Fò sí àkóónú

circa AD 48–96

Letters to the Churches

Paul and other apostles write to strengthen, correct, and encourage the scattered churches across the Roman world.

2,767 ẹsẹ · 21 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. 2 Tẹsalonika 3:3nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n olódodo ni Olúwa, ẹni tí yóò fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀, tí yóò sì pa yín mọ́ kúrò nínú ibi.

  2. 2 Tẹsalonika 3:4nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Àwa sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa ní ti ohun tí ẹ ń ṣe, àti pé àwọn nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí a pàṣẹ fún un yín ni ẹ̀yin ń ṣe.

  3. 2 Tẹsalonika 3:5nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Kí Olúwa máa tọ́ ọkàn yín ṣọ́nà sí ìfẹ́ Ọlọ́run àti sínú sùúrù Kristi.

  4. 2 Tẹsalonika 3:6nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Ní orúkọ Jesu Kristi Olúwa wa, àwa pàṣẹ fún un yín ará, pé kí ẹ yẹra fún gbogbo àwọn arákùnrin yín tí ń ṣe ìmẹ́lẹ́, tí kò sì gbé ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀kọ́ tí ẹ gbà ní ọ̀dọ̀ wa.

  5. 2 Tẹsalonika 3:7nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí ẹ̀yin náà mọ̀ bí ó ṣe yẹ kí ẹ máa fi ara wé wa. Àwa kì í ṣe ìmẹ́lẹ́ nígbà tí a wà ní ọ̀dọ̀ yín.

  6. 2 Tẹsalonika 3:8nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Bẹ́ẹ̀ ni àwa kò sì jẹ oúnjẹ ẹnikẹ́ni lọ́fẹ̀ẹ́. Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, àwa ń ṣiṣẹ́ tọ̀sán tòru kí a má ba à di àjàgà sí ẹnikẹ́ni nínú yín lọ́rùn.

  7. 2 Tẹsalonika 3:9nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Àwa ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, kì í ṣe nítorí pé àwa kò ní ẹ̀tọ́ láti béèrè fún un, ṣùgbọ́n àwa ń fi ara wa ṣe àpẹẹrẹ tí ẹ ó tẹ̀lé.

  8. 2 Tẹsalonika 3:10nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí nígbà tí àwa wà lọ́dọ̀ yín, a ṣe àwọn òfin wọ̀nyí fún un yín pé, “Bí ẹnikẹ́ni kò bá fẹ́ ṣiṣẹ́, kí ó má ṣe jẹun.”

  9. 2 Tẹsalonika 3:11nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    A gbọ́ pé àwọn kan wà láàrín yín tí wọn jẹ́ ìmẹ́lẹ́. Wọ́n jẹ́ atọjúlékiri.

  10. 2 Tẹsalonika 3:12nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Ǹjẹ́ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni àwa ń pàṣẹ fún, tí a sì ń rọ̀ nínú Jesu Kristi Olúwa pé kí wọn ó máa ṣiṣẹ́ fún oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ.

  11. 2 Tẹsalonika 3:13nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n ní tiyín ará, ẹ má ṣe jẹ́ kí agara dá yín ní rere ṣíṣe.

  12. 2 Tẹsalonika 3:14nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Bí ẹnikẹ́ni kò bá sì pa òfin wa nínú lẹ́tà yìí mọ́, ẹ sàmì sí ẹni náà. Ẹ má ṣe bá a kẹ́gbẹ́ kí ojú bà á le tì í.

  13. 2 Tẹsalonika 3:15nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Síbẹ̀, ẹ má ṣe kà á sí ọ̀tá, ṣùgbọ́n ẹ máa kìlọ̀ fún un gẹ́gẹ́ bí arákùnrin yín.

  14. 2 Tẹsalonika 3:16nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Ǹjẹ́ kí Olúwa àlàáfíà, fúnra rẹ̀ máa fún yín ní àlàáfíà nígbà gbogbo. Kí Olúwa kí ó wà pẹ̀lú gbogbo yín.

  15. 2 Tẹsalonika 3:17nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Èmi Paulu fi ọwọ́ ara mi kọ lẹ́tà ìkíni yìí, èyí ṣe àmì ìdámọ̀ nínú gbogbo lẹ́tà. Bí mo ṣe máa ń kọ̀wé nìyìí.

  16. 2 Tẹsalonika 3:18nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Kí oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa wa wà pẹ̀lú yín.

  17. 1 Timotiu 1:1nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Paulu, aposteli Kristi Jesu gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Ọlọ́run Olùgbàlà wa, àti Jesu Kristi ìrètí wa,

  18. 1 Timotiu 1:2nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Sí Timotiu ọmọ mi nínú ìgbàgbọ́: Oore-ọ̀fẹ́, àánú àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba àti Jesu Kristi Olúwa wa.

  19. 1 Timotiu 1:3nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Bí mo ṣe rọ̀ yìn nígbà tí mò ń lọ sí Makedonia, ẹ dúró ní Efesu, kí ẹ lè dá àwọn ènìyàn kan lẹ́kun láti má ṣe kọ́ ni ní ẹ̀kọ́ èké mọ́

  20. 1 Timotiu 1:4nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    kí wọ́n má sì ṣe fiyèsí àwọn ìtàn asán, àti ìtàn ìran aláìlópin. Irú èyí máa ń mú iyàn jíjà wá dípò iṣẹ́ ìríjú Ọlọ́run èyí tí í ṣe ti ìgbàgbọ́.

  21. 1 Timotiu 1:5nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Ète àṣẹ náà ni ìfẹ́ ti ń jáde wá láti inú ọkàn mímọ́ àti ẹ̀rí ọkàn rere àti ìgbàgbọ́ àìṣẹ̀tàn.

  22. 1 Timotiu 1:6nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn ẹlòmíràn ti yapa kúrò tí wọ́n sì yà sápá kan sí ọ̀rọ̀ asán.

  23. 1 Timotiu 1:7nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Wọ́n ń fẹ́ ṣe olùkọ́ òfin; òye ohun tí wọ́n ń wí kò yé wọn tàbí ti ohun tí wọ́n ń fi ìgboyà tẹnumọ́.

  24. 1 Timotiu 1:8nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n àwa mọ̀ pé òfin dára, bí ènìyàn bá lò ó dáradára.

  25. 1 Timotiu 1:9nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Bí a ti mọ̀ pé, a kò ṣe òfin fún olódodo, bí kò ṣe fún àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, fún àwọn aláìmọ́ àti àwọn ẹlẹ́gàn, fún àwọn tí ń pa baba àti àwọn tí ń pa ìyá wọn àti àwọn apànìyàn,