- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 1380–1050 BC
The Judges & Ruth
Israel cycles through rebellion, oppression, and rescue under charismatic leaders—culminating in Ruth's faithful love story.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Onidajọ 17:5nǹkan bí 1419 ṣáájú Kristi
Ọkùnrin náà, Mika sì ní ojúbọ kan. Òun sì ra ẹ̀wù efodu kan, ó sì ṣe àwọn ère kan, ó sì fi ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin ṣe àlùfáà rẹ̀.
- Onidajọ 17:6nǹkan bí 1419 ṣáájú Kristi
Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àwọn ọmọ Israẹli kò ní ọba; olúkúlùkù ṣe bí ó ti rò pé ó tọ́ ní ojú ara rẹ́.
- Onidajọ 17:7nǹkan bí 1419 ṣáájú Kristi
Ọ̀dọ́mọkùnrin kan sì ti Bẹtilẹhẹmu ti Juda wá, tí í ṣe ìdílé Juda, ẹni tí í ṣe ẹ̀yà Lefi, òun sì ṣe àtìpó níbẹ̀,
- Onidajọ 17:8nǹkan bí 1419 ṣáájú Kristi
ọkùnrin náà sì ti ìlú Bẹtilẹhẹmu ti Juda lọ, láti ṣe àtìpó ní ibikíbi tí ó bá rí. Ní ojú ọ̀nà àjò rẹ̀, ó dé ilẹ̀ Mika nínú àwọn ilẹ̀ òkè Efraimu.
- Onidajọ 17:9nǹkan bí 1419 ṣáájú Kristi
Mika bi í pé, “Níbo ni ó ti ń bọ̀?” Ó dáhùn pé, “Ọmọ Lefi ni mí láti Bẹtilẹhẹmu Juda, mo sì ń wá ibi tí èmi yóò máa gbé.”
- Onidajọ 17:10nǹkan bí 1419 ṣáájú Kristi
Mika sì sọ fún un wí pé, “Dúró lọ́dọ̀ mi kí ìwọ sì jẹ́ baba mi àti àlùfáà fún mi, èmi ó sì máa fún ọ ní ṣékélì mẹ́wàá fàdákà ní ọdọọdún, pẹ̀lú aṣọ àti oúnjẹ rẹ̀.”
- Onidajọ 17:11nǹkan bí 1419 ṣáájú Kristi
Ọmọ Lefi náà sì gbà láti máa bá a gbé, ọ̀dọ́mọkùnrin náà sì dàbí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀.
- Onidajọ 17:12nǹkan bí 1419 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni Mika ya ará Lefi náà sí mímọ́, ọ̀dọ́mọkùnrin náà sì di àlùfáà rẹ̀, ó sì ń gbé ilé rẹ̀.
- Onidajọ 17:13nǹkan bí 1419 ṣáájú Kristi
Mika sì wí pé, “Báyìí, èmi mọ̀ pé Olúwa yóò ṣe mi ní oore nítorí pé mo ní ọmọ Lefi ní àlùfáà mi.”
- Onidajọ 18:1nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi
Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àwọn ọmọ Israẹli kò ní ọba. Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àwọn ẹ̀yà Dani ń wá ilẹ̀ tiwọn, níbi tí wọn yóò máa gbé, nítorí pé títí di àkókò náà wọn kò ì tí ì pín ogún ilẹ̀ fún wọn ní ìní láàrín àwọn ọmọ Israẹli.
- Onidajọ 18:2nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi
Nítorí náà àwọn ẹ̀yà Dani rán àwọn jagunjagun márùn-ún lọ láti Sora àti Eṣtaoli láti yọ́ ilẹ̀ náà wò àti láti rìn ín wò. Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣe ojú fún gbogbo àwọn ẹ̀yà wọn. Wọ́n wí fún wọn pé, “Ẹ lọ kí ẹ rin ilẹ̀ náà ká, kí ẹ sì wò ó fínní fínní.” Àwọn ọkùnrin náà wọ àwọn ìlú tí ó wà ní agbègbè òkè Efraimu, wọ́n sì dé ilé Mika, níbi tí wọ́n sùn ní òru náà.
- Onidajọ 18:3nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi
Nígbà tí wọ́n súnmọ́ tòsí ilé e Mika, wọ́n dá ohùn ọ̀dọ́mọkùnrin Lefi náà mọ̀, torí náà wọ́n yípadà, wọ́n sì wọ inú ilé náà lọ wọ́n sì bi í pé, “Tá ni ó mú ọ wa sí ibi? Kí ni ìwọ ń ṣe níhìn-ín yìí? Èéṣe tí o fi wà ní ibí?”
- Onidajọ 18:4nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi
Ó sọ ohun tí Mika ti ṣe fún un, ó fi kún un fún wọn pé, “Ó gbà mí sí iṣẹ́, èmi sì ni àlùfáà rẹ̀.”
- Onidajọ 18:5nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi
Wọ́n wí fún un pé, “Jọ̀wọ́ béèrè ní ọwọ́ Ọlọ́run, kí àwa lè mọ̀ bí ìrìnàjò wa yóò yọrí sí rere.”
- Onidajọ 18:6nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi
Àlùfáà náà dá wọn lóhùn pé, “Ẹ máa lọ ní àlàáfíà. Ìrìnàjò yín tí ẹ̀yin ń rìn bá ojúrere Olúwa pàdé.”
- Onidajọ 18:7nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi
Àwọn ọkùnrin márààrún náà kúrò, wọ́n sì wá sí Laiṣi, níbi tí wọ́n ti rí i pé àwọn ènìyàn tí ń gbé ibẹ̀ ní ààbò, bí àwọn ará Sidoni, láìsí ìfòyà àti ní ìpamọ́. Ní ìgbà tí ilẹ̀ wọn kò ṣe aláìní ohunkóhun, wọ́n ní ọrọ̀ púpọ̀. Ibùgbé wọn tún jìnnà sí ti àwọn ará Sidoni, wọn kò fi ohunkóhun bá ẹnikẹ́ni dàpọ̀.
- Onidajọ 18:8nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi
Nígbà tí wọ́n padà sí Sora àti Eṣtaoli, àwọn arákùnrin wọn bi wọ́n léèrè pé, “Báwo ni ibi tí ẹ lọ ti rí? Kí ni ìròyìn tí ẹ mú wá?”
- Onidajọ 18:9nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi
Wọ́n dáhùn pé, “Ẹ dìde ẹ jẹ́ kí a lọ kọlù wọ́n! A wá rí i pé ilẹ̀ náà dára gidigidi. Ṣé ẹ̀yin ó sì jókòó láìsí nǹkan nípa rẹ̀? Ẹ má ṣe lọ́ra láti lọ síbẹ̀ kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà.
- Onidajọ 18:10nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi
Nígbà tí ẹ̀yin bá dé ibẹ̀, ẹ yóò rí àwọn ènìyàn tí ọkàn wọn balẹ̀ àti ilẹ̀ tí ó tẹ́jú tí Ọlọ́run ti fi fún yín, ilẹ̀ tí kò ṣe aláìní nǹkan kan.”
- Onidajọ 18:11nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni ẹgbẹ̀ta (600) ọkùnrin tí ó múra ogun láti ìran Dani, jáde lọ láti Sora àti Eṣtaoli ní mímú ra láti jagun.
- Onidajọ 18:12nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi
Wọ́n sì jáde lọ, ní ojú ọ̀nà wọn, wọ́n tẹ̀dó ogun sí ẹ̀bá Kiriati-Jearimu ní Juda. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń gbé ìwọ̀-oòrùn Kiriati-Jearimu ni Mahane-Dani títí di òní yìí.
- Onidajọ 18:13nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi
Láti ibẹ̀ wọ́n kọjá lọ sí àwọn ìlú agbègbè òkè Efraimu, wọ́n sì dé ilé Mika.
- Onidajọ 18:14nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin márùn-ún tí ó lọ yọ́ ilẹ̀ Laiṣi wò sọ fún àwọn arákùnrin wọn pé, “Ǹjẹ́ ẹ̀yin mọ̀ pé ọ̀kan nínú àwọn ilé yìí ní ẹ̀wù efodu, àwọn yòókù ní òrìṣà, ère gbígbẹ́ àti ère dídà? Ẹ mọ ohun tí ó yẹ kí ẹ ṣe báyìí.”
- Onidajọ 18:15nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi
Wọ́n sì yà sí ibẹ̀, wọ́n sì wọ ilé ọ̀dọ́mọkùnrin Lefi náà, sí ilé Mika, wọ́n sì béèrè àlàáfíà rẹ̀.
- Onidajọ 18:16nǹkan bí 1406 ṣáájú Kristi
Àwọn ẹgbẹ̀ta (600) ọkùnrin ará Dani náà tí ó hámọ́ra ogun, dúró ní àbáwọlé ẹnu odi.