Fò sí àkóónú

circa 930–586 BC

The Divided Kingdom

The kingdom splits into Israel and Judah; prophets warn of judgment as both nations slowly drift into idolatry and exile.

1,722 ẹsẹ · 3 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. 2 Kronika 33:12nǹkan bí 677 ṣáájú Kristi

    Nínú ìpọ́njú rẹ̀, ó wá ojúrere Olúwa Ọlọ́run rẹ̀. Ó sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ gidigidi níwájú Ọlọ́run àwọn baba rẹ̀.

  2. 2 Kronika 33:13nǹkan bí 677 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí ó sì gbàdúrà sí i, inú Olúwa dùn sí àdúrà rẹ̀, ó sì tẹ́tí sí ẹ̀bẹ̀ rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni ó mú un padà wá sí Jerusalẹmu àti sí ìjọba rẹ̀. Nígbà náà Manase mọ̀ wí pé Olúwa ni Ọlọ́run.

  3. 2 Kronika 33:14nǹkan bí 677 ṣáájú Kristi

    Ǹjẹ́ lẹ́yìn èyí, ó mọ odi kan lẹ́yìn ìlú Dafidi, ní ìhà ìwọ̀-oòrùn Gihoni, ní àfonífojì, àní ní àtiwọ ẹnu ibodè ẹja, ó sì yí orí òkè Ofeli ká; ó sì mọ ọ́n ga sókè gidigidi, ó sì fi balógun sínú gbogbo ìlú olódi Juda wọ̀n-ọn-nì.

  4. 2 Kronika 33:15nǹkan bí 677 ṣáájú Kristi

    Ó pa gbogbo àwọn Ọlọ́run àjèjì run. Ó sì hú gbogbo àwọn ère kúrò nínú ilé Olúwa, pẹ̀lú gbogbo àwọn pẹpẹ tí ó ti kọ́ ní òkè ilé Olúwa àti ní Jerusalẹmu; ó sì kó wọn jáde kúrò nínú ìlú.

  5. 2 Kronika 33:16nǹkan bí 677 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni ó mú àwọn pẹpẹ padà bọ̀ sípò. Ó sì rú ọrẹ ìdàpọ̀ àti ọrẹ-ọpẹ́ lórí rẹ̀. Ó sì sọ fún Juda láti sin Olúwa, Ọlọ́run Israẹli.

  6. 2 Kronika 33:17nǹkan bí 677 ṣáájú Kristi

    Àwọn ènìyàn, ko tẹ̀síwájú láti máa rú ẹbọ ní àwọn ibi gíga. Ṣùgbọ́n sí Olúwa Ọlọ́run wọn nìkan.

  7. 2 Kronika 33:18nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    Àwọn iṣẹ́ yòókù ti ìjọba Manase pẹ̀lú àdúrà rẹ̀ sí Ọlọ́run rẹ̀ àti àwọn ọ̀rọ̀ tí àwọn aríran sọ sí i ní orúkọ Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, wà nínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli.

  8. 2 Kronika 33:19nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    Àdúrà rẹ̀ àti bí inú Ọlọ́run ṣe dùn sí àdúrà rẹ̀ àti gbogbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ àti àìṣòótọ́, àti àwọn òpó níbi tí ó kọ́ àwọn ibi gíga sí, ó sì gbé àwọn ère Aṣerah àti àwọn òrìṣà kí ó tó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, gbogbo rẹ̀ ni a kọ sínú ìwé ìrántí àwọn aríran.

  9. 2 Kronika 33:20nǹkan bí 698 ṣáájú Kristi

    Manase sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín sínú ààfin rẹ̀. Amoni ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

  10. 2 Kronika 33:21nǹkan bí 643 ṣáájú Kristi

    Amoni jẹ́ ẹni ọdún méjìlélógún nígbà tí ó di ọba. Ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún méjì.

  11. 2 Kronika 33:22nǹkan bí 643 ṣáájú Kristi

    Ó ṣe búburú ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ Manase ti ṣe. Amoni rú ẹbọ sí gbogbo àwọn òrìṣà tí Manase baba rẹ̀ ti ṣe, ó sì sìn wọ́n.

  12. 2 Kronika 33:23nǹkan bí 643 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n kì í ṣe bí i baba rẹ̀ Manase. Kò rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Olúwa: ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ Amoni sì ń pọ̀ sì í.

  13. 2 Kronika 33:24nǹkan bí 641 ṣáájú Kristi

    Àwọn oníṣẹ́ Amoni dìtẹ̀ sí i. Wọ́n sì pa á ní ààfin rẹ̀.

  14. 2 Kronika 33:25nǹkan bí 641 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà, gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà pa gbogbo àwọn tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Amoni, wọ́n sì mú Josiah ọmọ rẹ̀ jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

  15. 2 Kronika 34:1nǹkan bí 641 ṣáájú Kristi

    Josiah sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́jọ nígbà tí ó jẹ ọba, ó sì dí ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n.

  16. 2 Kronika 34:2nǹkan bí 641 ṣáájú Kristi

    Ó sì ṣe ohun tí ó dára ní ojú Olúwa, ó sì rìn ọ̀nà baba rẹ̀ Dafidi, kò sì yà sí ọwọ́ ọ̀tún tàbí òsì.

  17. 2 Kronika 34:3nǹkan bí 634 ṣáájú Kristi

    Ní ọdún kẹjọ ìjọba rẹ̀, nígbà tí ó sì wà ní ọ̀dọ́mọdé, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wá ojú Ọlọ́run baba Dafidi. Ní ọdún kejìlá. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fọ Juda àti Jerusalẹmu mọ́ kúrò ní ibi gíga rẹ̀, ère òrìṣà Aṣerah, àti ère yíyá àti ère dídà.

  18. 2 Kronika 34:4nǹkan bí 634 ṣáájú Kristi

    Lábẹ́ àpẹẹrẹ àwọn pẹpẹ Baali ni a yí lulẹ̀, ó sì fọ́ àwọn ère sí wẹ́wẹ́, ó run àwọn pẹpẹ tí ó wà lórí rẹ̀, wọ́n sì fọ́ túútúú, àwọn ère Aṣerah àti àwọn òrìṣà. Èyí tí ó fọ́ wọn sì lúúlúú, ó sì gbọ̀n wọ́n sí orí isà òkú àti àwọn tí ó ń rú ẹbọ sí wọn.

  19. 2 Kronika 34:5nǹkan bí 634 ṣáájú Kristi

    Ó sì sun àwọn egungun àwọn àlùfáà lórí pẹpẹ wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni ó sì wẹ Juda àti Jerusalẹmu mọ́.

  20. 2 Kronika 34:6nǹkan bí 634 ṣáájú Kristi

    Ní ìlú Manase, Efraimu àti Simeoni, àní títí ó fi dé Naftali, àti nínú àwọn, ó tú ilé wọn yíkákiri.

  21. 2 Kronika 34:7nǹkan bí 634 ṣáájú Kristi

    Ó sì wó pẹpẹ àti ère Aṣerah lulẹ̀ àti àwọn ère yíyá àti àwọn òrìṣà, ó sì gùn ó sì ti ké gbogbo àwọn ère orí pẹpẹ lulẹ̀ ní gbogbo àyíká Israẹli. Lẹ́yìn náà ó padà sí Jerusalẹmu.

  22. 2 Kronika 34:8nǹkan bí 624 ṣáájú Kristi

    Ní ọdún kejìdínlógún ìjọba Josiah ni a ti wẹ ilẹ̀ náà mọ́ àti ilé Olúwa, ó sì rán Ṣafani ọmọ Asalia àti Maaseiah olórí ìlú náà, pẹ̀lú Joah, ọmọ Joahasi, akọ̀wé, láti tún ilé Olúwa Ọlọ́run ṣe.

  23. 2 Kronika 34:9nǹkan bí 624 ṣáájú Kristi

    Wọ́n sì lọ sí ọ̀dọ̀ Hilkiah olórí àlùfáà, ó sì fún un ní owó náà tí ó mú wá sí inú ilé Ọlọ́run, ti àwọn ọmọ Lefi ẹni tí ó jẹ́ aṣọ́bodè ti gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn Manase Efraimu àti láti ọ̀dọ̀ àwọn ìyókù Israẹli àti ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn Juda àti Benjamini wọ́n sì padà sí Jerusalẹmu.

  24. 2 Kronika 34:10nǹkan bí 624 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni wọn sì fi le àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ilé lọ́wọ́, àwọn tí ń ṣe alábojútó iṣẹ́ ilé Olúwa. Àwọn ọkùnrin yìí sì san owó fún àwọn òṣìṣẹ́ tí ó ń túnṣe, tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ ní ilé Olúwa.

  25. 2 Kronika 34:11nǹkan bí 624 ṣáájú Kristi

    Wọ́n sì tún fi owó fún àwọn oníṣọ̀nà àti àwọn olùkọ́lé láti ra òkúta gbígbẹ́ àti ìtì igi fún ìsopọ̀ àti igi rírẹ́ fún ìkọ́lé tí ọba Juda ti gbà láti túnṣe.