọ̀ fún òun, ó sì padà sí ilé rẹ̀.
- Onidajọ 18:27nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi
Wọ́n sì kó àwọn ohun tí Mika ti ṣe àti àlùfáà rẹ̀, wọ́n sì kọjá lọ sí Laiṣi, ní ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí ó ní ìbàlẹ̀ ọkàn tí wọ́n sì wà ní àlàáfíà. Wọ́n fi ojú idà kọlù wọ́n, wọ́n sì jó ìlú wọn run.
- Onidajọ 18:28nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi
Kò sì sí ẹnikẹ́ni tí yóò gbà wọ́n sílẹ̀ nítorí pé ibi tí wọ́n ń gbé jìnà sí àwọn ará Sidoni, wọn kò sì ní àṣepọ̀ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni. Ìlú náà wà ní inú àfonífojì lẹ́bàá a Beti-Rehobu. Àwọn ará Dani sì tún ìlú náà kọ́, wọ́n sì ń gbé inú rẹ̀.
- Onidajọ 18:29nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi
Wọ́n sọ orúkọ ìlú náà ní Dani gẹ́gẹ́ bí orúkọ baba ńlá wọn Dani, ẹni tí wọ́n bí fún Israẹli: bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Laiṣi ni orúkọ ìlú náà tẹ́lẹ̀ rí.
- Onidajọ 18:30nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi
Àwọn ọmọ Dani sì gbé àwọn ère kalẹ̀ fún ara wọn níbẹ̀; Jonatani ọmọ Gerṣomu, ọmọ Mose, àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni àlùfáà fún àwọn ẹ̀yà Dani títí di àkókò tí a kó ilẹ̀ náà ní ìgbèkùn.
- Onidajọ 18:31nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi
Wọ́n tẹ̀síwájú láti lo àwọn ère tí Mika ṣe, ní gbogbo àkókò tí ilé Ọlọ́run wà ní Ṣilo.
- Onidajọ 19:1nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi
Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì Israẹli kò ní ọba. Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Lefi tí ń gbé ibi tí ó sá pamọ́ nínú àwọn agbègbè òkè Efraimu, mú àlè kan láti Bẹtilẹhẹmu ní Juda.
- Onidajọ 19:2nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n àlè rẹ̀ náà sì ṣe panṣágà sí i, òun fi sílẹ̀, ó sì padà lọ sí ilé baba rẹ̀ ní Bẹtilẹhẹmu ti Juda, ó sì wà ní ibẹ̀ ní ìwọ̀n oṣù mẹ́rin,
- Onidajọ 19:3nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi
ọkọ rẹ̀ lọ sí ibẹ̀ láti rọ̀ ọ́ pé kí ó padà sí ọ̀dọ̀ òun. Nígbà tí ó ń lọ ó mú ìránṣẹ́ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ méjì lọ́wọ́, obìnrin náà mú un wọ inú ilé baba rẹ̀ lọ, nígbà tí baba obìnrin náà rí i ó fi tayọ̀tayọ̀ gbà á.
- Onidajọ 19:4nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi
Àna rẹ̀, baba ọmọbìnrin náà rọ̀ ọ́, ó sì borí rẹ̀ láti dá a dúró fún ìgbà díẹ̀, òun sì dúró fún ọjọ́ mẹ́ta, ó ń jẹ, ó ń mu, ó sì ń sùn níbẹ̀.
- Onidajọ 19:5nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi
Ní ọjọ́ kẹrin, wọ́n dìde ní òwúrọ̀ kùtùkùtù òun sì múra láti padà lọ, ṣùgbọ́n baba ọmọbìnrin náà wí fún àna rẹ̀ pé, “Fi ohun jíjẹ díẹ̀ gbé inú ró nígbà náà kí ìwọ máa lọ.”
- Onidajọ 19:6nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi
Àwọn méjèèjì sì jùmọ̀ jókòó láti jọ jẹun àti láti jọ mu. Lẹ́yìn èyí ni baba ọmọbìnrin wí pé, “Jọ̀wọ́ dúró ní alẹ́ yìí kí o sì gbádùn ara rẹ.”
- Onidajọ 19:7nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi
Nígbà tí ọkùnrin náà dìde láti máa lọ, baba ìyàwó rẹ̀ rọ̀ ọ́, torí náà ó sùn níbẹ̀ ní alẹ́ ọjọ́ náà.
- Onidajọ 19:8nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi
Ní òwúrọ̀ ọjọ́ karùn-ún nígbà tí ó dìde láti lọ, baba ọmọbìnrin wí pé, “Fi oúnjẹ gbé ara ró. Dúró de ọ̀sán!” Àwọn méjèèjì sì jùmọ̀ jọ jẹun.
- Onidajọ 19:9nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi
Nígbà tí ọkùnrin náà, pẹ̀lú àlè àti ìránṣẹ́ rẹ̀, dìde láti máa lọ, àna rẹ̀, baba ọmọbìnrin náà ní, “Wò ó ilẹ̀ ti ń ṣú lọ, dúró níbí, ọjọ́ ti lọ. Dúró kí o sì gbádùn ara rẹ. Ìwọ lè jí ní àárọ̀ kùtùkùtù ọ̀la kí ìwọ sì máa lọ ilé.”
- Onidajọ 19:10nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n nítorí pé òun kò fẹ́ dúró mọ́ níbẹ̀ ní òru náà ọkùnrin náà kúrò ó sì gba ọ̀nà Jebusi: ọ̀nà Jerusalẹmu pẹ̀lú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ méjèèjì tí ó fi dì í ní gàárì àti àlè rẹ̀.