Fò sí àkóónú

circa 1380–1050 BC

The Judges & Ruth

Israel cycles through rebellion, oppression, and rescue under charismatic leaders—culminating in Ruth's faithful love story.

703 ẹsẹ · 2 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Onidajọ 20:6nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi

    Mo mú àlè mi náà, mo sì gé e sí ekìrí ekìrí, mo sì fi ekìrí kọ̀ọ̀kan ránṣẹ́ sí agbègbè ìní Israẹli kọ̀ọ̀kan, nítorí pé wọ́n ti ṣe ohun tí ó jẹ́ èèwọ̀ àti ohun ìtìjú yìí ní ilẹ̀ Israẹli.

  2. Onidajọ 20:7nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi

    Nísinsin yìí, gbogbo ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ sọ ìmọ̀ràn yín, kí ẹ sì ṣe ìdájọ́ yín.”

  3. Onidajọ 20:8nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi

    Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì dìde bí ẹnìkan pẹ̀lú gbólóhùn kan wí pé, “Kò sí ẹnikẹ́ni nínú wa tí yóò lọ sí àgọ́ rẹ̀. Rárá o, kò sí ẹyọ ẹnìkan tí yóò padà lọ sí ilé rẹ̀.

  4. Onidajọ 20:9nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ohun tí àwa yóò ṣe sí Gibeah ní yìí. Àwa yóò lọ kọlù ú bí ìbò bá ṣe darí wa.

  5. Onidajọ 20:10nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi

    A yóò mú ọkùnrin mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn-ún nínú gbogbo ẹ̀yà Israẹli àti ọgọ́rùn-ún láti inú ẹgbẹ̀rún (1,000) kan àti ẹgbẹ̀rún kan láti inú ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) láti máa pèsè oúnjẹ fún àwọn ọmọ-ogun. Yóò sì ṣe nígbà tí àwọn jagunjagun bá dé Gibeah ti àwọn ará Benjamini, wọn yóò fún wọn ní ohun tí ó bá tọ́ sí wọn fún gbogbo ìwà búburú àti ìwà ìtìjú tí wọ́n ṣe yìí ní ilẹ̀ Israẹli.”

  6. Onidajọ 20:11nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi

    Báyìí ni gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli parapọ̀ ṣọ̀kan bí ọkùnrin kan ṣoṣo wọ́n sì dìde sí ìlú náà.

  7. Onidajọ 20:12nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi

    Àwọn ẹ̀yà Israẹli rán àwọn ọkùnrin sí gbogbo ẹ̀yà Benjamini wí pé, “Kí ni ẹ̀rí sí ìwà búburú yìí tí ó ṣẹlẹ̀ ní àárín yín?

  8. Onidajọ 20:13nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà ẹ mú àwọn ẹni ibi ti Gibeah yìí wá fún wa, kí àwa lé pa, kí a sì fọ ìṣe búburú yìí mọ́ kúrò ní Israẹli.” Ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀yà Benjamini kò fetí sí ti àwọn arákùnrin wọn ọmọ Israẹli.

  9. Onidajọ 20:14nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi

    Àwọn ẹ̀yà Benjamini sì kó ara wọn jọ láti àwọn ìlú wọn sí Gibeah láti bá àwọn ọmọ Israẹli jà.

  10. Onidajọ 20:15nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi

    Ní ẹsẹ̀kẹsẹ̀ àwọn ará Benjamini kó ẹgbàá mẹ́tàlá (26,000) àwọn ọmọ-ogun tí ń lọ dájọ́ láti àwọn ìlú wọn, yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (700) àṣàyàn ọkùnrin nínú àwọn tí ń gbé Gibeah.

  11. Onidajọ 20:16nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi

    Ní àárín àwọn ọmọ-ogun wọ̀nyí ni ó ti ní àwọn ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (700) àṣàyàn ọkùnrin tí wọ́n ń lo ọwọ́ òsì, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn dára dé bi pé wọ́n lè fi kànnàkànnà ba fọ́nrán òwú ní àìtàsé (wọ́n jẹ́ atamọ́tàsé).

  12. Onidajọ 20:17nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọkùnrin Israẹli, yàtọ̀ sí àwọn ará Benjamini, ka ogún ọ̀kẹ́ (400,000) àwọn tí ń fi idà jagun, gbogbo wọn jẹ́ akọni ní ogun jíjà.

  13. Onidajọ 20:18nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọ Israẹli lọ sí Beteli, wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run. Wọ́n wí pé, “Ta ni nínú wa tí yóò kọ́ kojú àwọn ará Benjamini láti bá wọn jà?” Olúwa dáhùn pé, “Juda ni yóò kọ́ lọ.”

  14. Onidajọ 20:19nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọ Israẹli dìde ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, wọ́n sì dó ti Gibeah (wọ́n tẹ̀gùn sí ẹ̀bá Gibeah).

  15. Onidajọ 20:20nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọkùnrin Israẹli jáde lọ láti bá àwọn ará Benjamini jà wọ́n sì dúró ní ipò ogun sí wọn ní Gibeah.

  16. Onidajọ 20:21nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọ Benjamini sì jáde láti Gibeah wá wọ́n sì pa àwọn ọmọ ẹgbẹ̀rún méjìlélógún (22,000) ọkùnrin nínú àwọn ọmọ Israẹli ní ojú ogun ní ọjọ́ náà.

  17. Onidajọ 20:22nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Israẹli mú ara wọn lọ́kàn le, wọ́n sì tún dúró sí ipò wọn ní ibi tí wọ́n dúró sí ní ọjọ́ àkọ́kọ́.

  18. Onidajọ 20:23nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọ Israẹli sì lọ wọ́n sọkún ní iwájú Olúwa títí oòrùn fi wọ̀, wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ Olúwa. Wọ́n ni, “Ṣé kí àwa tún gòkè lọ kí a sì bá àwọn ará Benjamini arákùnrin wa jà?” Olúwa dáhùn pé, “Lọ bá wọn jà.”

  19. Onidajọ 20:24nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọ Israẹli sì tún súnmọ́ tòsí àwọn ará Benjamini ní ọjọ́ kejì.

  20. Onidajọ 20:25nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi

    Ní ọjọ́ yìí nígbà tí ará Benjamini jáde sí wọn láti Gibeah, láti dojúkọ wọn, wọ́n pa ẹgbàá mẹ́sàn (18,000) ọkùnrin Israẹli, gbogbo wọn jẹ́ jagunjagun tí ń lo idà.

  21. Onidajọ 20:26nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni gbogbo àwọn ọmọ Israẹli àní gbogbo àwọn ènìyàn, gòkè lọ sí Beteli, níbẹ̀ ni wọ́n jókòó tí wọ́n sì ń sọkún níwájú Olúwa. Wọ́n gbààwẹ̀ ní ọjọ́ náà títí di àṣálẹ́, wọ́n sì rú ọrẹ ẹbọ sísun àti ọrẹ àlàáfíà sí Olúwa.

  22. Onidajọ 20:27nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọ Israẹli sì béèrè lọ́wọ́ Olúwa. (Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run wà níbẹ̀,

  23. Onidajọ 20:28nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi

    Finehasi ọmọ Eleasari ọmọ Aaroni, ní ń ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ ní iwájú rẹ̀.) wọ́n béèrè pé, “Ṣe àwa tún le lọ sí ogun pẹ̀lú Benjamini arákùnrin wa tàbí kí a má lọ?” Olúwa dáhùn pé, “Ẹ lọ nítorí ní ọ̀la ni èmi yóò fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́.”

  24. Onidajọ 20:29nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọ Israẹli sì yàn àwọn ènìyàn tí ó sá pamọ́ yí Gibeah ká.

  25. Onidajọ 20:30nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi

    Wọ́n jáde tọ àwọn ọmọ Benjamini lọ ní ọjọ́ kẹta wọ́n sì dúró ní ipò wọn, wọ́n sì dìde ogun sí Gibeah bí wọ́n ti ṣe tẹ́lẹ̀ rí.