Fò sí àkóónú

Nahshon

11 ẹsẹ · 3 ọmọ ẹbí

A tún mọ̀ ọ́n sí: Naashon, Naasson

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Nahshon

  1. Aaroni fẹ́ Eliṣeba ọmọbìnrin Amminadabu tí í ṣe arábìnrin Nahiṣoni, ó sì bí Nadabu, Abihu, Eleasari àti Itamari.

  2. Láti ọ̀dọ̀ Juda, Nahiṣoni ọmọ Amminadabu.

  3. Ní ìlà-oòrùn, ní ìdojúkọ àtiyọ oòrùn: ni kí ìpín ti Juda pa ibùdó wọn sí lábẹ́ ọ̀págun wọn. Olórí Juda ni Nahiṣoni ọmọ Amminadabu.

  4. Ẹni tí ó mú ọrẹ tirẹ̀ wá ní ọjọ́ kìn-ín-ní Nahiṣoni ọmọ Amminadabu láti inú ẹ̀yà Juda.

  5. akọ màlúù méjì, àgbò márùn-ún, òbúkọ ọlọ́dún kan márùn-ún tí wọn ó fi rú ẹbọ àlàáfíà. Wọ̀nyí ni ọrẹ Nahiṣoni ọmọ Amminadabu.

  6. Àwọn ìpín ti ibùdó Juda ló kọ́kọ́ gbéra tẹ̀lé wọn lábẹ́ ogun wọn Nahiṣoni ọmọ Amminadabu ni ọ̀gágun wọn.

  7. Amminadabu ni baba Nahiṣoni, Nahiṣoni ni baba Salmoni,

  8. Ramu sì ni baba Amminadabu, àti Amminadabu baba Nahiṣoni olórí àwọn ènìyàn Juda.

  9. Nahiṣoni sì ni baba Salmoni, Salmoni ni baba Boasi,

  10. Ramu ni baba Amminadabu; Amminadabu ni baba Nahiṣoni; Nahiṣoni ni baba Salmoni;

  11. tí í ṣe ọmọ Jese, tí í ṣe ọmọ Obedi, tí í ṣe ọmọ Boasi, tí í ṣe ọmọ Salmoni, tí í ṣe ọmọ Nahiṣoni,