- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 800–400 BC
The Hebrew Prophets
God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Isaiah 33:1nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Ègbé ni fún ọ, ìwọ apanirun, ìwọ tí a kò tí ì parun! Ègbé ni fún ọ, ìwọ ọ̀dàlẹ̀, ìwọ tí a kò tí ì dà ọ́! Nígbà tí o bá dẹ́kun à ń pa ni run; a ó pa ìwọ náà run, nígbà tí o bá dẹ́kun à ń dani, a ó da ìwọ náà.
- Isaiah 33:2nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Olúwa ṣàánú fún wa àwa ń ṣàfẹ́rí i rẹ. Máa jẹ́ agbára wa ní òròòwúrọ̀ ìgbàlà wa ní àsìkò ìpọ́njú.
- Isaiah 33:3nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Ní ìkérara ohùn rẹ, àwọn ènìyàn sá, nígbà tí o dìde sókè, àwọn orílẹ̀-èdè fọ́nká.
- Isaiah 33:4nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Ìkógun rẹ, ìwọ orílẹ̀-èdè ni a kórè gẹ́gẹ́ bí i ti ọ̀dọ́ eṣú; gẹ́gẹ́ bí àkójọpọ̀ eṣú, àwọn ènìyàn wọ ibẹ̀.
- Isaiah 33:5nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
A gbé Olúwa ga, nítorí pé ó ń gbé ibi gíga, Òun yóò kún Sioni pẹ̀lú ẹ̀tọ́ àti òdodo.
- Isaiah 33:6nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Òun yóò jẹ́ ìpìlẹ̀ tí ó dájú fún àkókò rẹ ibùjókòó ìgbàlà kíkún àti ọgbọ́n òun ìmọ̀; ìbẹ̀rù Olúwa ni kọ́kọ́rọ́ sí ìṣúra yìí.
- Isaiah 33:7nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Wò ó, àwọn onígboyà ọkùnrin wọn pohùnréré ẹkún ní òpópónà; àwọn ikọ̀ àlàáfíà sọkún kíkorò.
- Isaiah 33:8nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Àwọn ojú ọ̀nà ńlá ni a ṣá tì, kò sí arìnrìn-àjò kankan ní ojú ọ̀nà. A ti ba àdéhùn jẹ́, a kẹ́gàn àwọn ẹlẹ́rìí, a kò bu ọlá fún ẹnikẹ́ni.
- Isaiah 33:9nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Ilẹ̀ ṣọ̀fọ̀ ó sì ṣòfò dànù, ojú ti Lebanoni ó sì sá Ṣaroni sì dàbí aginjù, àti Baṣani òun Karmeli rẹ àwọn èwe wọn.
- Isaiah 33:10nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
“Ní ìsinsin yìí ni èmi yóò dìde,” ni Olúwa wí. “Ní ìsinsin yìí ni a ó gbé mi ga, ní ìsinsin yìí ni a ó gbé mi sókè.
- Isaiah 33:11nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Ìwọ lóyún ìyàngbò, o sì bí koríko; èémí yín bí iná tí yóò jẹ yín run.
- Isaiah 33:12nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
A ó jó àwọn ènìyàn run bí eérú; bí igbó ẹ̀gún tí a gé la ó dáná sí wọn.”
- Isaiah 33:13nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Ìwọ tí ó wà lọ́nà jíjìn, gbọ́ ohun tí mo ti ṣe; ìwọ tí ò ń bẹ nítòsí, jẹ́rìí agbára mi!
- Isaiah 33:14nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Ẹ̀rù ba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní Sioni; ìwárìrì bá àwọn tí kò gba Ọlọ́run gbọ́: “Ta ni nínú wa lólè gbé pẹ̀lú iná ajónirun? Ta ni nínú wa lólè gbé pẹ̀lú iná àìnípẹ̀kun?”
- Isaiah 33:15nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Ẹni tí ó ń rìn lódodo tí ó ń sọ ohun tí ó tọ́, tí ó kọ èrè tí ó ti ibi ìlọ́nilọ́wọ́gbà wá, tí ó sì pa ọwọ́ rẹ̀ mọ́ kúrò nínú gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, tí ó di etí rẹ̀ sí ọ̀tẹ̀ láti pànìyàn tí ó sì di ojú rẹ̀ sí à ti pète ibi,
- Isaiah 33:16nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Òun náà yóò gbé ní ibi gíga, ibi ààbò rẹ̀ yóò jẹ́ òkè ńlá olódi. A ó mú oúnjẹ fún un, omi rẹ̀ yóò sì dájú.
- Isaiah 33:17nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Ojú rẹ yóò rí ọba nínú ẹwà rẹ̀ yóò sì rí ilẹ̀ kan tí ó tẹ́ lọ rẹrẹẹrẹ.
- Isaiah 33:18nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Nínú èrò rẹ ìwọ yóò rántí ẹ̀rù rẹ àtẹ̀yìnwá: “Níbo ni ọ̀gá àgbà náà wà? Níbo ni ẹni tí ń gba owó òde wà? Níbo ni òṣìṣẹ́ ti ó ń mójútó ilé ìṣọ́ wà?”
- Isaiah 33:19nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Ìwọ kì yóò rí àwọn agbéraga ènìyàn mọ́, àwọn ènìyàn tí èdè wọn fi ara sin, pẹ̀lú ahọ́n tí ó ṣàjèjì tí kò sì yé ni.
- Isaiah 33:20nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Gbójú sókè sí Sioni, ìlú àjọ̀dún wa, ojú rẹ yóò rí Jerusalẹmu, ibùgbé àlàáfíà n nì, àgọ́ tí a kò ní yí padà; àwọn òpó rẹ̀ ni a kì yóò fàtu tàbí èyíkéyìí nínú okùn rẹ̀ kí já.
- Isaiah 33:21nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Níbẹ̀ ni Olúwa yóò ti jẹ́ alágbára kan fún wa. Yóò sì dàbí ibi àwọn odò ńlá ńlá àti odò kéékèèké. Kì yóò sí ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú tí yóò kọjá lórí i wọn, ọkọ̀ ojú omi ńlá ni a kì yóò tù lórí wọn.
- Isaiah 33:22nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Nítorí Olúwa ni onídàájọ́ wa, Olúwa ni onídàájọ́ wa, Olúwa òun ni ọba wa; òun ni ẹni tí yóò gbà wá là.
- Isaiah 33:23nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Gbogbo okùn rẹ ni ó ti dẹ̀: Ìgbókùnró kò fìdímúlẹ̀, wọn kò taṣọ agbọ́kọ̀rìn, lẹ́yìn náà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkógun ni a ó pín àní arọ pẹ̀lú yóò ru ìkógun lọ.
- Isaiah 33:24nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó ń gbé Sioni tí yóò wí pé, “Ara mi kò yá,” a ó dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn tí ń gbé ibẹ̀ jì wọ́n.
- Isaiah 34:1nǹkan bí 713 ṣáájú Kristi
Súnmọ́ tòsí, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè láti gbọ́, tẹ́tí sílẹ̀ ẹ̀yin ènìyàn jẹ́ kí ayé gbọ́, àti ẹ̀kún rẹ̀, ayé àti ohun gbogbo tí ó ti inú rẹ̀ jáde.