Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Righteousness

480 ẹsẹ · 132 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. àti láti pèsè fún àwọn tí inú wọn bàjẹ́ ní Sioni láti dé wọn ládé ẹwà dípò eérú, òróró ayọ̀ dípò ọ̀fọ̀, àti aṣọ ìyìn dípò ìpòrúru ọkàn. A ó sì pè wọ́n ní igi óákù òdodo, irúgbìn Olúwa láti fi ọláńlá rẹ̀ hàn.

  2. Èmi yọ̀ gidigidi nínú Olúwa; ọkàn mi yọ̀ nínú Ọlọ́run mi. Nítorí ó ti wọ̀ mí ní aṣọ ìgbàlà ó sì ṣe mí lọ́ṣọ̀ọ́ nínú aṣọ òdodo; gẹ́gẹ́ bí ọkọ ìyàwó ti ṣe orí rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ bí àlùfáà, àti bí ìyàwó ṣe ń ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú ohun ọ̀ṣọ́.

  3. Gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ti í mú irúgbìn jáde àti bí ọgbà ṣe ń mú irúgbìn dàgbà, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa Olódùmarè yóò ṣe mú òdodo àti ìyìn kí ó ru sókè níwájú gbogbo orílẹ̀-èdè.

  4. Nítorí Sioni èmi kì yóò dákẹ́, nítorí i Jerusalẹmu èmi kì yóò sinmi ẹnu, títí tí òdodo rẹ̀ yóò fi tàn bí òwúrọ̀, àti ìgbàlà rẹ̀ bí i fìtílà tí ń jó geere.

  5. Gbogbo wa ti dàbí ẹnìkan tí ó jẹ́ aláìmọ́, gbogbo òdodo wa sì dàbí èkísà ẹlẹ́gbin; gbogbo wa kákò bí ewé, àti bí afẹ́fẹ́, ẹ̀ṣẹ̀ wa ti gbá wa lọ kúrò.

  6. Ní ọjọ́ rẹ̀ ni a ó gba Juda là, Israẹli yóò sì máa gbé ní aláìléwu. Èyí ni orúkọ tí a ó fi máa pè é: Olúwa Òdodo wa.

  7. “Bí ọkùnrin olódodo kan bá wà, tó ń ṣe ohun tó tọ́, tó sì yẹ

  8. tí kò bá wọn jẹun lórí òkè gíga, tí kò gbójú rẹ̀ sókè sí àwọn òrìṣà ilẹ̀ Israẹli, ti kò sì ba obìnrin aládùúgbò rẹ̀ jẹ́ tàbí kí ó sùn ti obìnrin ni àsìkò èérí rẹ̀.

  9. Kò sì ni ẹnikẹ́ni lára, ó sì sanwó fún onígbèsè rẹ̀ gẹ́gẹ́ bó ṣe ṣe ìlérí fún un, kò fi ipá jalè ṣùgbọ́n ó fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ, tí ó sì fi ẹ̀wù wọ àwọn tí ó wà ní ìhòhò.

  10. Ẹni tí kò fi fún ni láti gba ẹ̀dá, tàbí kò gba èlé tó pọ̀jù. Ó yọ ọwọ́ rẹ̀ kúrò nínú ìwà ẹ̀ṣẹ̀, ó sì ń ṣe ìdájọ́ òtítọ́ láàrín ọkùnrin kan àti èkejì rẹ̀.

  11. Tí ó ń tẹ̀lé àṣẹ mi, tí ó sì ń pa òfin mi mọ́ lóòtítọ́ àti lódodo. Ó jẹ́ olódodo, yóò yè nítòótọ́, ní Olúwa Olódùmarè wí.

  12. Tí ó bá mu ògo padà, tí o sì da ohun tí o ti jí gbé padà, tí ó sì tẹ̀lé òfin tí ó ń fún ni ní ìyè, tí kò sì ṣe búburú, òun yóò yè dandan; òun kì yóò kú.

  13. Àwọn igi eléso ní oríṣìíríṣìí ni yóò máa hù ní bèbè odò ní ìhà ìhín àti ní ìhà ọ̀hún. Ewé wọn kì yóò sì rọ, bẹ́ẹ̀ ní èso wọn kì yóò run, wọn yóò máa ṣe èso tuntun rẹ̀ ní oṣù nítorí pé omi láti ibi mímọ́ ń sàn sí wọn. Èso wọn yóò sì jẹ́ fún jíjẹ àti ewé wọn fún ìwòsàn.”

  14. Nítorí náà ọba, jẹ́ kí ìmọ̀ràn mi jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún ọ, kọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ sílẹ̀ kí o sì ṣe rere, àti ìwà búburú rẹ nípa ṣíṣe àánú fún àwọn tálákà. Ó lè jẹ́ pé nígbà náà ni ìwọ yóò ṣe rere.”

  15. “Àádọ́rin ọ̀sẹ̀ ni a pàṣẹ fún àwọn ènìyàn rẹ àti fún àwọn ìlú mímọ́ rẹ láti parí ìrékọjá, láti fi òpin sí ẹ̀ṣẹ̀, láti ṣe ètùtù sí ìwà búburú, láti mú òdodo títí ayé wá, láti ṣe èdìdì ìran àti wòlíì àti láti fi òróró yan Ibi Mímọ́ Jùlọ.

  16. Àwọn tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n yóò máa tàn bí ìmọ́lẹ̀ ọ̀run, àti àwọn tí ó ń tọ́nisọ́nà sí òdodo, yóò máa tàn bí ìràwọ̀ láé àti láéláé.

  17. Ẹ gbin òdòdó fún ara yín, kí ẹ sì ká èso ìfẹ́ àìlópin. Ẹ tu ilẹ̀ yín tí a kò ro, nítorí pé ó ti tó àsìkò láti wá Olúwa, títí tí yóò fi dé, tí yóò sì rọ òjò òdodo lé yín lórí.

  18. Ẹ̀yin tí ẹ̀ sọ òdodo di ìkorò tí ẹ sì gbé olódodo ṣánlẹ̀.

  19. Ẹ wá Olúwa, gbogbo ẹ̀yin onírẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ náà, ẹ̀yin tí ń ṣe ohun tí ó bá pàṣẹ. Ẹ wá òdodo, ẹ wá ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú, bóyá á ó pa yín mọ́ ní ọjọ́ ìbínú Olúwa.

  20. Òun yóò sì jókòó bí ẹni tí n yọ́, tí ó sì ń da fàdákà; yóò wẹ àwọn ọmọ Lefi mọ́, yóò sì tún wọn dàbí wúrà àti fàdákà, kí wọn bá a lè mú ọrẹ òdodo wá fún Olúwa,

  21. Ṣùgbọ́n fún ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù orúkọ mi, oòrùn òdodo yóò yọ, pẹ̀lú ìmúláradá ni ìyẹ́ apá rẹ̀. Ẹ̀yin yóò sì jáde lọ, ẹ̀yin yóò sì máa fò fún ayọ̀ bi àwọn ẹgbọrọ màlúù tí a tú sílẹ̀ lórí ìso.

  22. Jesu sì dáhùn pé, “Jọ̀wọ́ rẹ̀ bẹ́ẹ̀ náà, nítorí bẹ́ẹ̀ ni ó yẹ fún wa láti mú gbogbo òdodo ṣẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni Johanu gbà, ó sì ṣe ìtẹ̀bọmi fún un.

  23. Alábùkún fún ni àwọn tí ebi ń pa tí òǹgbẹ ń gbẹ́ nítorí òdodo, nítorí wọn yóò yó.

  24. Alábùkún fún ni àwọn ẹni tí a ṣe inúnibíni sí, nítorí tí wọ́n jẹ́ olódodo nítorí tiwọn ní ìjọba ọ̀run.

  25. Nítorí náà ni mo ti wí fún yín pé àfi bí òdodo yín bá ju ti àwọn Farisi àti ti àwọn olùkọ́ òfin lọ, dájúdájú ẹ̀yin kì yóò le wọ ìjọba ọ̀run.