Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Tribe Of Judah

84 ẹsẹ · 42 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ààlà ìwọ̀-oòrùn sì jẹ́ agbègbè Òkun Ńlá. Ìwọ̀nyí ni ààlà àyíká ènìyàn Juda ní agbo ilé wọn.

  2. Nígbà náà ni àwọn olórí ẹ̀yà Juda béèrè ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Simeoni arákùnrin wọn pé, “Ẹ wá bá wa gòkè lọ sí ilẹ̀ tí a ti fi fún wa, láti bá àwọn ará Kenaani jà kí a sì lé wọn kúrò, àwa pẹ̀lú yóò sì bá a yín lọ sí ilẹ̀ tiyín bákan náà láti ràn yín lọ́wọ́.” Àwọn ọmọ-ogun Simeoni sì bá àwọn ọmọ-ogun Juda lọ.

  3. Nígbà tí àwọn ọmọ-ogun Juda sì kọlu wọ́n, Olúwa sì fi àwọn ará Kenaani àti àwọn ará Peresi lé wọn lọ́wọ́, wọ́n sì pa ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ọkùnrin ní Beseki.

  4. Ní Beseki ni wọ́n ti rí Adoni-Beseki, wọ́n sì bá a jagun, wọ́n sì ṣẹ́gun àwọn ará Kenaani àti Peresi.

  5. Ọba Adoni-Beseki sá àsálà, ṣùgbọ́n ogun Israẹli lépa rẹ̀ wọ́n sì bá a, wọ́n sì gé àwọn àtàǹpàkò ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀.

  6. Nígbà náà ni Adoni-Beseki wí pé, “Àádọ́rin ọba ni èmi ti gé àtàǹpàkò wọn tí wọ́n sì ń ṣa èérún oúnjẹ jẹ lábẹ́ tábìlì mi. Báyìí Ọlọ́run ti san án fún mi gẹ́gẹ́ bí ohun tí mo ṣe sí wọn.” Wọ́n sì mú un wá sí Jerusalẹmu, ó sì kú síbẹ̀.

  7. Àwọn ológun Juda sì ṣẹ́gun Jerusalẹmu, wọ́n sì kó o, wọ́n sì fi ojú idà kọlù ú, wọ́n sì dáná sun ìlú náà.

  8. Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ni àwọn ogun Juda sọ̀kalẹ̀ lọ láti bá àwọn ará Kenaani tí ń gbé ní àwọn ìlú orí òkè ní gúúsù àti ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ òkè lápá ìwọ̀-oòrùn Juda jagun.

  9. Ogun Juda sì tún ṣígun tọ ará Kenaani tí ń gbé Hebroni (tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kiriati-Arba) ó sì ṣẹ́gun Ṣeṣai, Ahimani àti Talmai.

  10. Láti ibẹ̀, wọ́n sì wọ́de ogun láti ibẹ̀ lọ bá àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Debiri (tí à ń pè ní Kiriati-Seferi nígbà kan rí).

  11. Kalebu sì wí pé, “Èmi yóò fi ọmọbìnrin mi Aksa fún ọkùnrin tí ó bá kọlu Kiriati-Seferi, tí ó sì gbà á ní ìgbéyàwó.”

  12. Otnieli ọmọ Kenasi, àbúrò Kalebu sì gbà á, báyìí ni Kalebu sì fi ọmọbìnrin rẹ̀ Aksa fún un ní ìyàwó.

  13. Ní ọjọ́ kan, nígbà tí Aksa lọ sí ọ̀dọ̀ Otnieli, ó rọ̀ ọ́ kí ó béèrè ilẹ̀ oko lọ́wọ́ baba rẹ̀. Nígbà náà ni Aksa sọ̀kalẹ̀ ní orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, Kalebu sì béèrè pé, “Kí ni kí èmi ṣe fún ọ?”

  14. Aksa sì dáhùn pé, “Mo ń fẹ́ kí o ṣe ojúrere kan fún mi, nígbà ti o ti fún mi ní ilẹ̀ ní gúúsù, fún mi ní ìsun omi náà pẹ̀lú.” Kalebu sì fún un ní ìsun òkè àti ìsun ìsàlẹ̀.

  15. Àwọn ìran Keni tí wọ́n jẹ́ àna Mose bá àwọn ọmọ Juda gòkè láti ìlú ọ̀pẹ lọ sí aginjù Juda ní gúúsù Aradi; wọ́n sì lọ, orílẹ̀-èdè méjèèjì sì jùmọ̀ ń gbé pọ̀ láti ìgbà náà.

  16. Ó sì ṣe, àwọn ológun Juda tẹ̀lé àwọn ológun Simeoni arákùnrin wọn, wọ́n sì lọ bá àwọn ará Kenaani tí ń gbé Sefati jagun, wọ́n sì run ìlú náà pátápátá, ní báyìí àwa yóò pe ìlú náà ní Horma (Horma èyí tí ń jẹ́ ìparun).

  17. Àwọn ogun Juda sì ṣẹ́gun Gasa àti àwọn agbègbè rẹ̀, Aṣkeloni àti Ekroni pẹ̀lú àwọn ìlú tí ó yí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ká.

  18. Olúwa sì wà pẹ̀lú ẹ̀yà Juda, wọ́n gba ilẹ̀ òkè, ṣùgbọ́n wọn kò le lé àwọn ènìyàn tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, nítorí wọ́n ní kẹ̀kẹ́ ogun onírin.

  19. Gẹ́gẹ́ bí Mose ti ṣèlérí, wọ́n fún Kalebu ní Hebroni, ó sì lé àwọn tí ń gbé ibẹ̀ kúrò; àwọn náà ni ìran àwọn ọmọ Anaki mẹ́ta.

  20. Dafidi ọba sì ránṣẹ́ sí Sadoku, àti sí Abiatari àwọn àlùfáà pé, “Sọ fún àwọn àgbàgbà Juda, pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin fi kẹ́yìn láti mú ọba padà wá sí ilé rẹ̀? Ọ̀rọ̀ gbogbo Israẹli sì ti dé ọ̀dọ̀ ọba àní ní ilé rẹ̀.

  21. Ẹ̀yin ni ara mi, ẹ̀yin ni egungun mi, àti ẹran-ara mi: èéṣì ti ṣe tí ẹ̀yin fi kẹ́yìn láti mú ọba padà wá.’

  22. Kí ẹ̀yin sì wí fún Amasa pé, ‘Egungun àti ẹran-ara mi kọ́ ni ìwọ jẹ́ bí? Kí Ọlọ́run ó ṣe bẹ́ẹ̀ sí mi àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú, bí ìwọ kò ba ṣe olórí ogun níwájú mi títí, ní ipò Joabu.’ ”

  23. Òun sì yí gbogbo àwọn ọkùnrin Juda lọ́kàn padà àní bí ọkàn ènìyàn kan; wọ́n sì ránṣẹ́ sí ọba, pé, “Ìwọ padà àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ.”

  24. Ọba sì padà, o sì wá sí odò Jordani. Juda sì wá sí Gilgali láti lọ pàdé ọba, àti láti mú ọba kọjá odò Jordani.

  25. Sì wò ó, gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli sì tọ ọba wá, wọ́n sì wí fún ọba pé, “Èéṣe tí àwọn arákùnrin wa àwọn ọkùnrin Juda fi jí ọ kúrò, tí wọ́n sì fi mú ọba àti àwọn ará ilé rẹ̀ gòkè odò Jordani, àti gbogbo àwọn ènìyàn Dafidi pẹ̀lú rẹ?”