Fò sí àkóónú

circa AD 48–96

Letters to the Churches

Paul and other apostles write to strengthen, correct, and encourage the scattered churches across the Roman world.

2,767 ẹsẹ · 21 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. 1 Timotiu 5:18nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí tí Ìwé Mímọ́ wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ di màlúù ti ń tẹ ọkà lẹ́nu,” àti pé, “Ọ̀yà alágbàṣe tọ́ sí i.”

  2. 1 Timotiu 5:19nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Má ṣe gba ẹ̀sùn sí alàgbà kan, bí kò ṣe láti ẹnu ẹlẹ́rìí méjì mẹ́ta.

  3. 1 Timotiu 5:20nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Bá àwọn tí ó ṣẹ̀ wí níwájú gbogbo ènìyàn, kí àwọn ìyókù pẹ̀lú bà á lè bẹ̀rù.

  4. 1 Timotiu 5:21nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Mo pàṣẹ fún ọ níwájú Ọlọ́run, àti Kristi Jesu, àti àwọn angẹli àyànfẹ́ kí ìwọ máa ṣàkíyèsí nǹkan wọ̀nyí, láìṣe ojúsàájú, láti fi ègbè ṣe ohunkóhun.

  5. 1 Timotiu 5:22nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Má ṣe fi ìkánjú gbe ọwọ́ lé ẹnikẹ́ni, bẹ́ẹ̀ ni kí ó má sì ṣe jẹ́ alábápín nínú ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹlòmíràn, pa ara rẹ mọ́ ní ìwà mímọ́.

  6. 1 Timotiu 5:23nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Ma ṣe máa mu omi nìkan, ṣùgbọ́n máa lo wáìnì díẹ̀ nítorí inú rẹ, àti nítorí àìlera ìgbàkúgbà.

  7. 1 Timotiu 5:24nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹlòmíràn a máa hàn gbangba, a máa lọ ṣáájú sí ìdájọ́; tí àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú a sì máa tẹ̀lé wọn.

  8. 1 Timotiu 5:25nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ pẹ̀lú ni iṣẹ́ rere wa máa ń hàn gbangba; bí wọn kò tilẹ̀ tí ì hàn, wọn kò lè fi ara sin títí.

  9. 1 Timotiu 6:1nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí i ṣe ẹrú lábẹ́ ìsìnrú máa ka àwọn olówó tí ó ni wọ́n yẹ sí ọlá gbogbo, kí a má bà á sọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ Ọlọ́run àti ẹ̀kọ́ rẹ̀.

  10. 1 Timotiu 6:2nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn ti ó ní ọ̀gá onígbàgbọ́, kí wọn má ṣe ṣàìbọ̀wọ̀ fún wọn nítorí tí wọn jẹ́ arákùnrin; ṣùgbọ́n kí wọn túbọ̀ máa sìn wọ́n, nítorí àwọn tí í ṣe alábápín iṣẹ́ rere wọn jẹ́ onígbàgbọ́ àti olùfẹ́. Nǹkan wọ̀nyí ni kí ó máa kọ́ ni, kí o sì máa fi gbani níyànjú.

  11. 1 Timotiu 6:3nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Bí ẹnikẹ́ni bá ń kọ́ni ní ẹ̀kọ́ mìíràn, ti kò sì gba ọ̀rọ̀ ti ó yè kooro, ti Jesu Kristi Olúwa wa, àti ẹ̀kọ́ ti ó bá ìwà-bí-Ọlọ́run mu,

  12. 1 Timotiu 6:4nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Ó gbéraga, kò mọ̀ nǹkan kan, bí kò ṣe ìyànjú àti ìjà nípa ọ̀rọ̀ èyí tí ó ń mú ìlara, ìjà, ọ̀rọ̀ búburú wá,

  13. 1 Timotiu 6:5nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    àti ọ̀rọ̀ àríyànjiyàn àwọn ènìyàn ọlọ́kàn èérí ti kò sí òtítọ́ nínú wọn, tiwọn ṣe bí ọ̀nà sí èrè ni ìwà-bí-Ọlọ́run; yẹra lọ́dọ̀ irú àwọn wọ̀nyí.

  14. 1 Timotiu 6:6nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n ìwà-bí-Ọlọ́run pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn èrè ńlá ni.

  15. 1 Timotiu 6:7nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí a kò mú ohun kan wá sí ayé, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì lè mu ohunkóhun jáde lọ.

  16. 1 Timotiu 6:8nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Bí a sì ni oúnjẹ àti aṣọ, ìwọ̀nyí yẹ́ kí ó tẹ́ wa lọ́rùn.

  17. 1 Timotiu 6:9nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n àwọn tí ń fẹ́ di ọlọ́rọ̀ a máa bọ́ sínú ìdánwò àti ìdẹ̀kùn, àti sínú òmùgọ̀ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ púpọ̀ tí í pa ni lára, irú èyí tí ó máa ń ri ènìyàn sínú ìparun àti ègbé.

  18. 1 Timotiu 6:10nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò ohun búburú gbogbo; èyí tí àwọn mìíràn ń lépa tí a sì mú wọn ṣìnà kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì fi ọ̀pọ̀ ìbànújẹ́ gún ara wọn lọ́kọ̀.

  19. 1 Timotiu 6:11nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n ìwọ ènìyàn Ọlọ́run, sá fún nǹkan wọ̀nyí; kí ó sì máa lépa òdodo, ìwà-bí-Ọlọ́run, ìgbàgbọ́, ìfẹ́ sùúrù, ìwà tútù.

  20. 1 Timotiu 6:12nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Máa ja ìjà rere ti ìgbàgbọ́, di ìyè àìnípẹ̀kun mú nínú èyí tí a pè ọ sí, ti ìwọ sì ṣe ìjẹ́wọ́ rere níwájú ẹlẹ́rìí púpọ̀.

  21. 1 Timotiu 6:13nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Mo pàṣẹ fún ọ níwájú Ọlọ́run, tí ń sọ ohun gbogbo di ààyè, àti níwájú Jesu Kristi, ẹni tí ó jẹ́rìí níwájú Pọntiu Pilatu,

  22. 1 Timotiu 6:14nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    kí ìwọ pa àṣẹ wọ̀nyí mọ́ ní àìlábàwọ́n, ní àìlẹ́gàn, títí di ìfarahàn Olúwa wa Jesu Kristi.

  23. 1 Timotiu 6:15nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Èyí ti yóò fihàn ní ìgbà tirẹ̀, Ẹni tí í ṣe Olùbùkún àti Alágbára kan ṣoṣo náà, ọba àwọn ọba, àti Olúwa àwọn Olúwa.

  24. 1 Timotiu 6:16nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Ẹnìkan ṣoṣo tí ó jẹ àìkú, tí ń gbé inú ìmọ́lẹ̀ tí a kò lè súnmọ́, ẹni tí ènìyàn kan kò rí rí, tí a kò sì lè rí: ẹni tí ọlá àti agbára títí láé ń ṣe tirẹ̀. Àmín.

  25. 1 Timotiu 6:17nǹkan bí 65 lẹ́yìn Kristi

    Kìlọ̀ fún àwọn tí ó lọ́rọ̀ ní ayé ìsinsin yìí kí wọn ma ṣe gbéraga, bẹ́ẹ̀ ni kí wọn má ṣe gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ àìdánilójú, bí kò ṣe lé Ọlọ́run alààyè, tí ń fi ohun gbogbo fún wa lọ́pọ̀lọ́pọ̀ láti lò;