Fò sí àkóónú

circa 800–400 BC

The Hebrew Prophets

God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.

3,706 ẹsẹ · 14 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Sekariah 8:13nǹkan bí 518 ṣáájú Kristi

    Yóò sì ṣe, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin tí jẹ́ ègún láàrín àwọn kèfèrí, ẹ̀yin ilé Juda, àti ilé Israẹli, bẹ́ẹ̀ ni èmi ó gbà yín sílẹ̀; ẹ̀yin o sì jẹ́ ìbùkún, ẹ má bẹ̀rù, ṣùgbọ́n jẹ́ ki ọwọ́ yín le.”

  2. Sekariah 8:14nǹkan bí 518 ṣáájú Kristi

    Nítorí báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Gẹ́gẹ́ bí mo ti rò láti ṣe yín níbi nígbà tí àwọn baba yín mú mi bínú,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, tí èmi kò sì ronúpìwàdà.

  3. Sekariah 8:15nǹkan bí 518 ṣáájú Kristi

    “Bẹ́ẹ̀ ni èmi sì ti ro ọjọ́ wọ̀nyí láti ṣe rere fún Jerusalẹmu, àti fún ilé Juda: ẹ má bẹ̀rù.

  4. Sekariah 8:16nǹkan bí 518 ṣáájú Kristi

    Wọ̀nyí ni nǹkan tí ẹ̀yin ó ṣe: ki olúkúlùkù yín kí ó máa ba ọmọnìkejì rẹ̀ sọ òtítọ́; ṣe ìdájọ́ tòótọ́ àti àlàáfíà ní àwọn ibodè yín.

  5. Sekariah 8:17nǹkan bí 518 ṣáájú Kristi

    Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan ro ibi ni ọkàn rẹ̀ sí ẹnìkejì rẹ̀; ẹ má fẹ́ ìbúra èké; nítorí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni mo kórìíra,” ni Olúwa wí.

  6. Sekariah 8:18nǹkan bí 518 ṣáájú Kristi

    Ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun sì tọ mi wá wí pé.

  7. Sekariah 8:19nǹkan bí 518 ṣáájú Kristi

    Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Àwẹ̀ oṣù kẹrin, karùn-ún, keje, àti tí ẹ̀kẹwàá, yóò jẹ́ ayọ̀ àti dídùn inú, àti àpéjọ àríyá fún ilé Juda; nítorí náà, ẹ fẹ́ òtítọ́ àti àlàáfíà.”

  8. Sekariah 8:20nǹkan bí 518 ṣáájú Kristi

    Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, “Àwọn ènìyàn yóò sá à tún wa, àti ẹni tí yóò gbe ìlú ńlá púpọ̀.

  9. Sekariah 8:21nǹkan bí 518 ṣáájú Kristi

    Àwọn ẹni tí ń gbé ìlú ńlá kan yóò lọ sí òmíràn, wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a yára lọ gbàdúrà kí a sì wá ojúrere Olúwa, àti láti wá Olúwa àwọn ọmọ-ogun. Èmi pẹ̀lú yóò sì lọ.’

  10. Sekariah 8:22nǹkan bí 518 ṣáájú Kristi

    Nítòótọ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn àti àwọn alágbára orílẹ̀-èdè yóò wá láti wá Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní Jerusalẹmu; àti láti gbàdúrà, àti láti wá ojúrere Olúwa.”

  11. Sekariah 8:23nǹkan bí 518 ṣáájú Kristi

    Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, “Ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí ni ọkùnrin mẹ́wàá láti inú gbogbo èdè àti orílẹ̀-èdè yóò dìímú, àní yóò di etí aṣọ ẹni tí i ṣe Júù mú, wí pé, ‘Àwa yóò ba ọ lọ, nítorí àwa tí gbọ́ pé, Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ.’ ”

  12. Sekariah 9:1nǹkan bí 487 ṣáájú Kristi

    Ọ̀rọ̀-ìmọ̀. Ọ̀rọ̀ Olúwa kọjú ìjà sí Hadiraki, Damasku ni yóò sì jẹ́ ibi ìsinmi rẹ̀; nítorí ojú Olúwa ń bẹ lára ènìyàn, àti lára gbogbo ẹ̀yà Israẹli.

  13. Sekariah 9:2nǹkan bí 487 ṣáájú Kristi

    Àti Hamati pẹ̀lú yóò ṣe ààlà rẹ̀ Tire àti Sidoni bí o tilẹ̀ ṣe ọlọ́gbọ́n gidigidi.

  14. Sekariah 9:3nǹkan bí 487 ṣáájú Kristi

    Tire sì mọ odi líle fún ara rẹ̀, ó sì kó fàdákà jọ bí eruku, àti wúrà dáradára bí ẹrẹ̀ ìgboro.

  15. Sekariah 9:4nǹkan bí 487 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n, Olúwa yóò kó gbogbo ohun ìní rẹ̀ lọ, yóò sì pa agbára rẹ̀ run ní ojú Òkun, a ó sì fi iná jó o run.

  16. Sekariah 9:5nǹkan bí 487 ṣáájú Kristi

    Aṣkeloni yóò rí í, yóò sì bẹ̀rù; Gasa pẹ̀lú yóò rí í, yóò sì káàánú gidigidi, àti Ekroni: nítorí tí ìrètí rẹ̀ yóò ṣákì í. Gasa yóò pàdánù ọba rẹ̀, Aṣkeloni yóò sì di ahoro.

  17. Sekariah 9:6nǹkan bí 487 ṣáájú Kristi

    Ọmọ àlè yóò sì gbé inú Aṣdodu, Èmi yóò sì gé ìgbéraga àwọn Filistini kúrò.

  18. Sekariah 9:7nǹkan bí 487 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ kúrò ni ẹnu rẹ̀, àti àwọn ohun èèwọ̀ kúrò láàrín eyín rẹ̀: ṣùgbọ́n àwọn tó ṣẹ́kù yóò jẹ́ tí Ọlọ́run wa, wọn yóò sì jẹ baálẹ̀ ní Juda, àti Ekroni ni yóò rí bí Jebusi.

  19. Sekariah 9:8nǹkan bí 487 ṣáájú Kristi

    Èmi yóò sì dó yí ilẹ̀ mi ká nítorí ogun àwọn tí wọ́n ń wá ohun tí wọn yóò bàjẹ́ kiri, kò sí aninilára tí yóò bori wọn mọ́: nítorí ni ìsinsin yìí ni mo fi ojú ṣọ́ wọn.

  20. Sekariah 9:9nǹkan bí 487 ṣáájú Kristi

    Kún fún ayọ̀, ìwọ ọmọbìnrin Sioni, hó ìhó ayọ̀, ìwọ ọmọbìnrin Jerusalẹmu. Wò ó, ọba rẹ ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ: òdodo ni òun, ó sì ní ìgbàlà; ó ní ìrẹ̀lẹ̀, ó sì ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àní ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.

  21. Sekariah 9:10nǹkan bí 487 ṣáájú Kristi

    Èmi ó sì gbé kẹ̀kẹ́ kúrò ni Efraimu, àti ẹṣin ogun kúrò ni Jerusalẹmu, a ó sì ṣẹ́ ọrun ogun. Òun yóò sì kéde àlàáfíà sí àwọn kèfèrí. Ìjọba rẹ̀ yóò sì gbilẹ̀ láti Òkun dé Òkun, àti láti odò títí de òpin ayé.

  22. Sekariah 9:11nǹkan bí 487 ṣáájú Kristi

    Ní tìrẹ, nítorí ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ, Èmi ó dá àwọn ìgbèkùn rẹ̀ sílẹ̀ kúrò nínú ọ̀gbun.

  23. Sekariah 9:12nǹkan bí 487 ṣáájú Kristi

    Ẹ padà sínú odi agbára yín, ẹ̀yin òǹdè ti o ni ìrètí: àní lónìí yìí èmi sọ pé, èmi o san án fún ọ ni ìlọ́po méjì.

  24. Sekariah 9:13nǹkan bí 487 ṣáájú Kristi

    Èmi ó fa Juda le bí mo ṣe fa ọrun mi le, mo sì fi Efraimu kún un, Èmi yóò gbé àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin dìde, ìwọ Sioni, sí àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, ìwọ Giriki, mo ṣe ọ́ bí idà alágbára.

  25. Sekariah 9:14nǹkan bí 487 ṣáájú Kristi

    Olúwa yóò sì fi ara hàn ní orí wọn; ọfà rẹ̀ yóò sì jáde lọ bí mọ̀nàmọ́ná. Olúwa Olódùmarè yóò sì fọn ìpè, Òun yóò sì lọ nínú atẹ́gùn ìjì gúúsù.