Fò sí àkóónú

circa AD 30–62

The Early Church

Pentecost ignites a movement; Peter, Paul, and countless others carry the gospel from Jerusalem to the ends of the earth.

1,007 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. Ìṣe àwọn Aposteli 15:32nǹkan bí 51 lẹ́yìn Kristi

    Bí Judasi àti Sila tìkára wọn ti jẹ́ wòlíì pẹ̀lú, wọ́n fi ọ̀rọ̀ púpọ̀ gba àwọn arákùnrin níyànjú, wọ́n sì mú wọn lọ́kàn le.

  2. Ìṣe àwọn Aposteli 15:33nǹkan bí 51 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí wọn sì pẹ́, díẹ̀, àwọn arákùnrin rán wọn padà lọ ni àlàáfíà sí ọ̀dọ̀ àwọn tí ó rán wọn wá.

  3. Ìṣe àwọn Aposteli 15:34nǹkan bí 51 lẹ́yìn Kristi

    Notwithstanding it pleased Silas to abide there still.

  4. Ìṣe àwọn Aposteli 15:35nǹkan bí 51 lẹ́yìn Kristi

    Paulu àti Barnaba sì dúró díẹ̀ ni Antioku, wọ́n ń kọ́ni, wọ́n sì ń wàásù ọ̀rọ̀, Olúwa, àti àwọn púpọ̀ mìíràn pẹ̀lú wọn.

  5. Ìṣe àwọn Aposteli 15:36nǹkan bí 51 lẹ́yìn Kristi

    Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan, Paulu sì sọ fún Barnaba pé, “Jẹ́ kí a tún padà lọ bẹ àwọn arákùnrin wa wò, bí wọn ti ń ṣe sí ni ìlú gbogbo tí àwa ti wàásù ọ̀rọ̀ Olúwa.”

  6. Ìṣe àwọn Aposteli 15:37nǹkan bí 51 lẹ́yìn Kristi

    Barnaba sì pinnu rẹ̀ láti mú Johanu lọ pẹ̀lú wọn, ẹni tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Marku.

  7. Ìṣe àwọn Aposteli 15:38nǹkan bí 51 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n Paulu rò pé, kò yẹ láti mú un lọ pẹ̀lú wọn, ẹni tí ó fi wọn sílẹ̀ ni Pamfilia, tí kò sì bá wọn lọ sí iṣẹ́ náà.

  8. Ìṣe àwọn Aposteli 15:39nǹkan bí 51 lẹ́yìn Kristi

    Ìjà náà sì pọ̀ tó bẹ́ẹ̀, tí wọn ya ara wọn sì méjì, Barnaba sì mu Marku ó tẹ ọkọ́ létí lọ sí Saipurọsi.

  9. Ìṣe àwọn Aposteli 15:40nǹkan bí 51 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n Paulu yan Sila, ó sì lọ, bí a ti fi lé oore-ọ̀fẹ́ Olúwa lọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin.

  10. Ìṣe àwọn Aposteli 15:41nǹkan bí 51 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì la Siria àti Kilikia lọ, ó ń mú ìjọ ní ọkàn le.

  11. Ìṣe àwọn Aposteli 16:1nǹkan bí 53 lẹ́yìn Kristi

    Ó sì wá sí Dabe àti Lysra: sí kíyèsi i, ọmọ-ẹ̀yìn kan wà níbẹ̀, tí a ń pè ní Timotiu, ọmọ obìnrin kan tí í ṣe Júù, tí ó gbàgbọ́; ṣùgbọ́n Giriki ní baba rẹ̀.

  12. Ìṣe àwọn Aposteli 16:2nǹkan bí 53 lẹ́yìn Kristi

    Ẹni tí a ròhìn rẹ̀ ní rere lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin tí ó wà ní Lysra àti Ikoniomu.

  13. Ìṣe àwọn Aposteli 16:3nǹkan bí 53 lẹ́yìn Kristi

    Òun ni Paulu fẹ́ kí ó bá òun lọ; ó sì mú un, ó sì kọ ọ́ ní ilà, nítorí àwọn Júù tí ó wà ní agbègbè wọ̀nyí, nítorí gbogbo wọn mọ̀ pé, Giriki ni baba rẹ̀.

  14. Ìṣe àwọn Aposteli 16:4nǹkan bí 53 lẹ́yìn Kristi

    Bí wọn sì ti ń la àwọn ìlú lọ, wọ́n ń fi àwọn àṣẹ, tí a tí pinnu láti ọ̀dọ̀ àwọn aposteli àti àwọn alàgbà tí ó wà ní Jerusalẹmu, lé wọn lọ́wọ́ láti máa pa wọ́n mọ́.

  15. Ìṣe àwọn Aposteli 16:5nǹkan bí 53 lẹ́yìn Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìjọ sì fẹsẹ̀múlẹ̀ ní ìgbàgbọ́, wọn sí ń pọ̀ sí i ní iye lójoojúmọ́.

  16. Ìṣe àwọn Aposteli 16:6nǹkan bí 53 lẹ́yìn Kristi

    Wọ́n sì la agbègbè Frigia já, àti Galatia, nítorí tí Ẹ̀mí Mímọ́ kọ̀ fún wọn láti sọ ọ̀rọ̀ náà ni Asia.

  17. Ìṣe àwọn Aposteli 16:7nǹkan bí 53 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí wọ́n dé ọ̀kánkán Misia, wọ́n gbìyànjú láti lọ sí Bitinia, ṣùgbọ́n Ẹ̀mí Jesu kò gbà fún wọn.

  18. Ìṣe àwọn Aposteli 16:8nǹkan bí 53 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí wọ́n sì kọjá lẹ́bàá Misia, wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí Troasi.

  19. Ìṣe àwọn Aposteli 16:9nǹkan bí 53 lẹ́yìn Kristi

    Ìran kan si hàn sì Paulu ni òru, ọkùnrin kan ará Makedonia dúró, ó sì ń bẹ̀ ẹ́, wí pé, “Rékọjá wá sí Makedonia, kí o sí ràn wá lọ́wọ́!”

  20. Ìṣe àwọn Aposteli 16:10nǹkan bí 53 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí ó sì tí rí ìran náà, lọ́gán ó múra láti lọ sí Makedonia, a ka á sí pé, Ọlọ́run tí pè wá láti wàásù ìyìnrere fún wọn.

  21. Ìṣe àwọn Aposteli 16:11nǹkan bí 53 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà nígbà tí àwa ṣíkọ̀ ní Troasi a ba ọ̀nà tààrà lọ sí Samotrakea, ni ọjọ́ kejì a sì dé Neapoli;

  22. Ìṣe àwọn Aposteli 16:12nǹkan bí 53 lẹ́yìn Kristi

    láti ibẹ̀ àwa sì lọ si Filipi, tí í ṣe ìlú Makedonia, olú ìlú ìhà ibẹ̀, ìlú lábẹ́ Romu, àwa sì jókòó ní ìlú yìí fún ọjọ́ mélòó kan.

  23. Ìṣe àwọn Aposteli 16:13nǹkan bí 53 lẹ́yìn Kristi

    Lọ́jọ́ ìsinmi, àwa sí jáde lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú náà, lẹ́bàá odò kan, níbi tí a rò pé ibi àdúrà wà; àwa sí jókòó, a sì bá àwọn obìnrin tí o péjọ sọ̀rọ̀.

  24. Ìṣe àwọn Aposteli 16:14nǹkan bí 53 lẹ́yìn Kristi

    Àti obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Lidia, elése àlùkò, ará ìlú Tiatira, ẹni tí ó sin Ọlọ́run, ó gbọ́ ọ̀rọ̀ wa, ọkàn ẹni tí Olúwa ṣí láti fetísí ohun tí a tí ẹnu Paulu sọ.

  25. Ìṣe àwọn Aposteli 16:15nǹkan bí 53 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí a sí bamitiisi rẹ̀, àti àwọn ara ilé rẹ̀, ó bẹ̀ wá, wí pé, “Bí ẹ̀yin bá kà mí ni olóòtítọ́ sí Olúwa, ẹ wá si ilé mi, kí ẹ sí wọ̀ níbẹ̀!” O sí rọ̀ wá.