- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 970–930 BC
Solomon & The Temple
Solomon builds the great Temple in Jerusalem and rules with unprecedented wisdom and wealth before foreign gods divide his heart.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- 2 Kronika 3:7nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi
Ó tẹ́ àjà ilé náà pẹ̀lú ìtí igi àti ìlẹ̀kùn ògiri àti àwọn ìlẹ̀kùn ilé Olúwa pẹ̀lú wúrà, ó sì gbẹ́ àwòrán kérúbù sára ògiri.
- 2 Kronika 3:8nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi
Ó kọ́ Ibi Mímọ́ Jùlọ, gígùn rẹ̀ bá fífẹ̀ ilé Olúwa mu, ogún ìgbọ̀nwọ́ fún gígùn, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́, ó tẹ́ inú rẹ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ̀ta (600) tálẹ́ǹtì ti wúrà dáradára.
- 2 Kronika 3:9nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi
Ìwọ̀n àwọn ìṣó náà jẹ́ àádọ́ta ṣékélì. Ó tẹ́ àwọn apẹ òkè pẹ̀lú wúrà.
- 2 Kronika 3:10nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi
Ní Ibi Mímọ́ Jùlọ, ó gbẹ́ àwòrán igi kérúbù kan, ó sì tẹ́ wọn pẹ̀lú wúrà.
- 2 Kronika 3:11nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi
Iye ìyẹ́ apá ìbú àtẹ́lẹwọ́ lápapọ̀ ní ti kérúbù, jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́ ọ̀kan nínú ìyẹ́ apá ti kérúbù àkọ́kọ́ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn, ó sì farakan ògiri ilé Olúwa. Nígbà tí ìyẹ́ apá kejì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn ó sì, farakan ìyẹ́ apá kérúbù mìíràn.
- 2 Kronika 3:12nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi
Ní ìjọra, ìyẹ́ apá kan ti kérúbù kejì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn, ó sì farakan ògiri ilé Olúwa mìíràn; ìyẹ́ apá rẹ̀ mìíràn sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn ní gígùn pẹ̀lú tí ó farakan ìyẹ́ apá kérúbù àkọ́kọ́.
- 2 Kronika 3:13nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi
Ìyẹ́ apá àwọn kérúbù wọ̀nyí gbà tó ogún ìgbọ̀nwọ́. Wọ́n dúró ní ẹsẹ̀ wọn, wọ́n kọjú sí yàrá pàtàkì ńlá náà.
- 2 Kronika 3:14nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi
Ó ṣe aṣọ títa ní àwọ̀ ojú ọ̀run, àwọ̀ àlùkò àti àwọ̀ pupa fòò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ pẹ̀lú kérúbù tí a ṣe sórí i rẹ̀.
- 2 Kronika 3:15nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi
Níwájú ilé Olúwa náà ó ṣe òpó méjì tí lápapọ̀ jẹ́ márùn-ún dín lógójì ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, olúkúlùkù pẹ̀lú olórí lórí rẹ̀ tí o ń wọn ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún.
- 2 Kronika 3:16nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi
Ó ṣe ẹ̀wọ̀n tí a hun wọ inú ara wọn, ó gbé wọn ká orí òpó náà. Ó ṣe ọgọ́rùn-ún pomegiranate (orúkọ èso igi) ó sì so wọ́n mọ́ àwọn ẹ̀wọ̀n náà
- 2 Kronika 3:17nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi
Ó gbe òpó náà dúró níwájú ilé Olúwa, ọ̀kan sí gúúsù, pẹ̀lú ọ̀kan sí àríwá. Èyí ti gúúsù, ó sọ ní Jakini àti èyí ti àríwá, ó sọ ní Boasi.
- 2 Kronika 4:1nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi
Ó ṣe pẹpẹ idẹ, ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ogún ìgbọ̀nwọ́ ní fífẹ̀ àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá fún gíga.
- 2 Kronika 4:2nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi
Ó ṣe agbada dídà ńlá tí ó rí róbótó tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá láti etí kan dé etí èkejì ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún sì ni gíga rẹ̀.
- 2 Kronika 4:3nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi
Lábẹ́ etí, àwòrán àwọn akọ màlúù yíká mẹ́wàá sí ìgbọ̀nwọ́ kan. Àwọn akọ màlúù náà ni á dá ní ọ̀nà méjì ní àwòrán kan pẹ̀lú okùn.
- 2 Kronika 4:4nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi
Okùn náà dúró lórí akọ màlúù méjìlá, mẹ́ta kọjú sí àríwá, mẹ́ta kọjú sí ìwọ̀-oòrùn, mẹ́ta kọjú sí gúúsù mẹ́ta kọjú sí ìlà-oòrùn. Òkun náà sì sinmi lórí wọn àti gbogbo ìhà ẹ̀yìn wọn sì wà ní apá àárín.
- 2 Kronika 4:5nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi
Ó nípọn tó ìbú àtẹ́lẹwọ́, etí rẹ̀ sì dàbí etí ife ìmumi, bí i ìtànná lílì ó sì dá ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) bati dúró.
- 2 Kronika 4:6nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi
Ó ṣe ọpọ́n mẹ́wàá fún fífọ nǹkan, ó sì gbé márùn-ún ka ìhà gúúsù àti márùn-ún ní àríwá. Nínú wọn ni ó ti ń fọ àwọn nǹkan tí wọ́n ń lò fún ẹbọ sísun ṣùgbọ́n, àwọn àlùfáà ní ó ń lo Òkun fún fífọ nǹkan.
- 2 Kronika 4:7nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi
Ó ṣe ìgbé fìtílà dúró mẹ́wàá ti wúrà gẹ́gẹ́ bí èyí tí a yàn fún wọn. A sì gbé wọn kalẹ̀ sínú ilé Olúwa márùn un ní ìhà gúúsù àti márùn-ún ní ìhà àríwá.
- 2 Kronika 4:8nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi
Ó ṣé tábìlì mẹ́wàá, ó sì gbé wọn sí inú ilé Olúwa, márùn un ní gúúsù àti márùn-ún ní ìhà àríwá. Ó ṣé ọgọ́rùn-ún ọpọ́n ìbùwọ́n wúrà.
- 2 Kronika 4:9nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi
Ó ṣe àgbàlá àwọn àlùfáà àti ààfin ńlá àti àwọn ìlẹ̀kùn fún ààfin, ó sì tẹ́ àwọn ìlẹ̀kùn náà pẹ̀lú idẹ.
- 2 Kronika 4:10nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi
Ó gbé Òkun náà ka orí ìhà gúúsù ní ẹ̀bá igun gúúsù àríwá.
- 2 Kronika 4:11nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi
Huramu ṣe àwọn ìkòkò pẹ̀lú, àti ọkọ́ àti àwọn ọpọ́n ìbùwọ́n. Bẹ́ẹ̀ ni Huramu parí iṣẹ́ tí ó ti dáwọ́lé fún ọba Solomoni ní ilé Ọlọ́run.
- 2 Kronika 4:12nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi
Àwọn ọ̀wọ́n méjì; ọpọ́n méjì ìparí tí ó wà lókè àwọn ọ̀wọ́n iṣẹ́; àwọn méjì ní láti bo ọpọ́n méjì ìparí tí ń bẹ lókè àwọn ọ̀wọ́n;
- 2 Kronika 4:13nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi
irinwó (400) pomegiranate fún iṣẹ́ ẹ̀wọ̀n méjì náà, ẹsẹ̀ méjì pomegiranate ni fún iṣẹ́ ẹ̀wọ̀n kan, láti bo ọpọ́n rìbìtì méjì náà tí ó wà lórí àwọn òpó náà;
- 2 Kronika 4:14nǹkan bí 1011 ṣáájú Kristi
ó sì ṣe àgbéró ó sì ṣe agbada sí orí wọn;