Fò sí àkóónú

circa AD 48–96

Letters to the Churches

Paul and other apostles write to strengthen, correct, and encourage the scattered churches across the Roman world.

2,767 ẹsẹ · 21 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Filipi 4:14nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ṣeun gidigidi ní ti pé ẹ̀yin ṣe alábápín nínú ìpọ́njú mi.

  2. Filipi 4:15nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ̀yin pàápàá sì mọ̀ pẹ̀lú, ẹ̀yin ará Filipi, pé ni ìbẹ̀rẹ̀ ìyìnrere, nígbà tí mo kúrò ni Makedonia, kò sí ìjọ kan ti ó bá mi ń ṣe alábápín ní ti gbígbà àti fífún ni, bí kò ṣe ẹ̀yin nìkan ṣoṣo.

  3. Filipi 4:16nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí ní Tẹsalonika ẹ̀yin fi nǹkan ránṣẹ́, lẹ́ẹ̀kan fún àìní mi.

  4. Filipi 4:17nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Kì í ṣe nítorí ti èmi ń fẹ́ ẹ̀bùn náà, ṣùgbọ́n èmi ń fẹ́ èso ti yóò máa di púpọ̀ nítorí yín.

  5. Filipi 4:18nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n mo ní ohun gbogbo, mo sì ti di púpọ̀, mo sì tún ni lọ́pọ̀lọ́pọ̀ nígbà ti mo tí gba nǹkan wọ̀nyí lọ́wọ́ Epafiroditu tí a ti rán wá láti lọ́dọ̀ yín, ọrẹ olóòórùn dídùn, ẹbọ ìtẹ́wọ́gbà, tì í ṣe inú dídùn gidigidi sí Ọlọ́run.

  6. Filipi 4:19nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n Ọlọ́run mi yóò pèsè ní kíkún fún gbogbo àìní yín, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú ògo nínú Kristi Jesu.

  7. Filipi 4:20nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ṣùgbọ́n ògo ni fún Ọlọ́run àti Baba wa láé àti láéláé. Àmín.

  8. Filipi 4:21nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ kí olúkúlùkù ènìyàn mímọ́ nínú Kristi Jesu. Àwọn ará tí ó wà pẹ̀lú mi kí yín.

  9. Filipi 4:22nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ kí yín, pàápàá àwọn tí ń ṣe ti agbo ilé Kesari.

  10. Filipi 4:23nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa wa, kí ó wà pẹ̀lú ẹ̀mí yín. Àmín.

  11. Kolose 1:1nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Paulu, aposteli Jesu Kristi nípa ìfẹ́ Ọlọ́run àti Timotiu arákùnrin wa,

  12. Kolose 1:2nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Sí àwọn ẹni mímọ́ àti àwọn arákùnrin àti arábìnrin nínú Kristi tí wọ́n ń gbé ní ìlú Kolose: Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún un yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa.

  13. Kolose 1:3nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Nígbàkígbà tí a bá ń gbàdúrà fún un yín ni a máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run Baba Olúwa wa Jesu Kristi.

  14. Kolose 1:4nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí a ti gbúròó ìgbàgbọ́ yín nínú Jesu Kristi, àti bí ẹ ti ṣe fẹ́ràn gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́.

  15. Kolose 1:5nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ tí ń sàn nínú ìrètí tí a gbé pamọ́ fún un yín ní ọ̀run èyí tí ẹ̀yin sì ti gbọ́ tẹ́lẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ òtítọ́ ìyìnrere náà,

  16. Kolose 1:6nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    èyí tí ó ti dé ọ̀dọ̀ yín. Káàkiri àgbáyé ni ìyìnrere yìí ń so èso tí ó sì ń dàgbà, gẹ́gẹ́ bí ó ti ń ṣe láàrín yín láti ọjọ́ náà tí ẹ ti gbọ́ ọ, tí ẹ sì ní ìmọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run nínú gbogbo òtítọ́ rẹ̀.

  17. Kolose 1:7nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ẹ̀yin ti kọ́ ọ lọ́dọ̀ Epafira, ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wa olùfẹ́, ẹni tí ó jẹ́ olóòtítọ́ ìránṣẹ́ Kristi ní ipò wa.

  18. Kolose 1:8nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Ẹni ti ó sọ fún wa nípa ìfẹ́ yín nínú ẹ̀mí.

  19. Kolose 1:9nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí ìdí èyí, láti ọjọ́ tí a ti gbọ́ nípa yín, a kò sinmi láti máa gbàdúrà fún yin, tí a sì ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fi ìmọ̀ ìfẹ́ rẹ̀ kún yín nípasẹ̀ ọgbọ́n àti òye gbogbo tí ń ṣe ti Ẹ̀mí.

  20. Kolose 1:10nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Àwa sì ń gbàdúrà yìí kí ẹ lè gbé irú ìgbé ayé tó yẹ fún Olúwa kí ẹ sì máa wu ú ní gbogbo ọ̀nà, kí ẹ sì máa so èso rere gbogbo, kí ẹ sì máa dàgbà nínú ìmọ̀ Ọlọ́run,

  21. Kolose 1:11nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    pé kí a lè fi ipa gbogbo sọ yín di alágbára gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ àti ògo rẹ̀, kí ó lè ṣe é ṣe fún un yín láti máa tẹ̀síwájú nínú sùúrù àti ìpamọ́ra pẹ̀lú ayọ̀.

  22. Kolose 1:12nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Kí a máa dúpẹ́ nígbà gbogbo lọ́wọ́ Baba, ẹni tí ó kà yín láti jẹ́ alábápín nínú ogún àwọn ẹni mímọ́ nínú ìjọba ìmọ́lẹ̀.

  23. Kolose 1:13nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Nítorí tí ó ti já wa gbà kúrò nínú agbára òkùnkùn ó sì mú wa wá sí ìjọba Ọmọ tí ó fẹ́ràn.

  24. Kolose 1:14nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Nínú ẹni tí a ní ìràpadà, àti ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀.

  25. Kolose 1:15nǹkan bí 64 lẹ́yìn Kristi

    Kristi ni àwòrán Ọlọ́run tí a kò le rí, àkọ́bí gbogbo ẹ̀dá.