Fò sí àkóónú

circa AD 30–62

The Early Church

Pentecost ignites a movement; Peter, Paul, and countless others carry the gospel from Jerusalem to the ends of the earth.

1,007 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. Ìṣe àwọn Aposteli 14:10nǹkan bí 46 lẹ́yìn Kristi

    Ó wí fún un ní ohùn rara pé, “Dìde dúró ṣánṣán lórí ẹsẹ̀ rẹ!” Ó sì ń fò sókè, ó sì ń rìn.

  2. Ìṣe àwọn Aposteli 14:11nǹkan bí 46 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí àwọn ènìyàn sì rí ohun tí Paulu ṣe, wọ́n gbé ohùn wọn sókè ni èdè Likaonia, wí pé, “Àwọn ọlọ́run sọ̀kalẹ̀ tọ̀ wá wá ni àwọ̀ ènìyàn!”

  3. Ìṣe àwọn Aposteli 14:12nǹkan bí 46 lẹ́yìn Kristi

    Wọn sì pe Barnaba ni Seusi àti Paulu ni Hermesi nítorí òun ni olórí ọ̀rọ̀ sísọ.

  4. Ìṣe àwọn Aposteli 14:13nǹkan bí 46 lẹ́yìn Kristi

    Àlùfáà Seusi, ẹni ti ilé òrìṣà rẹ̀ wá lẹ́yìn odi ìlú wọn sì mú màlúù àti màrìwò wá sí ẹnu ibodè láti rú ẹbọ pẹ̀lú ìjọ ènìyàn sí àwọn aposteli wọ̀nyí.

  5. Ìṣe àwọn Aposteli 14:14nǹkan bí 46 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn aposteli Barnaba àti Paulu gbọ́, wọ́n fa aṣọ wọn ya, wọn sí súré wọ inú àwùjọ, wọn ń ké rara pé:

  6. Ìṣe àwọn Aposteli 14:15nǹkan bí 46 lẹ́yìn Kristi

    “Ará, èéṣe ti ẹ̀yin fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí? Ènìyàn bí ẹ̀yin náà ni àwa ń ṣe pẹ̀lú, ti a sì ń wàásù ìyìnrere fún yín, kí ẹ̀yin ba à lè yípadà kúrò nínú ohun asán wọ̀nyí sí Ọlọ́run alààyè, tí ó dá ọ̀run àti ayé, òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn.

  7. Ìṣe àwọn Aposteli 14:16nǹkan bí 46 lẹ́yìn Kristi

    Ní ìran tí ó ti kọjá, ó faradà á fún gbogbo orílẹ̀-èdè, láti máa rìn ni ọ̀nà tiwọn.

  8. Ìṣe àwọn Aposteli 14:17nǹkan bí 46 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n kò fi ara rẹ̀ sílẹ̀ ní àìní ẹ̀rí, ní ti pé ó ṣe rere, ó ń fún yín lójò láti ọ̀run wá, àti ni àkókò èso, ó ń fi oúnjẹ àti ayọ̀ kún ọkàn yín.”

  9. Ìṣe àwọn Aposteli 14:18nǹkan bí 46 lẹ́yìn Kristi

    Díẹ̀ ni ó kù kí wọn má le fi ọ̀rọ̀ wọ̀nyí dá àwọn ènìyàn dúró, kí wọn má ṣe rú ẹbọ bọ wọ́n.

  10. Ìṣe àwọn Aposteli 14:19nǹkan bí 46 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn Júù kan sì ti Antioku àti Ikoniomu wá, nígbà tí wọ́n yí àwọn ènìyàn lọ́kàn padà, wọ́n sì sọ Paulu ní òkúta, wọ́n wọ́ ọ kúrò sí ẹ̀yin odi ìlú náà, wọn ṣe bí ó ti kú.

  11. Ìṣe àwọn Aposteli 14:20nǹkan bí 46 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn dúró ti i yíká, ó dìde ó sì padà wọ inú ìlú náà lọ. Ní ọjọ́ kejì ó bá Barnaba lọ sí Dabe.

  12. Ìṣe àwọn Aposteli 14:21nǹkan bí 46 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí wọ́n sì ti wàásù ìyìnrere fún ìlú náà, tí wọ́n sì ni ọmọ-ẹ̀yìn púpọ̀, wọn padà lọ sí Lysra, àti Ikoniomu, àti Antioku,

  13. Ìṣe àwọn Aposteli 14:22nǹkan bí 46 lẹ́yìn Kristi

    wọn sì ń mú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn lọ́kàn le, wọ́n sì ń gbà wọ́n níyànjú láti dúró nínú ìgbàgbọ́, àti pé nínú ìpọ́njú púpọ̀, ni àwa ó fi wọ ìjọba Ọlọ́run.

  14. Ìṣe àwọn Aposteli 14:23nǹkan bí 46 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí wọ́n sì ti yan àwọn alàgbà fún olúkúlùkù ìjọ, tí wọn sì ti fi àwẹ̀ gbàdúrà, wọn fi wọ́n lé Olúwa lọ́wọ, ẹni tí wọn gbàgbọ́.

  15. Ìṣe àwọn Aposteli 14:24nǹkan bí 46 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí wọn sí la Pisidia já, wọ́n wá sí Pamfilia.

  16. Ìṣe àwọn Aposteli 14:25nǹkan bí 46 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí wọn sì ti sọ ọ̀rọ̀ náà ni Perga, wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí Atalia.

  17. Ìṣe àwọn Aposteli 14:26nǹkan bí 46 lẹ́yìn Kristi

    Àti láti ibẹ̀ lọ wọ́n ṣíkọ̀ lọ sí Antioku ní ibi tí a gbé ti fi wọ́n lé oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run lọ́wọ́, fún iṣẹ́ tí wọ́n ṣe parí.

  18. Ìṣe àwọn Aposteli 14:27nǹkan bí 46 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí wọ́n sì dé, tí wọ́n sì pé ìjọ jọ, wọ́n ròhìn gbogbo ohun tí Ọlọ́run fi wọ́n ṣe, àti bí ó ti ṣí ìlẹ̀kùn ìgbàgbọ́ fún àwọn aláìkọlà.

  19. Ìṣe àwọn Aposteli 14:28nǹkan bí 46 lẹ́yìn Kristi

    Níbẹ̀ ni wọ́n ń gbé pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ni ọjọ́ púpọ̀.

  20. Ìṣe àwọn Aposteli 15:1nǹkan bí 51 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn ọkùnrin kan tí Judea sọ̀kalẹ̀ wá, wọ́n sì kọ́ àwọn arákùnrin pé, “Bí kò ṣe pé a bá kọ yín ni ilà bí ìṣe Mose, ẹ̀yin kí yóò lè là.”

  21. Ìṣe àwọn Aposteli 15:2nǹkan bí 51 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí Paulu àti Barnaba ni ìyapa àti ìyàn jíjà tí kò mọ níwọ̀n pẹ̀lú ara wọn, wọ́n yan Paulu àti Barnaba àti àwọn mìíràn nínú aposteli kí wọn gòkè lọ sí Jerusalẹmu, sọ́dọ̀ àwọn alàgbà nítorí ọ̀ràn yìí.

  22. Ìṣe àwọn Aposteli 15:3nǹkan bí 51 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà, bí ìjọ ti rán wọn jáde lọ sí ọ̀nà wọn, wọn la Fonisia àti Samaria kọjá, wọ́n ń ròyìn ìyípadà àwọn aláìkọlà, wọ́n sì fi ayọ̀ ńlá fún gbogbo àwọn arákùnrin.

  23. Ìṣe àwọn Aposteli 15:4nǹkan bí 51 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí wọn sì dé Jerusalẹmu, ìjọ àti àwọn aposteli àti àwọn alàgbà tẹ́wọ́gbà wọ́n, wọ́n sì ròyìn ohun gbogbo tí Ọlọ́run ti ṣe nípasẹ̀ wọn.

  24. Ìṣe àwọn Aposteli 15:5nǹkan bí 51 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n àwọn kan nínú ẹ̀yà àwọn Farisi tí wọ́n gbàgbọ́ dìde, wọ́n ń wí pé, “A ní láti kọ wọ́n ní ilà, àti láti pàṣẹ fún wọn pé kí wọn máa pa òfin Mose mọ́.”

  25. Ìṣe àwọn Aposteli 15:6nǹkan bí 51 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn aposteli àti àwọn alàgbà péjọ láti rí si ọ̀ràn yìí.