Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Tribe Of Judah

84 ẹsẹ · 42 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Gbogbo ọkùnrin Juda sì dá àwọn ọkùnrin Israẹli lóhùn pé, “Nítorí pé ọba bá wa tan ni; èéṣe tí ẹ̀yin fi bínú nítorí ọ̀ràn yìí? Àwa jẹ nínú oúnjẹ ọba rárá bí? Tàbí ó fi ẹ̀bùn kan fún wa bí?”

  2. Dafidi ọba sì wí pé, “Ẹ pe Sadoku àlùfáà wọlé fún mi àti Natani wòlíì àti Benaiah ọmọ Jehoiada.” Nígbà tí wọ́n wá síwájú ọba,

  3. ọba sì wí fún wọn pé, “Ẹ mú àwọn ìránṣẹ́ olúwa yín pẹ̀lú yín kí ẹ sì mú kí Solomoni ọmọ mi kí ó gun ìbáaka mi, kí ẹ sì mú un sọ̀kalẹ̀ wá sí Gihoni.

  4. Níbẹ̀ ni Sadoku àlùfáà àti Natani wòlíì yóò ti fi òróró yàn án ní ọba lórí Israẹli. Ẹ fọn fèrè, kí ẹ sì ké pé, ‘Kí Solomoni ọba kí ó pẹ́!’

  5. Nígbà náà ni kí ẹ sì gòkè pẹ̀lú rẹ̀, kí ó sì wá, kí ó sì jókòó sórí ìtẹ́ mi, kí ó sì jẹ ọba ní ipò mi. Èmi ti yàn án ní ọba lórí gbogbo Israẹli àti Juda.”

  6. Benaiah ọmọ Jehoiada sì dá ọba lóhùn pé, “Àmín! Kí Olúwa Ọlọ́run olúwa mi ọba, kéde rẹ̀ bẹ́ẹ̀.

  7. Bí Olúwa ti wà pẹ̀lú olúwa mi ọba, bẹ́ẹ̀ ni kí ó wà pẹ̀lú Solomoni kí ó lè mú kí ìjọba rẹ̀ pẹ́ ju ìtẹ́ olúwa mi Dafidi ọba lọ!”

  8. Nígbà náà ni Sadoku àlùfáà, Natani wòlíì, Benaiah ọmọ Jehoiada, àwọn ará Kereti àti Peleti sì sọ̀kalẹ̀ wá wọ́n sì gbé Solomoni gun ìbáaka Dafidi ọba wá sí Gihoni.

  9. Sadoku àlùfáà sì mú ìwo òróró láti inú àgọ́, ó sì dà á sí Solomoni lórí. Nígbà náà ni wọ́n sì fọn fèrè, gbogbo àwọn ènìyàn sì ké pé, “Kí Solomoni ọba kí ó pẹ́!”

  10. Juda ni baba Peresi àti Sera, Tamari sì ni ìyá rẹ̀, Peresi ni baba Hesroni: Hesroni ni baba Ramu;

  11. Ramu ni baba Amminadabu; Amminadabu ni baba Nahiṣoni; Nahiṣoni ni baba Salmoni;

  12. Salmoni ni baba Boasi, Rahabu sí ni ìyá rẹ̀; Boasi ni baba Obedi, Rutu sí ni ìyá rẹ̀; Obedi sì ni baba Jese;

  13. Jese ni baba Dafidi ọba. Dafidi ni baba Solomoni, ẹni tí ìyá rẹ̀ jẹ́ aya Uriah tẹ́lẹ̀ rí.

  14. Solomoni ni baba Rehoboamu, Rehoboamu ni baba Abijah, Abijah ni baba Asa,

  15. Asa ni baba Jehoṣafati; Jehoṣafati ni baba Jehoramu; Jehoramu ni baba Ussiah;

  16. Ussiah ni baba Jotamu; Jotamu ni baba Ahaṣi; Ahaṣi ni baba Hesekiah;

  17. Hesekiah ni baba Manase; Manase ni baba Amoni; Amoni ni baba Josiah;

  18. Josiah sì ni baba Jekoniah àti àwọn arákùnrin rẹ̀ ní àkókò ìkólọ sí Babeli.

  19. Lẹ́yìn ìkólọ sí Babeli: Jekoniah ni baba Ṣealitieli; Ṣealitieli ni baba Serubbabeli;

  20. Serubbabeli ni baba Abihudi; Abihudi ni baba Eliakimu; Eliakimu ni baba Asori;

  21. Asori ni baba Sadoku; Sadoku ni baba Akimu; Akimu ni baba Elihudi;

  22. Elihudi ni baba Eleasari; Eleasari ni baba Mattani; Mattani ni baba Jakọbu;

  23. Jakọbu ni baba Josẹfu, ẹni tí ń ṣe ọkọ Maria, ìyá Jesu, ẹni tí í ṣe Kristi.

  24. Jesu tìkára rẹ̀ ń tó bí ẹni ọgbọ̀n ọdún, nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ ó jẹ́ (bí a ti fi pè) ọmọ Josẹfu, tí í ṣe ọmọ Eli,

  25. tí í ṣe ọmọ Mattati, tí í ṣe ọmọ Lefi, tí í ṣe ọmọ Meliki, tí í ṣe ọmọ Janai, tí í ṣe ọmọ Josẹfu,