Fò sí àkóónú

circa AD 48–96

Letters to the Churches

Paul and other apostles write to strengthen, correct, and encourage the scattered churches across the Roman world.

2,767 ẹsẹ · 21 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. 1 Timotiu 1:10nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    fún àwọn àgbèrè, fún àwọn aláyídà, fún àwọn onísòwò-ẹrú, fún àwọn èké, fún àwọn abúra èké, àti bí ohun mìíràn bá wà tí ó lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro.

  2. 1 Timotiu 1:11nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Gẹ́gẹ́ bí ìyìnrere ti ògo Ọlọ́run olùbùkún, tí a fi sí ìtọ́jú mi.

  3. 1 Timotiu 1:12nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹni tí ó fún mi ní agbára, àní Kristi Jesu Olúwa wa, nítorí tí ó kà mí sí olóòtítọ́ ní yíyànmí sí iṣẹ́ rẹ̀.

  4. 1 Timotiu 1:13nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Bí mo tilẹ̀ jẹ́ asọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run rí, àti onínúnibíni àti ìkà ènìyàn, ṣùgbọ́n mo rí àánú gbà, nítorí tí mo ṣe é nínú àìmọ̀ àti àìgbàgbọ́.

  5. 1 Timotiu 1:14nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Oore-ọ̀fẹ́ Olúwa wa sì pọ̀ rékọjá pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́, tí ń bẹ nínú Kristi Jesu.

  6. 1 Timotiu 1:15nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà, ó sì yẹ fún ìtẹ́wọ́gbà, pé Jesu Kristi wá sí ayé láti gba ẹlẹ́ṣẹ̀ là; nínú àwọn ẹni tí èmi jẹ́ búburú jùlọ.

  7. 1 Timotiu 1:16nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n nítorí èyí ni mo ṣe rí àánú gbà, pé lára mi, bí olórí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni kí Jesu Kristi fi gbogbo ìpamọ́ra rẹ̀ hàn bí àpẹẹrẹ fún àwọn tí yóò gbà á gbọ́ sí ìyè àìnípẹ̀kun ìkẹyìn.

  8. 1 Timotiu 1:17nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Ǹjẹ́ fún ọba ayérayé, àìdíbàjẹ́, àìrí, Ọlọ́run kan ṣoṣo, ni ọlá àti ògo wà fún láéláé. Àmín.

  9. 1 Timotiu 1:18nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Àṣẹ yìí ni mo pa fún ọ, Timotiu ọmọ mi, gẹ́gẹ́ bí ìsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí tó ó ti ṣáájú nípa rẹ̀, pé nípasẹ̀ wọ́n kí ìwọ lè máa ja ìjà rere;

  10. 1 Timotiu 1:19nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    máa ní ìgbàgbọ́ àti ẹ̀rí ọkàn rere. Èyí ti àwọn mìíràn ti mú kúrò lọ́dọ̀ wọn tí wọ́n sì rí ọkàn ìgbàgbọ́ wọn.

  11. 1 Timotiu 1:20nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Nínú àwọn ẹni tí Himeneu àti Aleksanderu wà; àwọn tí mo ti fi lé Satani lọ́wọ́, kí a lè kọ́ wọn kí wọ́n má sọ̀rọ̀-òdì mọ́.

  12. 1 Timotiu 2:1nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà mo gbà yín níyànjú ṣáájú ohun gbogbo, pé kí a máa bẹ̀bẹ̀, kí a máa gbàdúrà, kí a máa ṣìpẹ̀, àti kí a máa dúpẹ́ nítorí gbogbo ènìyàn.

  13. 1 Timotiu 2:2nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Fún àwọn ọba, àti gbogbo àwọn tí ó wà ni ipò àṣẹ, kí a lè máa lo ayé wa ní àlàáfíà àti ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ pẹ̀lú nínú gbogbo ìwà-bí-Ọlọ́run àti ìwà mímọ́.

  14. 1 Timotiu 2:3nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí èyí dára, ó sì ṣe ìtẹ́wọ́gbà níwájú Ọlọ́run Olùgbàlà wa;

  15. 1 Timotiu 2:4nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    ẹni tí ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn ní ìgbàlà kí wọ́n sì wá sínú ìmọ̀ òtítọ́.

  16. 1 Timotiu 2:5nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí Ọlọ́run kan ní ń bẹ, onílàjà kan pẹ̀lú láàrín Ọlọ́run àti ènìyàn, àní Kristi Jesu ọkùnrin náà.

  17. 1 Timotiu 2:6nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Ẹni ti ó fi ara rẹ̀ ṣe ìràpadà fún gbogbo ènìyàn—ẹ̀rí tí a fi fún ni ní àkókò tó yẹ.

  18. 1 Timotiu 2:7nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí èyí tí a yàn mi ṣe oníwàásù, aposteli òtítọ́ ni èmi ń sọ, èmi kò ṣèké olùkọ́ àwọn aláìkọlà nínú ìgbàgbọ́ àti òtítọ́.

  19. 1 Timotiu 2:8nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Mo fẹ́ kí àwọn ọkùnrin máa gbàdúrà níbi gbogbo, kí wọ́n máa gbé ọwọ́ mímọ́ sókè, ní àìbínú àti àìjiyàn.

  20. 1 Timotiu 2:9nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni kí àwọn obìnrin fi aṣọ ìwọ̀ntúnwọ̀nsì ṣe ara wọn ní ọ̀ṣọ́, ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì àti pẹ̀lú ìwà àìrékọjá; kì í ṣe pẹ̀lú irun dídì, tàbí wúrà, tàbí peali, tàbí aṣọ olówó iyebíye,

  21. 1 Timotiu 2:10nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    bí kò ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ rere, èyí tí ó yẹ fún àwọn obìnrin tó jẹ́wọ́ pé wọ́n sin Ọlọ́run.

  22. 1 Timotiu 2:11nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Jẹ́ kí obìnrin máa fi ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìtẹríba gbogbo kọ́ ẹ̀kọ́.

  23. 1 Timotiu 2:12nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n èmi kò fi àṣẹ fún obìnrin láti máa kọ́ni, tàbí láti pàṣẹ lórí ọkùnrin, bí kò ṣe kí ó dákẹ́ jẹ́ẹ́.

  24. 1 Timotiu 2:13nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí Adamu ni a kọ́ dá, lẹ́yìn náà, Efa.

  25. 1 Timotiu 2:14nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Adamu kọ́ ni a tànjẹ, ṣùgbọ́n obìnrin náà ni a tàn tí ó sì di ẹlẹ́ṣẹ̀.