- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 970–930 BC
Solomon & The Temple
Solomon builds the great Temple in Jerusalem and rules with unprecedented wisdom and wealth before foreign gods divide his heart.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- 2 Kronika 1:17nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Wọ́n ra kẹ̀kẹ́ kan láti Ejibiti. Fún ẹgbẹ̀ta (600) ṣékélì fàdákà àti ẹṣin kan fún ọgọ́rin méjìdínláàádọ́ta. Wọ́n ko wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba mìíràn ti Hiti àti ti àwọn ará Aramu.
- 2 Kronika 2:1nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Solomoni pinnu láti kọ́ ilé fún orúkọ Olúwa àti ilé kan fún ìjọba rẹ̀
- 2 Kronika 2:2nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Solomoni sì yan ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà àádọ́rin (70,000) àwọn ọkùnrin láti ru ẹrù àti ọ̀kẹ́ mẹ́rin (80,000) àwọn ọkùnrin gẹ́gẹ́ bi olùgé-òkúta ní àwọn òkè àti ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógójì (36,000) gẹ́gẹ́ bí àwọn alábojútó lórí wọn.
- 2 Kronika 2:3nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Solomoni rán iṣẹ́ yìí sí Hiramu ọba Tire: “Rán àwọn igi kedari sí mi gẹ́gẹ́ bí o ti ṣe fún baba à mi Dafidi. Nígbà tí ó fi igi kedari ránṣẹ́ sí i láti kọ́ ààfin tí ó ń gbé.
- 2 Kronika 2:4nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Nísinsin yìí, èmi n kọ́ ilé kan fún orúkọ Olúwa Ọlọ́run mi àti láti yà á sí mímọ́ fún un àti láti sun tùràrí olóòórùn dídùn níwájú rẹ̀, fún gbígbé àkàrà ìfihàn ìgbàkúgbà, àti fún ṣíṣe ẹbọ sísun ní gbogbo àárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́ àti ní ọjọọjọ́ ìsinmi àti oṣù tuntun àti ní àjọ̀dún tí a yàn ti Olúwa Ọlọ́run wa. Èyí ni àṣẹ fún Israẹli láéláé.
- 2 Kronika 2:5nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
“Ilé Olúwa tí èmi yóò kọ́ yóò tóbi, nítorí pé Ọlọ́run wa tóbi ju gbogbo àwọn ọlọ́run mìíràn lọ.
- 2 Kronika 2:6nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n ta ni ó le è kọ́ ilé fún Olúwa, níwọ̀n ìgbà tí àwọn ọ̀run, àní ọ̀run àwọn ọ̀run tó ga jùlọ, kò le è gbà á? Ta ni èmi nígbà náà láti kọ́ ilé fún Olúwa, bí kò ṣe kìkì àti sun ẹbọ sun ẹbọ níwájú rẹ̀?
- 2 Kronika 2:7nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
“Nítorí náà, rán ọkùnrin kan sí mi, tí a kọ́ láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú wúrà àti fàdákà àti idẹ àti irin, àti ní àwọ̀ àlùkò àti àwọ̀ pupa fòò àti ní àwọ̀ ojú ọ̀run, tí ó jẹ́ onímọ̀ nínú iṣẹ́ igi gbígbẹ́ láti ṣiṣẹ́ ní Juda àti Jerusalẹmu pẹ̀lú àwọn onímọ̀ oníṣọ̀nà tí baba à mi Dafidi pèsè.
- 2 Kronika 2:8nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
“Fi ìtì igi kedari, junifa àti algumu ránṣẹ́ sí mi, láti Lebanoni, nítorí tí mo mọ̀ pé àwọn ọkùnrin rẹ ní ìmọ̀ nínú gígé igi rírẹ́. Àwọn ọkùnrin mi yóò ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ọkùnrin rẹ.
- 2 Kronika 2:9nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Láti pèsè ọ̀pọ̀ igi rírẹ́ fún mi, nítorí ilé Olúwa tí mo kọ́ gbọdọ̀ tóbi kí o sì lógo púpọ̀.
- 2 Kronika 2:10nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Èmi yóò fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ọkùnrin agégi tí ó ń gé ìtì igi náà ni ogún ẹgbẹ̀rún (20,000), alikama ilẹ̀ àti ogún ẹgbẹ̀rún (20,000), ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti barle; ogún ẹgbẹ̀rún (20,000), bati ọtí wáìnì àti ogún ẹgbẹ̀rún (20,000) bati òróró olifi.”
- 2 Kronika 2:11nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Hiramu ọba Tire fèsì padà nípasẹ̀ ìwé sí Solomoni: “Nítorí tí Olúwa fẹ́ràn àwọn ènìyàn rẹ̀, ó ti ṣe ọ́ ní ọba wọn.”
- 2 Kronika 2:12nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Hiramu fi kún un pe, “Ìyìn ni fún Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, tí ó dá ọ̀run òun ayé! O ti fún ọba Dafidi ní ọmọ tí ó gbọ́n, tí ó kún fún ìmọ̀ àti òye, tí yóò kọ́ ilé fún Olúwa àti ààfin fún ara rẹ̀.
- 2 Kronika 2:13nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
“Èmi ń rán Huramu-Abi, ọkùnrin tí ó kún fún ìmọ̀ àti òye sí ọ.
- 2 Kronika 2:14nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Ọmọbìnrin kan nínú àwọn ọmọbìnrin Dani àti tí baba a rẹ̀ wá láti Tire tí ó gbọ́ngbọ́n àti ṣiṣẹ́ ní wúrà àti ní fàdákà, ní idẹ, ní irin, ní òkúta àti ní ìtì igi, ní èse-àlùkò, ní aláró, àti ní ọ̀gbọ̀ tí ó dára, àti òdòdó, láti gbẹ́ onírúurú ohun gbígbẹ́ pẹ̀lú, àti láti ṣe àwárí ìmọ̀ ẹ̀rọ irú ẹ̀yàkẹ́yà tí a ó fún un ṣe. Òun yóò ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ọlọ́gbọ́n rẹ̀, àti pẹ̀lú àwọn ọlọ́gbọ́n olúwa mi, Dafidi baba a rẹ.
- 2 Kronika 2:15nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
“Nísinsin yìí, jẹ́ kí olúwa mi rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní alikama àti barle àti òróró Olifi náà àti ọtí tí ó ti ṣe ìlérí.
- 2 Kronika 2:16nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Àwa yóò sì gé gbogbo àwọn ìtí igi láti Lebanoni tí ìwọ yóò lò pẹ̀lú a ó gbé wọn fò lójú omi òkun lọ sí Joppa. Lẹ́yìn náà ìwọ lè kó wọn gòkè lọ sí Jerusalẹmu.”
- 2 Kronika 2:17nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Solomoni ka iye àwọn àjèjì tí ó wà ní Israẹli lẹ́yìn kíka iye wọn tí baba a rẹ̀ Dafidi ti ṣe; a sì ka iye wọn sí ọ̀kẹ́ mẹ́jọ ó dín egbèjìlélọ́gbọ̀n (153,600).
- 2 Kronika 2:18nǹkan bí 1015 ṣáájú Kristi
Ó sì yan ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà àádọ́rin (70,000) nínú wọn láti ru ẹrù, àti ọ̀kẹ́ mẹ́rin (80,000) láti ṣe àgọ́ òkúta lórí òkè, àti egbèjìdínlógún (3,600) alábojútó láti kó àwọn ènìyàn ṣiṣẹ́.
- 2 Kronika 3:1nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi
Nígbà náà, Solomoni bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́ ilé Olúwa ní Jerusalẹmu lórí òkè Moria, níbi tí Olúwa ti farahan baba a rẹ̀ Dafidi. Ní orí ilẹ̀ ìpakà Arauna ará Jebusi, ibi tí Dafidi pèsè.
- 2 Kronika 3:2nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi
Ó bẹ̀rẹ̀ sí kíkọ́ rẹ̀ ní ọjọ́ kejì oṣù kejì ní ọdún kẹrin ìjọba rẹ̀.
- 2 Kronika 3:3nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi
Ìpìlẹ̀ tí Solomoni gbé kalẹ̀ fún kíkọ́ ilé Ọlọ́run jẹ́ ọgọ́ta gígùn ìgbọ̀nwọ́ àti ogún fífẹ̀ ìgbọ̀nwọ́.
- 2 Kronika 3:4nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi
Ìloro tí ó wà níwájú ilé Olúwa náà jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn rékọjá fífẹ̀ ilé náà àti gíga rẹ̀ jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn rékọjá fífẹ̀ ilé náà àti gíga rẹ̀ jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́. Ó tẹ́ inú rẹ̀ pẹ̀lú kìkì wúrà.
- 2 Kronika 3:5nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi
Ó fi igi firi bo ilé yàrá ńlá náà ó sì bò ó pẹ̀lú kìkì wúrà, ó sì ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú igi ọ̀pẹ àti àwòrán ẹ̀wọ̀n.
- 2 Kronika 3:6nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi
Ó ṣe ilé Olúwa náà lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú òkúta iyebíye. Wúrà tí ó lò jẹ́ wúrà parifaimu.