Fò sí àkóónú

circa AD 30–62

The Early Church

Pentecost ignites a movement; Peter, Paul, and countless others carry the gospel from Jerusalem to the ends of the earth.

1,007 ẹsẹ · 1 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

  1. Ìṣe àwọn Aposteli 13:12nǹkan bí 45 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí baálẹ̀ rí ohun tí ó ṣe, ó gbàgbọ́, ẹnu sì yà á sì ẹ̀kọ́ Olúwa.

  2. Ìṣe àwọn Aposteli 13:13nǹkan bí 45 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà tí Paulu àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ si ṣíkọ̀ ni Pafosi wọ́n wá sí Perga ni Pamfilia: Johanu sì fi wọ́n sílẹ̀, ó sì padà lọ sí Jerusalẹmu.

  3. Ìṣe àwọn Aposteli 13:14nǹkan bí 45 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà ti wọ́n sì là Perga kọjá, wọ́n wá sí Pisidia ní Antioku. Wọ́n sì wọ inú Sinagọgu ní ọjọ́ ìsinmi, wọ́n sì jókòó.

  4. Ìṣe àwọn Aposteli 13:15nǹkan bí 45 lẹ́yìn Kristi

    Lẹ́yìn kíka ìwé òfin àti ìwé àwọn wòlíì, àwọn olórí Sinagọgu ránṣẹ́ sí wọn, pé, “Ará, bí ẹ̀yin bá ni ọ̀rọ̀ ìyànjú kan fún àwọn ènìyàn, ẹ sọ ọ́!”

  5. Ìṣe àwọn Aposteli 13:16nǹkan bí 45 lẹ́yìn Kristi

    Paulu sì dìde dúró, ó sì juwọ́ sí wọn, ó ní, “Ẹ̀yin Israẹli, àti ẹ̀yin ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run, ẹ fi etí sílẹ̀ sí mi!

  6. Ìṣe àwọn Aposteli 13:17nǹkan bí 45 lẹ́yìn Kristi

    Ọlọ́run àwọn ènìyàn Israẹli yìí yan àwọn baba wa, ó sì gbé àwọn ènìyàn náà lékè, nígbà tí wọ́n ṣe àtìpó ní ilẹ̀ Ejibiti, pẹ̀lú agbára ńlá ni ó sì fi mú wọn jáde kúrò nínú rẹ̀,

  7. Ìṣe àwọn Aposteli 13:18nǹkan bí 45 lẹ́yìn Kristi

    ní ìwọ̀n ìgbà ogójì ọdún ni ó fi mú sùúrù fún ìwà wọn ní ijù,

  8. Ìṣe àwọn Aposteli 13:19nǹkan bí 45 lẹ́yìn Kristi

    nígbà tí ó sì ti run orílẹ̀-èdè méje ni ilẹ̀ Kenaani, ó sì fi ilẹ̀ wọn fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ni ìní.

  9. Ìṣe àwọn Aposteli 13:20nǹkan bí 45 lẹ́yìn Kristi

    Gbogbo èyí sì ṣẹlẹ̀ fún ìwọ̀n àádọ́ta lé ní irinwó (450) ọdún. “Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ni Ọlọ́run fi onídàájọ́ fún wọn, títí ó fi di ìgbà Samuẹli wòlíì.

  10. Ìṣe àwọn Aposteli 13:21nǹkan bí 45 lẹ́yìn Kristi

    Lẹ́yìn náà ni wọ́n sì béèrè ọba; Ọlọ́run sì fún wọn ní Saulu ọmọ Kiṣi, ọkùnrin kan nínú ẹ̀yà Benjamini, fún ogójì ọdún.

  11. Ìṣe àwọn Aposteli 13:22nǹkan bí 45 lẹ́yìn Kristi

    Nígbà ti ó sì mú Saulu kúrò, ó gbé Dafidi dìde ní ọba fún wọn, ẹni tí ó sì jẹ́rìí rẹ̀ pé, ‘Mo rí Dafidi ọmọ Jese ẹni bí ọkàn mi, ti yóò ṣe gbogbo ìfẹ́ mi.’

  12. Ìṣe àwọn Aposteli 13:23nǹkan bí 45 lẹ́yìn Kristi

    “Láti inú irú-ọmọ ọkùnrin yìí ni Ọlọ́run ti gbé Jesu Olùgbàlà dìde fún Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìlérí.

  13. Ìṣe àwọn Aposteli 13:24nǹkan bí 45 lẹ́yìn Kristi

    Ṣáájú wíwá Jesu ni Johanu ti wàásù bamitiisi ìrònúpìwàdà fún gbogbo ènìyàn Israẹli.

  14. Ìṣe àwọn Aposteli 13:25nǹkan bí 45 lẹ́yìn Kristi

    Bí Johanu sì ti ńlá ipa tirẹ̀ já, ó ni, ‘Ta ni ẹ̀yin ṣe bí èmi jẹ́? Èmi kì í ṣe òun. Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsi í, ẹnìkan ń bọ̀ lẹ́yìn mi, bàtà ẹsẹ̀ ẹni tí èmi kò tó tú.’

  15. Ìṣe àwọn Aposteli 13:26nǹkan bí 45 lẹ́yìn Kristi

    “Ará, ẹ̀yin ọmọ ìran Abrahamu, àti ẹ̀yin ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run, àwa ni a rán ọ̀rọ̀ ìgbàlà yìí sí.

  16. Ìṣe àwọn Aposteli 13:27nǹkan bí 45 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu, àti àwọn olórí wọn, nítorí tiwọn kò mọ̀ Jesu, tí wọn kò sì ní òye ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì, tí a ń kà ní ọjọọjọ́ ìsinmi fún wọn, kò yé wọn, wọ́n mú ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì yìí ṣẹ nípa dídá a lẹ́bi.

  17. Ìṣe àwọn Aposteli 13:28nǹkan bí 45 lẹ́yìn Kristi

    Àti bí wọn kò tilẹ̀ ti rí ọ̀ràn ikú sí i, síbẹ̀ wọn rọ Pilatu láti pa á.

  18. Ìṣe àwọn Aposteli 13:29nǹkan bí 45 lẹ́yìn Kristi

    Bí wọ́n ti mú nǹkan gbogbo ṣẹ ti a kọ̀wé nítorí rẹ̀, wọn sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ kúrò lórí igi, wọ́n sì tẹ́ ẹ sí ibojì.

  19. Ìṣe àwọn Aposteli 13:30nǹkan bí 45 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òkú,

  20. Ìṣe àwọn Aposteli 13:31nǹkan bí 45 lẹ́yìn Kristi

    o sì farahàn lọ́jọ́ púpọ̀ fún àwọn tí ó bá a gòkè láti Galili wá sí Jerusalẹmu, àwọn tí í ṣe ẹlẹ́rìí rẹ̀ nísinsin yìí fún àwọn ènìyàn.

  21. Ìṣe àwọn Aposteli 13:32nǹkan bí 45 lẹ́yìn Kristi

    “Àwa sì mú ìyìnrere wá fún yín pé, ìlérí èyí tí Ọlọ́run ti ṣe fún àwọn baba wa,

  22. Ìṣe àwọn Aposteli 13:33nǹkan bí 45 lẹ́yìn Kristi

    èyí ni Ọlọ́run ti mú ṣẹ fún àwa ọmọ wọn, nípa gbígbé Jesu dìde, bí a sì ti kọ̀wé rẹ̀ nínú Saamu kejì pé, “ ‘Ìwọ ni Ọmọ mi; lónìí ni mo bí ọ.’

  23. Ìṣe àwọn Aposteli 13:34nǹkan bí 45 lẹ́yìn Kristi

    Àti ni tí pé Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òkú, ẹni tí kì yóò tún padà sí ìbàjẹ́ mọ́, ó wí báyìí pé: “ ‘Èmi ó fún yín ní ọ̀rẹ́ mímọ́ Dafidi, tí ó dájú.’

  24. Ìṣe àwọn Aposteli 13:35nǹkan bí 45 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí ó sì wí nínú Saamu mìíràn pẹ̀lú pé, “ ‘Ìwọ kí yóò jẹ́ kí Ẹni Mímọ́ rẹ rí ìdíbàjẹ́.’

  25. Ìṣe àwọn Aposteli 13:36nǹkan bí 45 lẹ́yìn Kristi

    “Nítorí lẹ́yìn ìgbà ti Dafidi ti sin ìran rẹ tan nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, ó sùn, a sì tẹ́ ẹ ti àwọn baba rẹ̀, ara rẹ̀ sì rí ìdíbàjẹ́.