- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 930–586 BC
The Divided Kingdom
The kingdom splits into Israel and Judah; prophets warn of judgment as both nations slowly drift into idolatry and exile.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- 2 Kronika 34:12nǹkan bí 624 ṣáájú Kristi
Àwọn ọkùnrin náà ṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú òtítọ́, láti darí wọn ní Jahati àti Obadiah, àwọn ọmọ Lefi láti Merari, àti Sekariah àti Meṣullamu, sọ̀kalẹ̀ láti Kohati àwọn ọmọ Lefi gbogbo tí ó ní ọgbọ̀n ohun èlò orin.
- 2 Kronika 34:13nǹkan bí 624 ṣáájú Kristi
Wọ́n sì ní olórí àwọn aláàárù àti àwọn alábojútó gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ láti ibi iṣẹ́ sí ibi iṣẹ́, díẹ̀ nínú àwọn ọmọ Lefi sì ní akọ̀wé, olùtọ́jú àti olùṣọ́nà.
- 2 Kronika 34:14nǹkan bí 624 ṣáájú Kristi
Nígbà tí wọ́n mú owó náà tí wọ́n mú wá sí ilé Olúwa, Hilkiah àlùfáà sì rí ìwé òfin Olúwa tí a ti fi fún un láti ọwọ́ Mose.
- 2 Kronika 34:15nǹkan bí 624 ṣáájú Kristi
Hilkiah sì wí fún Ṣafani akọ̀wé pé, “Èmi ti rí ìwé òfin nínú ilé Olúwa.” Ó sì fi fún Ṣafani.
- 2 Kronika 34:16nǹkan bí 624 ṣáájú Kristi
Nígbà náà Ṣafani sì mú ìwé náà lọ sí ọ̀dọ̀ ọba ó sì ròyìn fún un. “Àwọn ìjòyè rẹ̀ ń ṣe gbogbo nǹkan tí a ti fi lé wọn lọ́wọ́.
- 2 Kronika 34:17nǹkan bí 624 ṣáájú Kristi
Wọ́n ti san owó náà tí ó wà nínú ilé Olúwa wọ́n sì ti fi lé àwọn alábojútó lọ́wọ́ àti àwọn òṣìṣẹ́.”
- 2 Kronika 34:18nǹkan bí 624 ṣáájú Kristi
Nígbà náà Ṣafani akọ̀wé sì sọ fún ọba, “Hilkiah àlùfáà ti fún mi ní ìwé.” Ṣafani sì kà níwájú ọba.
- 2 Kronika 34:19nǹkan bí 624 ṣáájú Kristi
Nígbà tí ọba sì gbọ́ ọ̀rọ̀ òfin, ó sì fa aṣọ rẹ̀ ya.
- 2 Kronika 34:20nǹkan bí 624 ṣáájú Kristi
Ó sì pa àṣẹ yìí fún Hilkiah, Ahikamu ọmọ Ṣafani, Abdoni ọmọ Mika, Ṣafani akọ̀wé àti Asaiah ìránṣẹ́ ọba.
- 2 Kronika 34:21nǹkan bí 624 ṣáájú Kristi
“Ẹ lọ kí ẹ lọ béèrè lọ́wọ́ Olúwa fún mi nípa àwọn ìyókù Israẹli àti Juda nípa ohun tí wọ́n kọ sínú ìwé yìí tí a ti rí. Títóbi ni ìbínú Olúwa tí ó ti jáde sí orí wa nítorí àwọn baba wa kò ti pa ọ̀rọ̀ Olúwa mọ́, wọn kò sì tí ì ṣe gẹ́gẹ́ bí i gbogbo èyí tí a kọ sínú ìwé yìí.”
- 2 Kronika 34:22nǹkan bí 624 ṣáájú Kristi
Hilkiah àti àwọn ènìyàn tí ọba yàn tọ Hulda wòlíì obìnrin láti ba sọ̀rọ̀, ẹni tí ó jẹ́ aya Ṣallumu ọmọ Tokhati tí a tún ń pè ní Tikfa, ọmọ Harhasi, olùtọ́jú ibi ìkáṣọsí. Ó sì ń gbé ní Jerusalẹmu, ní ìhà kejì.
- 2 Kronika 34:23nǹkan bí 624 ṣáájú Kristi
Ó sì wí fún wọn wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli ti sọ, sọ fún àwọn ọkùnrin tí ó rán ọ sí mi pé,
- 2 Kronika 34:24nǹkan bí 624 ṣáájú Kristi
‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí, “Èmi yóò sì mú ibi wá sí ìhín yìí àti àwọn ènìyàn rẹ̀ gbogbo àní ègún tí a kọ sínú ìwé tí wọ́n ti kà níwájú ọba Juda.”
- 2 Kronika 34:25nǹkan bí 624 ṣáájú Kristi
Nítorí tí wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀ wọ́n sì ti sun tùràrí sí ọlọ́run mìíràn wọ́n sì ti mú mi bínú pẹ̀lú gbogbo ohun tí wọ́n ti fi ọwọ́ wọn ṣe, ìbínú yóò tú jáde wá sórí ibí yìí, a kì yóò sì paná rẹ̀.’
- 2 Kronika 34:26nǹkan bí 624 ṣáájú Kristi
Sọ fún ọba Juda, ẹni tí ó rán yín láti béèrè lọ́wọ́ Olúwa, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa ti sọ, Ọlọ́run Israẹli, sọ nípa ọ̀rọ̀ wọ́n nì tí ìwọ gbọ́.
- 2 Kronika 34:27nǹkan bí 624 ṣáájú Kristi
Nítorí ọkàn rẹ̀ dúró, ìwọ sì rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú Olúwa nígbà tí ó gbọ́ ohun tí ó sọ lórí ibí yìí àti ènìyàn rẹ, nítorí ìwọ rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú mi tí o sì fa aṣọ rẹ ya, tí o sì lọ níwájú mi. Èmi ti gbọ́ tìrẹ ni Olúwa wí.
- 2 Kronika 34:28nǹkan bí 624 ṣáájú Kristi
Nísinsin yìí, Èmi ó kó ọ jọ pọ̀ sọ́dọ̀ àwọn baba rẹ, a ó sì sin ọ́ ní àlàáfíà. Ojú rẹ kò sì ní rí gbogbo ibi tí èmi ó mú wá sórí ibí yìí àti lórí àwọn tí ń gbé ibẹ̀.’ ” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n mú ìdáhùn rẹ̀ padà sí ọ̀dọ̀ ọba.
- 2 Kronika 34:29nǹkan bí 624 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni ọba sì pe gbogbo àwọn àgbàgbà Juda jọ àti Jerusalẹmu.
- 2 Kronika 34:30nǹkan bí 624 ṣáájú Kristi
Ó gòkè lọ sí ilé Olúwa pẹ̀lú àwọn ọkùnrin Juda, àwọn ènìyàn Jerusalẹmu, àwọn àlùfáà àti àwọn Lefi—gbogbo àwọn ènìyàn láti ibi kéékèèké sí ńlá. Ó kà á sí etí ìgbọ́ ọ wọn, gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú ìwé májẹ̀mú, tí a ti rí nínú ilé Olúwa.
- 2 Kronika 34:31nǹkan bí 624 ṣáájú Kristi
Ọba sì dúró ní ipò rẹ̀ ó sì tún májẹ̀mú dá níwájú Olúwa, láti tẹ̀lé Olúwa àti láti pa òfin rẹ̀ mọ́, àti ẹ̀rí rẹ̀ àti àṣẹ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀ àti gbogbo àyà rẹ̀ àti láti pa ọ̀rọ̀ májẹ̀mú tí a kọ sí inú ìwé yìí.
- 2 Kronika 34:32nǹkan bí 624 ṣáájú Kristi
Nígbà náà, ó sì mú kí gbogbo ènìyàn ní Jerusalẹmu àti Benjamini dúró nínú ẹ̀rí fún ara wọn, àwọn ènìyàn Jerusalẹmu ṣe èyí gẹ́gẹ́ bi májẹ̀mú Ọlọ́run, Ọlọ́run baba ńlá wọn.
- 2 Kronika 34:33nǹkan bí 624 ṣáájú Kristi
Josiah sì kó gbogbo ohun ìríra kúrò nínú gbogbo ìlú tí ń ṣe ti àwọn tí ó wà ní Israẹli, ó sì mú kí gbogbo àwọn tí ó wà ní Israẹli sin Olúwa Ọlọ́run wọn gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe wà láyè wọn, kò yà kúrò láti máa tọ Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn lẹ́yìn.
Síwájú sí i, Josiah ṣe ìrántí àjọ ìrékọjá sí Olúwa ní Jerusalẹmu, Ọ̀dọ́-àgùntàn àjọ ìrékọjá náà ni wọ́n sì pa ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ín-ní.
Ó sì yàn àwọn àlùfáà sí iṣẹ́ wọn, ó sì gbà wọ́n ní ìyànjú ní ìsìn ilé Olúwa.
Ó sì wí fún àwọn ọmọ Lefi, ẹni tí ń kọ́ gbogbo àwọn Israẹli ẹni tí a ti yà sí mímọ́ fún Olúwa pé ẹ gbé àpótí ẹ̀rí ìyàsọ́tọ̀ sí ilé Olúwa tí Solomoni ọmọ Dafidi ọba Israẹli ti kọ́. Kò gbọdọ̀ jẹ́ ẹrù àgbéká ní èjìká rẹ̀. Nísinsin yìí ẹ sin Olúwa Ọlọ́run yín àti àwọn ènìyàn rẹ̀ Israẹli.