- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 800–400 BC
The Hebrew Prophets
God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Sekariah 11:11nǹkan bí 487 ṣáájú Kristi
Ó sì dá ni ọjọ́ náà, bẹ́ẹ̀ ni àwọn òtòṣì nínú ọ̀wọ́ ẹran náà tí ó dúró tì mí mọ̀ pé, ọ̀rọ̀ Olúwa ni.
- Sekariah 11:12nǹkan bí 487 ṣáájú Kristi
Mo sì wí fún wọn pé, “Bí ó bá dára ní ojú yin, ẹ fún mi ni owó ọ̀yà mi; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ mú un lọ́wọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n wọn ọgbọ̀n owó fàdákà fún iye owó ọ̀yà mi.
- Sekariah 11:13nǹkan bí 487 ṣáájú Kristi
Olúwa sì wí fún mi pé, “Sọ ọ sí amọ̀kòkò.” Iye dáradára náà, tí wọn yọ owó mi sí. Mo sì mu ọgbọ̀n owó fàdákà náà, mo sì sọ wọ́n sí àpótí ìṣúra ní ilé Olúwa.
- Sekariah 11:14nǹkan bí 487 ṣáájú Kristi
Mo sì ṣẹ́ ọ̀pá mi kejì, àní Àmùrè, sí méjì, kí èmi lè ya ìbátan tí ó wà láàrín Juda àti láàrín Israẹli.
- Sekariah 11:15nǹkan bí 487 ṣáájú Kristi
Olúwa sì wí fún mi pé, “Tún mú ohun èlò aṣiwèrè olùṣọ́-àgùntàn kan sọ́dọ̀ rẹ̀.
- Sekariah 11:16nǹkan bí 487 ṣáájú Kristi
Nítorí Èmi o gbé Olùṣọ́-àgùntàn kan dìde ni ilẹ̀ náà, tí kí yóò bẹ àwọn tí ó ṣègbé wò, ti kì yóò sì wá èyí tí ó yapa; tí kì yóò ṣe ìtọ́jú èyí tí a pa lára tàbí kí ó bọ́ àwọn tí ara wọn dá pépé: Ṣùgbọ́n òun yóò jẹ ẹran èyí tí ó ni ọ̀rá, àwọn èyí tiwọn fi èékánná wọn ya ara wọn pẹ́rẹpẹ̀rẹ.
- Sekariah 11:17nǹkan bí 487 ṣáájú Kristi
“Ègbé ni fún olùṣọ́-àgùntàn asán náà, tí ó fi ọ̀wọ́ ẹran sílẹ̀! Idà yóò gé apá rẹ̀ àti ojú ọ̀tún rẹ̀: apá rẹ̀ yóò gbẹ pátápátá, ojú ọ̀tún rẹ̀ yóò sì fọ́ pátápátá!”
- Sekariah 12:1nǹkan bí 487 ṣáájú Kristi
Ọ̀rọ̀-ìmọ̀. Ọ̀rọ̀ Olúwa fún Israẹli ni. Olúwa wí, ẹni tí ó na àwọn ọ̀run, tí ó sì fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, tí ó sì da ẹ̀mí ènìyàn tí ń bẹ ni inú rẹ̀,
- Sekariah 12:2nǹkan bí 487 ṣáájú Kristi
“Kíyèsi í, èmi yóò sọ Jerusalẹmu dí àgọ́ ìwárìrì sí gbogbo ènìyàn yíká, nígbà tí wọn yóò dó ti Juda àti Jerusalẹmu.
- Sekariah 12:3nǹkan bí 487 ṣáájú Kristi
Ní ọjọ́ náà, nígbà tí gbogbo orílẹ̀-èdè ayé bá parapọ̀ sí i, ni èmi yóò sọ Jerusalẹmu di òkúta ti ko ṣe yí kúrò fún gbogbo ènìyàn, gbogbo àwọn tí ó bá sì fẹ́ yí i ni a ó gé sí wẹ́wẹ́,
- Sekariah 12:4nǹkan bí 487 ṣáájú Kristi
ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí, “Ni èmi yóò fi ìdágìrì lu gbogbo ẹṣin, àti fi òmùgọ̀ kọlu ẹni tí ń gun un; èmi yóò sì ṣí ojú mi sí ilé Juda, èmi yóò sì bu ìfọ́jú lu gbogbo ẹṣin tí orílẹ̀-èdè.
- Sekariah 12:5nǹkan bí 487 ṣáájú Kristi
Àti àwọn baálẹ̀ Juda yóò sì wí ni ọkàn wọn pé, ‘Àwọn ara Jerusalẹmu ni agbára mi nípa Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni Ọlọ́run wọn.’
- Sekariah 12:6nǹkan bí 487 ṣáájú Kristi
“Ní ọjọ́ náà, ni èmi yóò ṣe àwọn baálẹ̀ Juda bí ààrò iná kan láàrín igi, àti bi ẹ̀fúùfù iná láàrín ìtí; wọn yóò sì jẹ gbogbo àwọn ènìyàn run yíká lápá ọ̀tún àti lápá òsì, a ó sì tún máa gbé inú Jerusalẹmu ní ipò rẹ̀.
- Sekariah 12:7nǹkan bí 487 ṣáájú Kristi
“Olúwa pẹ̀lú yóò kọ́ tètè gba àgọ́ Juda là ná, kí ògo ilé Dafidi àti ògo àwọn ara Jerusalẹmu má ba gbé ara wọn ga sí Juda.
- Sekariah 12:8nǹkan bí 487 ṣáájú Kristi
Ní ọjọ́ náà ni Olúwa yóò dáàbò bò àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu; ẹni tí ó bá sì ṣe àìlera nínú wọn ní ọjọ́ náà, yóò dàbí Dafidi; ilé Dafidi yóò sì dàbí Ọlọ́run, bí angẹli Olúwa níwájú wọn.
- Sekariah 12:9nǹkan bí 487 ṣáájú Kristi
Yóò sì ṣe ni ọjọ́ náà, èmi yóò wá láti pa gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè run tí ó wá kọjú ìjà sí Jerusalẹmu.”
- Sekariah 12:10nǹkan bí 487 ṣáájú Kristi
“Èmi ó sì tu ẹ̀mí oore-ọ̀fẹ́ àti ẹ̀bẹ̀ sórí ilé Dafidi àti sórí Jerusalẹmu, wọn ó sì máa wo ẹni tí wọn tí gún ni ọ̀kọ̀, wọn ó sì máa ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, bí ẹnìkan ti ń ṣọ̀fọ̀ fún ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo àti gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí wọn yóò sì wà ni ìbànújẹ́, bí ẹni tí ń banújẹ́ fún àkọ́bí rẹ̀.
- Sekariah 12:11nǹkan bí 487 ṣáájú Kristi
Ní ọjọ́ náà ni ẹkún, ńlá ńlá yóò wà ni Jerusalẹmu, gẹ́gẹ́ bí ọ̀fọ̀ Hadadi Rimoni ni àfonífojì Megido.
- Sekariah 12:12nǹkan bí 487 ṣáájú Kristi
Ilẹ̀ náà yóò ṣọ̀fọ̀, ìdílé, kọ̀ọ̀kan fun ara rẹ, lọ́tọ̀ọ̀tọ̀; ìdílé Dafidi lọ́tọ̀; àti àwọn aya wọn lọ́tọ̀; ìdílé Natani lọ́tọ̀, àti àwọn aya wọn lọ́tọ́.
- Sekariah 12:13nǹkan bí 487 ṣáájú Kristi
Ìdílé Lefi lọ́tọ̀, àti àwọn aya wọn lọ́tọ̀; ìdílé Ṣimei lọ́tọ̀, àti àwọn aya wọn lọ́tọ̀.
- Sekariah 12:14nǹkan bí 487 ṣáájú Kristi
Gbogbo àwọn ìdílé tí o kù, ìdílé, ìdílé, lọ́tọ̀ọ̀tọ̀, àti àwọn aya wọn lọ́tọ̀ọ̀tọ̀.
- Sekariah 13:1nǹkan bí 487 ṣáájú Kristi
“Ní ọjọ́ náà ìsun kan yóò ṣí sílẹ̀ fún ilé Dafidi àti fún àwọn ará Jerusalẹmu, láti wẹ̀ wọ́n mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti àìmọ́ wọn.
- Sekariah 13:2nǹkan bí 487 ṣáájú Kristi
“Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ni èmi ó gé orúkọ àwọn òrìṣà kúrò ni ilẹ̀ náà, a kì yóò sì rántí wọn mọ́, àti pẹ̀lú èmi ó mú àwọn wòlíì èké àti àwọn ẹ̀mí àìmọ́ kúrò ni ilẹ̀ náà.
- Sekariah 13:3nǹkan bí 487 ṣáájú Kristi
Yóò sì ṣe, nígbà tí ẹnìkan yóò sọtẹ́lẹ̀ síbẹ̀, ni baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ tí ó bí í yóò wí fún un pé, ‘Ìwọ ki yóò yè, nítorí ìwọ ń sọ ọ̀rọ̀ èké ni orúkọ Olúwa.’ Àti baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ tí o bí í yóò gun un ni àgúnpa nígbà tí ó bá sọtẹ́lẹ̀.
- Sekariah 13:4nǹkan bí 487 ṣáájú Kristi
“Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà, ojú yóò tí àwọn wòlíì èké olúkúlùkù nítorí ìran rẹ̀, nígbà tí òun ba tí sọtẹ́lẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò sì wọ aṣọ wòlíì onírun rẹ̀ tí o fi ń tan ní jẹ.