Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Righteousness: Fruits of

298 ẹsẹ · 132 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Fruits of

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Bí a bá ṣọ́ra láti pa gbogbo òfin wọ̀nyí mọ́ níwájú Olúwa Ọlọ́run wa, bí ó ti pàṣẹ fún wa, èyí ni yóò máa jẹ́ òdodo wa.”

  2. Finehasi ọmọ Eleasari, àlùfáà wí fún Reubeni, Gadi àti Manase pé, “Ní òní ni àwa mọ̀ pé Olúwa wà pẹ̀lú wa, nítorí tí ẹ̀yin kò hùwà àìṣòótọ́ sí Olúwa ní orí ọ̀rọ̀ yí nísinsin yìí, ẹ̀yin ti yọ àwọn ará Israẹli kúrò ní ọwọ́ Olúwa”.

  3. Ó dàbí igi tí a gbìn sí etí odò tí ń sàn, tí ń so èso rẹ̀ jáde ní àkókò rẹ̀ tí ewé rẹ̀ kì yóò rẹ̀. Ohunkóhun tí ó dáwọ́lé, ni yóò máa yọrí sí rere.

  4. Saamu ti Dafidi. Olúwa, ta ni yóò máa ṣe àtìpó nínú àgọ́ rẹ? Ta ni yóò máa gbé ní òkè mímọ́ rẹ?

  5. Ẹni tí ń rìn déédé tí ó sì ń sọ òtítọ́, láti inú ọkàn rẹ̀;

  6. tí kò fi ahọ́n rẹ̀ sọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn, tí kò ṣe ibi sí aládùúgbò rẹ̀ tí kò sì sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí ẹnìkejì rẹ̀,

  7. ní ojú ẹni tí ènìyànkénìyàn di gígàn ṣùgbọ́n ó bọ̀wọ̀ fún àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa, ẹni tí ó búra sí ibi ara rẹ̀ àní tí kò sì yípadà,

  8. tí ó ń yá ni lówó láìsí èlé tí kò sì gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lòdì sí aláìlẹ́ṣẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe èyí ni a kì yóò mì láéláé.

  9. Ta ni yóò gun orí òkè Olúwa lọ? Ta ni yóò dúró ní ibi mímọ́ rẹ̀?

  10. Ẹni tí ó ní ọwọ́ mímọ́ àti àyà funfun, ẹni tí kò gbé ọkàn rẹ̀ sókè sí asán tí kò sì búra èké.

  11. Òun ni yóò rí ìbùkún gbà láti ọ̀dọ̀ Olúwa, àti òdodo lọ́wọ́ Ọlọ́run ìgbàlà rẹ̀.

  12. Èmi kì yóò gbé ohun búburú sí iwájú mi: iṣẹ́ àwọn tí ó yapa ni èmi kórìíra. Wọn kì yóò rọ̀ mọ́ mi.

  13. Agídí ọkàn yóò kúrò lọ́dọ̀ mi; èmi kì yóò mọ ènìyàn búburú.

  14. Ìbùkún ni fún àwọn tí ń pa ìdájọ́ mọ́? Ẹni tí n ṣe ohun tí ó tọ́.

  15. Fún olóòótọ́ ni ìmọ́lẹ̀ yóò tàn fún ní òkùnkùn: olóore-ọ̀fẹ́ àti aláàánú àti òdodo.

  16. Ènìyàn rere fi ojúrere hàn, a sì wínni; ìmòye ni yóò máa fi la ọ̀nà iṣẹ́ rẹ̀.

  17. Dájúdájú a kì yóò le yí ní ipò padà láéláé: olódodo ni a ó máa ṣe ìrántí rẹ láéláé.

  18. Òun kì yóò béèrè ìyìn búburú: ọkàn rẹ̀ ti dúró, ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa.

  19. Ó ti mú ọkàn rẹ̀ gbilẹ̀, ẹ̀rù kí yóò bà á, títí yóò fi rí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀.

  20. Nígbà náà ni ìwọ yóò bẹ̀rù Olúwa, ìwọ yóò sì rí ìmọ̀ Ọlọ́run.

  21. Nítorí Olúwa ni ó ń fún ni ní ọgbọ́n, láti ẹnu rẹ̀ sì ni ìmọ̀ àti òye ti ń wá.

  22. Ó to ìgbàlà fún àwọn olódodo, Òun ni asà fún àwọn tí ń rìn déédé,

  23. Ó pa ipa ọ̀nà ìdájọ́ mọ́ Ó sì ń pa ọ̀nà àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ mọ́.

  24. Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ òdodo àti ìdájọ́, àti àìṣègbè—gbogbo ipa ọ̀nà rere.

  25. Nítorí ọgbọ́n yóò wọ inú ọkàn rẹ ìmọ̀ yóò sì jẹ́ ìtura fún ọkàn rẹ.