- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa AD 48–96
Letters to the Churches
Paul and other apostles write to strengthen, correct, and encourage the scattered churches across the Roman world.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- 1 Peteru 3:7nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa fi òye ba àwọn aya yín gbé, ẹ máa fi ọlá fún aya, bi ohun èlò ti kò lágbára, àti pẹ̀lú bí àjùmọ̀jogún oore-ọ̀fẹ́ ìyè; kí àdúrà yín má bà á ní ìdènà.
- 1 Peteru 3:8nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
Lákòótan, kí gbogbo yín jẹ́ onínú kan, ẹ máa bá ara yín kẹ́dùn, ẹ ní ìfẹ́ ará, ẹ máa ṣe ìyọ́nú, ẹ ni ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀.
- 1 Peteru 3:9nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
Ẹ má ṣe fi búburú san búburú, tàbí fi èébú san èébú: ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa súre; nítorí èyí ni a pè yín sí, kí ẹ̀yin lè jogún ìbùkún.
- 1 Peteru 3:10nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
Nítorí, “Ẹni tí yóò bá fẹ́ ìyè, ti yóò sì rí ọjọ́ rere, kí o pa ahọ́n rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi, àti ètè rẹ̀ mọ́ kúrò nínú sísọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.
- 1 Peteru 3:11nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
Kí ó yà kúrò nínú ibi, kí ó sì máa ṣe rere; kí ó máa wá àlàáfíà, kí ó sì máa lépa rẹ̀.
- 1 Peteru 3:12nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
Nítorí ojú Olúwa ń bẹ lára àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí ẹ̀bẹ̀ wọn, ṣùgbọ́n ojú Olúwa korò sí àwọn tí ń ṣe búburú.”
- 1 Peteru 3:13nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
Tá nì yóò sì ṣe yín ní ibi, bí ẹ̀yin bá jẹ́ onítara sí ohun rere?
- 1 Peteru 3:14nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá jìyà nítorí òdodo, a ti bùkún yín. “Ẹ má ṣe bẹ̀rù ìhàlẹ̀ wọn, kí ẹ má sì ṣe kọminú.”
- 1 Peteru 3:15nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n ẹ bọ̀wọ̀ fún Kristi bí Olúwa ní ọkàn yín: kí ẹ sì múra tan nígbà gbogbo láti dá olúkúlùkù lóhùn tí ń béèrè ìrètí tí o ń bẹ nínú yín, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọkàn tútù àti ìbẹ̀rù.
- 1 Peteru 3:16nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
Kí ẹ máa ni ẹ̀rí ọkàn rere bí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ yín ní ibi, kí ojú lè ti àwọn tí ń kẹ́gàn ìwà rere yín nínú Kristi.
- 1 Peteru 3:17nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
Nítorí ó sàn, bí ó bá jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run, kí ẹ jìyà fún ṣíṣe rere ju fún ṣíṣe búburú lọ.
- 1 Peteru 3:18nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
Nítorí tí Kristi pẹ̀lú jìyà lẹ́ẹ̀kan nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, olóòótọ́ fún àwọn aláìṣòótọ́, kí a lè mú wa dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí a pa nínú ara, ṣùgbọ́n tí a sọ di ààyè nínú ẹ̀mí.
- 1 Peteru 3:19nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
Nínú èyí tí ó lọ pẹ̀lú tí ó sì wàásù fún àwọn ẹ̀mí nínú túbú,
- 1 Peteru 3:20nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
àwọn tí ó ṣe aláìgbọ́ràn nígbà kan, nígbà tí sùúrù Ọlọ́run dúró pẹ́ ní sá à kan ní ọjọ́ Noa, nígbà tí wọ́n fi kan ọkọ̀ nínú èyí tí a gba ọkàn díẹ̀ là nípa omi, èyí ni ẹni mẹ́jọ.
- 1 Peteru 3:21nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
Àpẹẹrẹ èyí ti ń gbà yín là nísinsin yìí pẹ̀lú, àní ìtẹ̀bọmi, kì í ṣe wíwẹ́ èérí ti ara nù, bí kò ṣe ìdáhùn ẹ̀rí ọkàn rere si Ọlọ́run, nípa àjíǹde Jesu Kristi.
- 1 Peteru 3:22nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
Ẹni tí ó lọ sí ọ̀run, tí ó sì ń bẹ lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọ́run: pẹ̀lú àwọn angẹli, àwọn aláṣẹ, àti àwọn alágbára sì tẹríba lábẹ́ rẹ̀.
- 1 Peteru 4:1nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
Ǹjẹ́ bí Kristi ti jìyà fún wa nípa ti ará, irú kan náà ni kí ẹ̀yin fi hámọ́ra; nítorí ẹni tí ó bá ti jìyà nípa ti ara, ó ti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀.
- 1 Peteru 4:2nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
Kí ẹ̀yin má ṣe fi ìgbà ayé yín ìyókù wà nínú ara mọ́ sí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ènìyàn bí kò ṣe sí ìfẹ́ Ọlọ́run.
- 1 Peteru 4:3nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
Nítorí ìgbà tí ó ti kọjá ti tó fún ṣíṣe ìfẹ́ àwọn aláìkọlà, rínrìn nínú ìwà wọ̀bìà, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ọtí àmupara, ìréde òru, kíkó ẹ̀gbẹ́ ọ̀mùtí, àti ìbọ̀rìṣà tí í ṣe ohun ìríra.
- 1 Peteru 4:4nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
Èyí tí ó yà wọ́n lẹ́nu pé ẹ̀yin kò ba wọn súré sínú irú àṣejù ìwà wọ̀bìà wọ́n, tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ yín ní búburú.
- 1 Peteru 4:5nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
Àwọn ẹni tí yóò jíyìn fún ẹni tí ó ti múra láti ṣe ìdájọ́ alààyè àti òkú.
- 1 Peteru 4:6nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
Nítorí èyí ní a sá ṣe wàásù ìyìnrere fún àwọn òkú, kí a lè ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ènìyàn nípa ti ara, ṣùgbọ́n kí wọ́n lè wà láààyè si Ọlọ́run nípa tí Ẹ̀mí.
- 1 Peteru 4:7nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
Ṣùgbọ́n òpin ohun gbogbo kù sí dẹ̀dẹ̀; nítorí náà kí ẹ̀yin wà ní àìrékọjá, kí ẹ sì máa ṣọ́ra nínú àdúrà.
- 1 Peteru 4:8nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ ní ìfẹ́ tí ó gbóná láàrín ara yín, nítorí ìfẹ́ ni ń bo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.
- 1 Peteru 4:9nǹkan bí 60 lẹ́yìn Kristi
Ẹ máa ṣe ara yín ni àlejò láìsí ìkùnsínú.