Fò sí àkóónú

circa 930–586 BC

The Divided Kingdom

The kingdom splits into Israel and Judah; prophets warn of judgment as both nations slowly drift into idolatry and exile.

1,722 ẹsẹ · 3 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. 2 Kronika 30:18nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú Efraimu àti Manase, Isakari, àti Sebuluni kò sá wẹ̀ ara wọn mọ́ síbẹ̀ wọ́n jẹ ìrékọjá náà, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́. Ṣùgbọ́n Hesekiah bẹ̀bẹ̀ fún wọn, wí pé, Olúwa, ẹni rere, dáríjì olúkúlùkù,

  2. 2 Kronika 30:19nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    tí ó múra ọkàn rẹ̀ láti wá Ọlọ́run, Olúwa Ọlọ́run àwọn baba rẹ̀ ṣùgbọ́n tí kì í ṣe nípa ìwẹ̀nùmọ́ mímọ́

  3. 2 Kronika 30:20nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Olúwa sì gbọ́ ti Hesekiah, ó sì mú àwọn ènìyàn náà láradá.

  4. 2 Kronika 30:21nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọ Israẹli tí a rí ní Jerusalẹmu fi ayọ̀ ńlá pa àjọ àkàrà àìwú mọ́ ní ọjọ́ méje: àwọn ọmọ Lefi, àti àwọn àlùfáà yin Olúwa lójoojúmọ́, wọ́n ń fi ohun èlò olóhùn gooro kọrin sí Olúwa.

  5. 2 Kronika 30:22nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Hesekiah sọ̀rọ̀ ìtùnú fún gbogbo àwọn ọmọ Lefi, tí ó lóye ní ìmọ̀ rere Olúwa: ọjọ́ méje ni wọ́n fi jẹ àsè náà wọ́n rú ẹbọ àlàáfíà, wọ́n sì ń fi ohùn rara dúpẹ́ fún Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba wọn.

  6. 2 Kronika 30:23nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Gbogbo ìjọ náà sì gbìmọ̀ láti pa ọjọ́ méje mìíràn mọ́: wọ́n sì fi ayọ̀ pa ọjọ́ méje mìíràn mọ́.

  7. 2 Kronika 30:24nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Nítorí Hesekiah, ọba Juda, ta ìjọ ènìyàn náà ní ọrẹ, ẹgbẹ̀rún (1,000) akọ màlúù, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) àgùntàn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn àlùfáà sì ya ara wọn sí mímọ́.

  8. 2 Kronika 30:25nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Gbogbo ìjọ ènìyàn Juda pẹ̀lú àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi, àti gbogbo ìjọ ènìyàn tí ó ti inú Israẹli jáde wá, àti àwọn àjèjì tí ó ti ilẹ̀ Israẹli jáde wá, àti àwọn tí ń gbé Juda yọ̀.

  9. 2 Kronika 30:26nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ni ayọ̀ ńlá sì wà ní Jerusalẹmu: nítorí láti ọjọ́ Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israẹli, irú èyí kò sí ní Jerusalẹmu.

  10. 2 Kronika 30:27nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Lefi dìde, wọ́n sì súre fún àwọn ènìyàn náà: a sì gbọ́ ohùn wọn, àdúrà wọn sì gòkè lọ si ibùgbé mímọ́ rẹ̀, àní sí ọ̀run.

  11. 2 Kronika 31:1nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ti dé òpin, àwọn ọmọ Israẹli tí ó wà níbẹ̀ jáde lọ sí àwọn ìlú Juda, wọ́n fọ́ àwọn òkúta ìyàsọ́tọ̀ sí wẹ́wẹ́, wọ́n gé àwọn ère Aṣerah lulẹ̀. Wọ́n ba àwọn ibi gíga jẹ́ àti àwọn pẹpẹ jákèjádò Juda àti Benjamini àti ní Efraimu àti Manase. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti pa gbogbo wọn run, àwọn ọmọ Israẹli padà sí ìlú wọn àti sí nǹkan ìní wọn.

  12. 2 Kronika 31:2nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Hesekiah fi lé àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi lọ́wọ́ sí àwọn ìpín olúkúlùkù wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà tàbí ará Lefi láti tẹ́ ẹbọ sísun àti ọrẹ ìdàpọ̀, láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ láti fi ọpẹ́ fún àti láti kọ àwọn orin ìyìn ní ẹnu-ọ̀nà ibùgbé Olúwa.

  13. 2 Kronika 31:3nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Ọba fi sílẹ̀ láti ara ohun ìní rẹ̀ fun ẹbọ sísun àárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́ àti fún ẹbọ sísun ní ọjọ́ ìsinmi, òṣùpá tuntun àti ní àjọ̀dún tí a yàn gẹ́gẹ́ bi a ti ṣe kọ ọ́ nínú òfin Olúwa.

  14. 2 Kronika 31:4nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Ó pàṣẹ fún àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Jerusalẹmu láti fi ìpín tí ó yẹ fún àlùfáà fún un àti àwọn ará Lefi, kí wọn kí ó lè fi ara wọn jì fún òfin Olúwa.

  15. 2 Kronika 31:5nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Ní kété tí àṣẹ náà jáde lọ, àwọn ọmọ Israẹli fi tìfẹ́tìfẹ́ fi àkọ́so ti ọkà wọn, ọtí tuntun, òróró àti oyin àti gbogbo ohun tí pápá mú jáde lélẹ̀. Wọ́n kó ọ̀pọ̀ iye, àti ìdámẹ́wàá gbogbo nǹkan wá.

  16. 2 Kronika 31:6nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọkùnrin Israẹli àti Juda ti gbe inú àwọn ìlú Juda pẹ̀lú mú ìdámẹ́wàá agbo ẹran àti ohun èlò àti ohun ọ̀sìn àti ìdámẹ́wàá ti àwọn nǹkan mímọ́ tí a ti yà sọ́tọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wọn, wọ́n sì kó wọn jọ ní òkìtì.

  17. 2 Kronika 31:7nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Wọ́n bẹ̀rẹ̀ ṣíṣe èyí ní oṣù kẹta, wọ́n sì parí ní oṣù keje.

  18. 2 Kronika 31:8nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí Hesekiah àti àwọn oníṣẹ́ rẹ̀ wá, tí wọ́n sì rí òkìtì náà, wọ́n yin Olúwa, pẹ̀lú ìbùkún àwọn ènìyàn rẹ̀ Israẹli.

  19. 2 Kronika 31:9nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Hesekiah béèrè lọ́wọ́ àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi nípa òkìtì;

  20. 2 Kronika 31:10nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    àti Asariah olórí àlùfáà ti ìdílé Sadoku sì dáhùn pé, “Ní ìwọ̀n ìgbà tí àwọn ènìyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní mú ìdáwó wọn wá sí ilé Olúwa àti ní èyí tí yóò tó jẹ àti ọ̀pọ̀ láti tọ́jú pamọ́ nítorí Olúwa ti bùkún àwọn ènìyàn rẹ̀, ó sì ṣẹ́kù lọ́pọ̀lọ́pọ̀.”

  21. 2 Kronika 31:11nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Hesekiah pàṣẹ láti tọ́jú àwọn yàrá ìṣúra nínú ilé Olúwa, wọ́n sì ṣe èyí.

  22. 2 Kronika 31:12nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà wọ́n mú ọrẹ àti ìdámẹ́wàá àti àwọn ẹ̀bùn tí a yà sí mímọ́ wọ ilé náà wá nítòótọ́. Lórí èyí tí Konaniah ọmọ Lefi, ń ṣe olórí, Ṣimei arákùnrin rẹ̀ ni igbákejì rẹ̀.

  23. 2 Kronika 31:13nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Jehieli, Asasiah, Nahati, Asaheli, Jerimoti, Josabadi, Elieli, Ismakia, Mahati àti Benaiah jẹ́ àwọn alábojútó lábẹ́ Konaniah àti Ṣimei arákùnrin rẹ̀ nípa ipá ọba Hesekiah àti Asariah olórí ti ó wà ní ìkáwọ́ ilé Ọlọ́run.

  24. 2 Kronika 31:14nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Kore ọmọ Imina ará Lefi olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà ìlà-oòrùn, wà ní ìkáwọ́ àwọn ọrẹ àtinúwá tí a fi fún Ọlọ́run, o ń pín ìdáwó tí a ṣe fún Olúwa pẹ̀lú àwọn ẹ̀bùn tí a yà sọ́tọ̀

  25. 2 Kronika 31:15nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Edeni, Miniamini, Jeṣua, Ṣemaiah, Amariah àti Ṣekaniah ràn án lọ́wọ́ tọkàntọkàn nínú àwọn ìlú àwọn àlùfáà tí ń dáwó fún àwọn àlùfáà ẹlẹgbẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, àgbà àti kékeré.