Fò sí àkóónú

circa AD 48–96

Letters to the Churches

Paul and other apostles write to strengthen, correct, and encourage the scattered churches across the Roman world.

2,767 ẹsẹ · 21 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. 1 Timotiu 4:9nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà, ó sì yẹ fún ìtẹ́wọ́gbà gbogbo.

  2. 1 Timotiu 4:10nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí fún èyí ni àwa ń ṣe làálàá tí a sì ń jìjàkadì, nítorí àwa ní ìrètí nínú Ọlọ́run alààyè, ẹni tí í ṣe Olùgbàlà gbogbo ènìyàn, pẹ̀lúpẹ̀lú ti àwọn ti ó gbàgbọ́.

  3. 1 Timotiu 4:11nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Nǹkan wọ̀nyí ni kí ó máa paláṣẹ kí ó máa kọ́ni.

  4. 1 Timotiu 4:12nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni gan ìgbà èwe rẹ; ṣùgbọ́n kì ìwọ jẹ́ àpẹẹrẹ fún àwọn tí ó gbàgbọ́, nínú ọ̀rọ̀, nínú ìwà híhù, nínú ìfẹ́, nínú ẹ̀mí, nínú ìgbàgbọ́, nínú ìwà mímọ́.

  5. 1 Timotiu 4:13nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Títí èmi ó fi dé, máa fiyèsí kíkàwé àti ìgbaniníyànjú àti ìkọ́ni.

  6. 1 Timotiu 4:14nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Má ṣe àìnání ẹ̀bùn tí ń bẹ lára rẹ, èyí tí a fi fún ọ nípa ìsọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú ìgbọ́wọ́lé àwọn alàgbà.

  7. 1 Timotiu 4:15nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Máa fiyèsí nǹkan wọ̀nyí; fi ara rẹ fún wọn pátápátá; kí ìlọsíwájú rẹ lè hàn gbangba fún gbogbo ènìyàn.

  8. 1 Timotiu 4:16nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Máa ṣe ìtọ́jú ará rẹ àti ẹ̀kọ́ rẹ; máa dúró láìyẹsẹ̀ nínú nǹkan wọ̀nyí; nítorí ní ṣíṣe èyí, ìwọ ó gba ara rẹ àti tí àwọn ti ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ là.

  9. 1 Timotiu 5:1nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Má ṣe bá àgbàlagbà ọkùnrin wí, ṣùgbọ́n kí ó máa gbà á níyànjú bí i baba; àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin bí arákùnrin.

  10. 1 Timotiu 5:2nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn àgbàlagbà obìnrin bí ìyá; àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin bí arábìnrin nínú ìwà mímọ́.

  11. 1 Timotiu 5:3nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Bọ̀wọ̀ fún àwọn opó ti í ṣe opó nítòótọ́.

  12. 1 Timotiu 5:4nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n bí opó kan bá ni ọmọ tàbí ọmọ ọmọ, jẹ́ kí wọn kọ́kọ́ kọ́ bí a ti ń ṣe ìtọ́jú ilé àwọn tìkára wọn, kí wọn sì san oore àwọn òbí wọn padà; nítorí pé èyí ni ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà níwájú Ọlọ́run.

  13. 1 Timotiu 5:5nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Ǹjẹ́ ẹni ti í ṣe opó nítòótọ́, ti ó ṣe òun nìkan, a máa gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run, a sì máa dúró nínú ẹ̀bẹ̀ àti nínú àdúrà lọ́sàn àti lóru.

  14. 1 Timotiu 5:6nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá fi ara rẹ fún ayé jíjẹ, ó kú nígbà tí ó wà láààyè.

  15. 1 Timotiu 5:7nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Nǹkan wọ̀nyí ni kí wọn máa paláṣẹ, kí wọn lè wà láìlẹ́gàn.

  16. 1 Timotiu 5:8nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni kò bá pèsè fún àwọn tirẹ̀, pàápàá fún àwọn ará ilé rẹ̀, ó ti sẹ́ ìgbàgbọ́, ó burú ju aláìgbàgbọ́ lọ.

  17. 1 Timotiu 5:9nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Kọ orúkọ ẹni tí kò bá dín ni ọgọ́ta ọdún sílẹ̀ bí opó, lẹ́yìn ti ó ti jẹ́ aya ọkọ kan.

  18. 1 Timotiu 5:10nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Ẹni ti a jẹ́rìí rẹ̀ fún iṣẹ́ rere; bí ẹni ti ó ti tọ́ ọmọ dàgbà, ti ó ń ṣe ìtọ́jú àlejò, tí ó sì ń wẹ ẹsẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́, tí ó ti ran àwọn olùpọ́njú lọ́wọ́, tí ó sì ń lépa iṣẹ́ rere gbogbo.

  19. 1 Timotiu 5:11nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n ma ṣe kọ orúkọ àwọn opó tí kò dàgbà; nítorí pé nígbà tiwọn bá ti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ lòdì sí Kristi, wọn á tún fẹ́ láti gbéyàwó.

  20. 1 Timotiu 5:12nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Wọn á di ẹlẹ́bi, nítorí tí wọn ti kọ ìgbàgbọ́ wọn ìṣáájú sílẹ̀.

  21. 1 Timotiu 5:13nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Àti pẹ̀lú wọn ń kọ́ láti ṣe ọ̀lẹ, láti máa kiri láti ilédélé, kì í ṣe ọ̀lẹ nìkan, ṣùgbọ́n onísọkúsọ àti olófòófó pẹ̀lú, wọn a máa sọ ohun tí kò yẹ.

  22. 1 Timotiu 5:14nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà, mo fẹ́ kí àwọn opó tí kò dàgbà máa gbéyàwó, kí wọn máa bímọ, kí wọn máa ṣe alábojútó ilé, kí wọn má ṣe fi ààyè sílẹ̀ rárá fún ọ̀tá náà láti sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn.

  23. 1 Timotiu 5:15nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí àwọn mìíràn ti yípadà kúrò sí ẹ̀yìn Satani.

  24. 1 Timotiu 5:16nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Bí ọkùnrin tàbí obìnrin kan tí ó gbàgbọ́ bá ní àwọn opó, kí ó máa ràn wọ́n lọ́wọ́, kí a má sì di ẹrù lé ìjọ, kí wọn lè máa ran àwọn ti í ṣe opó nítòótọ́ lọ́wọ́.

  25. 1 Timotiu 5:17nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn alàgbà ti ó ṣe àkóso dáradára ni kí a kà yẹ sí ọlá ìlọ́po méjì, pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ti ó ṣe làálàá ni ọ̀rọ̀ àti ni kíkọ́ni.