Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Righteousness

480 ẹsẹ · 132 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Olódodo ènìyàn máa ń ṣọ́ra láti dọ́rẹ̀ẹ́ ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ń mú wọn ṣìnà.

  2. Ní ọ̀nà àwọn olódodo ni ìyè wà ní ọ̀nà náà ni àìkú wà.

  3. Òdodo ń ṣamọ̀nà ènìyàn olóòtítọ́ inú, ṣùgbọ́n ìwà búburú ṣí ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ipò.

  4. Olódodo jẹ́wọ́ títí ó fi tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn ṣùgbọ́n ebi yóò máa pa ikùn ènìyàn búburú.

  5. Òdodo a máa gbé orílẹ̀-èdè lékè, ṣùgbọ́n ìtìjú ni ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ fún àwùjọ káwùjọ.

  6. Ilé olódodo kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ìṣúra, ṣùgbọ́n èrè àwọn ènìyàn búburú ń mú ìyọnu wá fún wọn.

  7. Olúwa kórìíra ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n ó fẹ́ràn àwọn tí ń lépa òdodo.

  8. Olúwa jìnnà sí ènìyàn búburú ṣùgbọ́n ó ń gbọ́ àdúrà olódodo.

  9. Àwọn ọba kórìíra ìwà àìtọ́ nítorí òdodo ní í fi ìdí ìtẹ́ múlẹ̀.

  10. Adé ògo ni ewú orí jẹ́, ìgbé ayé òdodo ní í mú ni dé bẹ̀.

  11. Ṣíṣe ohun tí ó dára tí ó sì tọ̀nà ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà sí Olúwa ju ẹbọ lọ.

  12. Ẹni tí ó bá tẹ̀lé òdodo àti àánú yóò rí ìyè, òdodo, àti ọlá.

  13. Mú ènìyàn búburú kúrò níwájú ọba a ó sì fìdí ìtẹ́ rẹ múlẹ̀ nípasẹ̀ òdodo.

  14. Ènìyàn búburú ń sá bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹnìkan kò lé e ṣùgbọ́n olódodo láyà bí i kìnnìún.

  15. Olódodo ń máa ro ọ̀rọ̀ tálákà, ṣùgbọ́n ènìyàn búburú kò sú sí i láti rò ó.

  16. Ẹ sọ fún olódodo pé yóò dára fún wọn, nítorí ní àjẹgbádùn ni wọn yóò jẹ èso iṣẹ́ ẹ wọn.

  17. Ọgbà àjàrà Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ilé Israẹli àwọn ọkùnrin Juda sì ni àyànfẹ́ ọgbà rẹ̀. Ó retí ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ṣùgbọ́n, ìtàjẹ̀ sílẹ̀ ni ó rí. Òun ń retí òdodo ṣùgbọ́n ó gbọ́ ẹkún ìpayínkeke.

  18. ṣùgbọ́n pẹ̀lú òdodo ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn aláìní, pẹ̀lú òtítọ́ ni yóò ṣe ìpinnu fún àwọn aláìní ayé. Òun yóò lu ayé pẹ̀lú ọ̀pá tí ó wà ní ẹnu rẹ̀, pẹ̀lú èémí ẹnu rẹ̀ ni yóò pa àwọn ìkà.

  19. Òdodo ni yóò jẹ́ ìgbànú rẹ̀ àti òtítọ́ ni yóò ṣe ọ̀já yí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ká.

  20. Ọkàn mi ń pòùngbẹẹ̀ rẹ ní ọ̀gànjọ́ òru; ní òwúrọ̀ ni ẹ̀mí mi ń ṣàfẹ́rí rẹ. Nígbà tí ìdájọ́ rẹ bá sọ̀kalẹ̀ sórí ayé àwọn ènìyàn yóò kọ́ ìṣòdodo.

  21. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a fi oore-ọ̀fẹ́ hàn sí àwọn ìkà wọn kò kọ́ láti sọ òdodo; kódà ní ilẹ̀ àwọn tí ó dúró ṣinṣin wọ́n tẹ̀síwájú láti máa ṣe ibi wọn kò sì ka ọláńlá Olúwa sí.

  22. Èmi yóò fi ìdájọ́ ṣe okùn òsùwọ̀n àti òdodo òjé òsùwọ̀n; yìnyín yóò gbá ààbò yín dànù àti irọ́, omi yóò sì kún bo gbogbo ibi tí ẹ ń fi ara pamọ́ sí mọ́lẹ̀.

  23. Wò ó, ọba kan yóò jẹ nínú òdodo àwọn olórí yóò máa fi ìdájọ́ ṣe àkóso.

  24. Ẹ̀tọ́ yóò máa gbé ní inú aṣálẹ̀ àti òdodo yóò sì máa gbé ní pápá oko ọlọ́ràá.

  25. Èso òdodo náà yóò sì jẹ́ àlàáfíà; àbájáde òdodo yóò sì jẹ́ ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé títí láé.