Fò sí àkóónú

circa AD 48–96

Letters to the Churches

Paul and other apostles write to strengthen, correct, and encourage the scattered churches across the Roman world.

2,767 ẹsẹ · 21 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Filipi 3:10nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Èmi mọ̀ ọ́n, àti agbára àjíǹde rẹ̀, àti láti jẹ́ alábápín nínú ìyà rẹ̀ nígbà tí mo bá fi ara mọ́ ọn nínú ikú rẹ̀;

  2. Filipi 3:11nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    nípasẹ̀ bẹ́ẹ̀ kí èmi lè ní àjíǹde kúrò nínú òkú.

  3. Filipi 3:12nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Kì í ṣe pé ọwọ́ mi ti tẹ̀ ẹ́ ná, tàbí mo ti di pípé, ṣùgbọ́n èmi ń lépa sí i, bí ọwọ́ mi yóò lè tẹ èrè náà nítorí èyí tí a ti dì mímú pẹ̀lú, láti ọ̀dọ̀ Kristi Jesu wá.

  4. Filipi 3:13nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ará, èmi kò kara mi sí ẹni ti ọwọ́ rẹ̀ ti tẹ̀ ẹ́ ná, ṣùgbọ́n ohun kan yìí ni èmi ń ṣe, èmi ń gbàgbé àwọn nǹkan tí ó ti kọjá. Lẹ́yìn náà mo ń nàgà wo àwọn nǹkan tí ó wà níwájú.

  5. Filipi 3:14nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Èmi ń lépa láti dé òpin eré ìje náà fún èrè ìpè gíga Ọlọ́run nínú Kristi Jesu.

  6. Filipi 3:15nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí àwa tí a dàgbà nípa ti ẹ̀mí ni èrò yìí; bí ẹ̀yin bá sì ní èrò mìíràn nínú ohunkóhun, èyí náà pẹ̀lú ni Ọlọ́run yóò fihàn yín.

  7. Filipi 3:16nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Kìkì pé, ki a ma gbe ìgbé ayé gẹ́gẹ́ bi èyí ti a ri gba.

  8. Filipi 3:17nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ará, ẹ jùmọ̀ ṣe àfarawé mi, ẹ ṣe àkíyèsí àwọn tí ń rìn bẹ́ẹ̀, àní bí ẹ ti ní wa fún àpẹẹrẹ.

  9. Filipi 3:18nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní ń rìn, nípasẹ̀ àwọn ẹni tí mo ti ń wí fún yín nígbàkígbà, àní, tí mo sì ń sọkún bí mo ti ń wí fún yín nísinsin yìí, pé, ọ̀tá àgbélébùú Kristi ni wọ́n.

  10. Filipi 3:19nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ìgbẹ̀yìn wọn ni ìparun, ikùn wọn sì ni Ọlọ́run wọn, wọ́n sì ń ṣògo nínú ìtìjú wọn, àwọn ẹni tí ń tọ́jú ohun ti ayé.

  11. Filipi 3:20nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí ìlú ìbílẹ̀ wá ń bẹ̀ ní ọ̀run, láti ibi ti àwa pẹ̀lú gbé ń fojúsọ́nà fún Olùgbàlà, Jesu Kristi Olúwa.

  12. Filipi 3:21nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ẹni tí yóò sọ ara ìrẹ̀lẹ̀ wa di ọ̀tún kí ó lè bá ara ògo rẹ̀ mu, nípa agbára tí ó mú kí ó ṣe é ṣe fún un láti tẹ orí ohun gbogbo bá fún ara rẹ̀.

  13. Filipi 4:1nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí náà ẹ̀yin ará mi olùfẹ́, ti mo sì ń ṣàfẹ́rí gidigidi, ayọ̀ àti adé mi, ẹ dúró ṣinṣin bẹ́ẹ̀ nínú Olúwa, ẹ̀yin olùfẹ́ mi.

  14. Filipi 4:2nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Èmi ń bẹ̀ Euodia, mo sì ń bẹ Sintike, kí wọn ní inú kan náà nínú Olúwa.

  15. Filipi 4:3nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Mo sì bẹ̀ yin pẹ̀lú bí alájọru àjàgà mi tòótọ́, ran àwọn obìnrin wọ̀nyí lọ́wọ́, nítorí wọn bá mi ṣiṣẹ́ pọ̀ ní ìfẹ̀gbẹ́-kẹ̀gbẹ́ nínú ìyìnrere, àti Klementi pẹ̀lú, àti àwọn olùbáṣiṣẹ́ mi yòókù pẹ̀lú, orúkọ àwọn tí ń bẹ nínú ìwé ìyè.

  16. Filipi 4:4nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ máa yọ̀ nínú Olúwa nígbà gbogbo: mo sì tún wí pé. Ẹ máa yọ̀.

  17. Filipi 4:5nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ jẹ́ ki ìpamọ́ra yín di mímọ́ fún gbogbo ènìyàn, Olúwa ń bẹ nítòsí.

  18. Filipi 4:6nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ má ṣe ṣe àníyàn ohunkóhun; ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo, nípa àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, ẹ máa fi ìbéèrè yín hàn fún Ọlọ́run.

  19. Filipi 4:7nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Àti àlàáfíà Ọlọ́run, tí ó ju ìmòye gbogbo lọ, yóò pa ọkàn àti èrò yín mọ nínú Kristi Jesu.

  20. Filipi 4:8nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ní àkótán, ará, ohunkóhun tí í ṣe òtítọ́, ohunkóhun tí í ṣe ọ̀wọ̀, ohunkóhun tí í ṣe títọ́ ohunkóhun tí í ṣe mímọ́, ohunkóhun tí í ṣe fífẹ́, ohunkóhun tí ó ni ìròyìn rere, bí ìwà títọ́ kan bá wà, bí ìyìn kan bá sì wà, ẹ máa gba nǹkan wọ̀nyí rò.

  21. Filipi 4:9nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Àwọn nǹkan tí ẹ̀yin ti kọ́, tí ẹ̀yin sì ti gbà, tí ẹ̀yin sì ti gbọ́, tí ẹ̀yin sì ti rí lọ́wọ́ mi, ẹ máa ṣe wọ́n: Ọlọ́run àlàáfíà yóò sì wà pẹ̀lú yín.

  22. Filipi 4:10nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Èmi yọ̀ gidigidi nínú Olúwa pé, nísinsin yìí, ẹ̀yin tún ti sọjí nínú àníyàn ọkàn yín sí mi, nítòótọ́ ọkàn yín ń fàmọ́ mi ṣùgbọ́n ẹ kò ní àǹfààní tó.

  23. Filipi 4:11nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Kì í ṣe pé èmi ń sọ nítorí àìní: nítorí pé ni ipòkípò tí mo bá wà, mo tí kọ́ láti ní ìtẹ́lọ́rùn nínú rẹ̀.

  24. Filipi 4:12nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Mo mọ̀ ohun tí o jẹ láti wa nínú àìní, mo sì mọ ohun tí ó jẹ láti ni lọ́pọ̀lọ́pọ̀. Nínú ohunkóhun àti nínú ohun gbogbo mo ti kọ́ àṣírí láti máa jẹ́ àjẹyó tàbí láti wà ni àìjẹun, láti máa ni ànító àti láti ṣe aláìní.

  25. Filipi 4:13nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Èmi le ṣe ohun gbogbo nínú Kristi ẹni ti ń fi agbára fún mi.