Fò sí àkóónú

circa AD 48–96

Letters to the Churches

Paul and other apostles write to strengthen, correct, and encourage the scattered churches across the Roman world.

2,767 ẹsẹ · 21 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. 1 Tẹsalonika 5:10nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Jesu kú fún wa kí a lè ba à gbé títí láéláé. Èyí yóò rí bẹ́ẹ̀ yálà a sùn tàbí a wà láààyè pẹ̀lú rẹ̀.

  2. 1 Tẹsalonika 5:11nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà, ẹ máa gba ara yín níyànjú, kí ẹ sì máa gbé ara yín ró, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ń ṣe.

  3. 1 Tẹsalonika 5:12nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ̀yin ará, ẹ fi ọlá fún àwọn olórí tí ń ṣe iṣẹ́ àṣekára láàrín yín tí wọn ń kìlọ̀ fún yín nínú Olúwa.

  4. 1 Tẹsalonika 5:13nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ bu ọlá fún wọn gidigidi nínú ìfẹ́, nítorí iṣẹ́ wọn. Ẹ sì máa wà ní àlàáfíà láàrín ara yín.

  5. 1 Tẹsalonika 5:14nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ̀yin ará mi, ẹ kìlọ̀ fún àwọn ọ̀lẹ ti ó wà láàrín yín, ẹ gba àwọn tí ẹ̀rù ń bà ní ìyànjú, ẹ tọ́jú àwọn aláìlera pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, kí ẹ sì ní sùúrù pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.

  6. 1 Tẹsalonika 5:15nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ rí i pé kò sí ẹni tí ó fi búburú san búburú, ṣùgbọ́n ẹ máa lépa èyí tí í ṣe rere láàrín ara yín àti sí ènìyàn gbogbo.

  7. 1 Tẹsalonika 5:16nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo.

  8. 1 Tẹsalonika 5:17nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ máa gbàdúrà nígbà gbogbo.

  9. 1 Tẹsalonika 5:18nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ máa dúpẹ́ nígbà gbogbo nínú ipòkípò tí o wù kí ẹ wà; nítorí pé, èyí ni ìfẹ́ Ọlọ́run fún yin nínú Kristi Jesu nítòótọ́.

  10. 1 Tẹsalonika 5:19nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ má ṣe pa iná Ẹ̀mí Mímọ́.

  11. 1 Tẹsalonika 5:20nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ má ṣe kẹ́gàn àwọn ti ń sọtẹ́lẹ̀.

  12. 1 Tẹsalonika 5:21nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n ẹ dán gbogbo nǹkan wò. Ẹ di èyí tí ṣe òtítọ́ mú.

  13. 1 Tẹsalonika 5:22nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ yẹra fún ohunkóhun tí í ṣe ibi.

  14. 1 Tẹsalonika 5:23nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Kí Ọlọ́run fúnra rẹ̀, Ọlọ́run àlàáfíà, sọ yín di mímọ́ pátápátá. Kí Ọlọ́run pa ẹ̀mí àti ọkàn pẹ̀lú ara yín mọ́ pátápátá ní àìlábùkù, títí di ìgbà wíwá Jesu Kristi Olúwa wa.

  15. 1 Tẹsalonika 5:24nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Olóòtítọ́ ni ẹni tí ó pè yín, yóò sì ṣe.

  16. 1 Tẹsalonika 5:25nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ̀yin ará, ẹ gbàdúrà fún wa.

  17. 1 Tẹsalonika 5:26nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ fi ìfẹ́nukonu mímọ́ ki ara yin.

  18. 1 Tẹsalonika 5:27nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Mo pàṣẹ fún yín níwájú Olúwa pé, kí ẹ ka lẹ́tà yìí fún gbogbo àwọn ará.

  19. 1 Tẹsalonika 5:28nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Ki oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa wa, wà pẹ̀lú yín.

  20. 2 Tẹsalonika 1:1nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Paulu, Sila àti Timotiu, Sí ìjọ Tẹsalonika, nínú Ọlọ́run Baba wa àti Jesu Kristi Olúwa:

  21. 2 Tẹsalonika 1:2nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba àti Jesu Kristi Olúwa.

  22. 2 Tẹsalonika 1:3nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Ó yẹ kí a máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà gbogbo nítorí yín, ará, àní gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ, nítorí pé ìgbàgbọ́ yín ń dàgbà gidigidi, àti ìfẹ́ olúkúlùkù yín sí ara yín ń di púpọ̀.

  23. 2 Tẹsalonika 1:4nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà, àwa tìkára wa ń fi yín ṣògo nínú ìjọ Ọlọ́run, nítorí sùúrù àti ìgbàgbọ́ yín nínú gbogbo inúnibíni àti wàhálà yín tí ẹ̀yin náà ń fi ara dà.

  24. 2 Tẹsalonika 1:5nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ẹ̀rí pé òdodo ni ìdájọ́ Ọlọ́run àti pé nítorí èyí ni a ó kà yín yẹ fún ìjọba Ọlọ́run, nítorí èyí tí ẹ̀yin pẹ̀lú ṣe ń jìyà.

  25. 2 Tẹsalonika 1:6nǹkan bí 54 lẹ́yìn Kristi

    Olódodo ni Ọlọ́run: Òun yóò pọ́n àwọn tí ń pọ́n yín lójú, lójú,