Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Murder

131 ẹsẹ · 88 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Èéṣe tí ìwọ fi kẹ́gàn ọ̀rọ̀ Olúwa, tí ìwọ fi ṣe nǹkan tí ó burú lójú rẹ̀, àní tí ìwọ fi fi idà pa Uriah ará Hiti, àti tí ìwọ fi mú obìnrin rẹ̀ láti fi ṣe obìnrin rẹ, o sì fi idà àwọn ọmọ Ammoni pa á.

  2. Àwọn ìránṣẹ́ Absalomu sì ṣe sí Amnoni gẹ́gẹ́ bí Absalomu ti pàṣẹ. Gbogbo àwọn ọmọ ọba sì dìde, olúkúlùkù gun ìbáaka rẹ̀, wọ́n sì sá.

  3. Ọba sì pàṣẹ fún Benaiah pé, “Ṣe bí ó ti wí. Kọlù ú, kí o sì sin ín, kí o sì mú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi àti kúrò lọ́dọ̀ ilé baba mi, tí Joabu ti ta sílẹ̀.

  4. Olúwa yóò sì san ẹ̀jẹ̀ tí ó ti ta sílẹ̀ padà fún un, nítorí tí ó kọlu ọkùnrin méjì, ó sì fi idà rẹ̀ pa wọ́n, Dafidi baba mi kò sì mọ̀. Àwọn méjèèjì ni Abneri ọmọ Neri olórí ogun Israẹli, àti Amasa ọmọ Jeteri olórí ogun Juda, wọ́n jẹ́ olódodo, wọ́n sì sàn ju òun fúnra rẹ̀ lọ.

  5. Baaṣa ọmọ Ahijah ti ilé Isakari sì dìtẹ̀ sí i, Baaṣa sì kọlù ú ní Gibetoni, ìlú àwọn ará Filistini, nígbà tí Nadabu àti gbogbo Israẹli dó ti Gibetoni.

  6. Simri sì wọlé, ó sì kọlù ú, ó sì pa á ní ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n Asa, ọba Juda, ó sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

  7. Bẹ́ẹ̀ ni ó kọ̀wé ní orúkọ Ahabu, ó sì fi èdìdì rẹ̀ dì í, ó sì fi ìwé náà ránṣẹ́ sí àwọn àgbàgbà àti àwọn ọlọ́lá tí ó ń gbé ní ìlú Naboti pẹ̀lú rẹ̀.

  8. Nínú àwọn ìwé náà, ó kọ pé, “Ẹ kéde àwẹ̀, kí ẹ sì fi Naboti sí ipò ọlá láàrín àwọn ènìyàn.

  9. Ṣùgbọ́n kí ẹ fi ènìyàn méjì, ẹni búburú síwájú rẹ̀ láti jẹ́rìí sí i wí pé, ó bú Ọlọ́run àti ọba. Nígbà náà ni kí ẹ mú u jáde, kí ẹ sì sọ ọ́ ní òkúta pa.”

  10. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin méjì sì dé, àwọn ẹni búburú, wọ́n sì jókòó síwájú rẹ̀, wọ́n sì jẹ́rìí lòdì sí Naboti níwájú àwọn ènìyàn wí pé, “Naboti ti bú Ọlọ́run àti ọba.” Nígbà náà ni wọ́n mú jáde kúrò ní ìlú, wọ́n sì sọ ọ́ ní òkúta pa.

  11. Sọ fún un pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí: Ǹjẹ́ ìwọ kò ti pa ènìyàn, o sì ti fi agbára gba ogún rẹ̀?’ Nígbà náà ni kí o wí fún un pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí: Níbi tí ajá gbé lá ẹ̀jẹ̀ Naboti, ni àwọn ajá yóò lá ẹ̀jẹ̀ rẹ, àní tìrẹ!’ ”

  12. Nígbà náà ó mú àkọ́bí ọmọkùnrin rẹ̀, tí kò bá jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọba, ó sì fi rú ẹbọ sísun ní orí ògiri ìlú. Wọ́n sì bínú lórí Israẹli púpọ̀púpọ̀; wọ́n yọ́ kúrò wọ́n sì padà sí ìlú wọn.

  13. “Kí ni ó dé tí olúwa mi fi ń sọkún?” Hasaeli béèrè. “Nítorí pé èmi mọ ibi tí ìwọ yóò ṣe sí Israẹli,” ó sì dáhùn pé, “Ìwọ yóò fi iná si odi agbára wọn, ìwọ yóò, pa àwọn ọ̀dọ́ ọmọkùnrin wọn pẹ̀lú idà, ìwọ yóò kọlù àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ wọn, ìwọ ó sì fọ́ wọn túútúú, ìwọ o sì la inú àwọn aboyún wọn.”

  14. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kejì ó mú aṣọ tí ó nípọn, ó sì kì í bọ inú omi ó sì tẹ̀ ẹ́ sí ojú ọba, bẹ́ẹ̀ ni ó sì kú. Nígbà náà Hasaeli sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

  15. Wọ́n padà lọ sọ fún Jehu, ẹni tí ó wí pé, “Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó sọ nípasẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ Elijah ará Tiṣibi wí pé, ‘Ní orí oko Jesreeli ni àwọn ajá yóò ti jẹ ẹran-ara Jesebeli.

  16. Òkú Jesebeli yóò dàbí ohun ẹ̀gbin ní orí oko Jesreeli, dé bi pé, ẹnikẹ́ni kì yóò lè sọ pé, “Jesebeli ni èyí.” ’ ”

  17. Ní ọjọ́ kan, nígbà tí ó sùn nínú ilé òrìṣà Nisroki, ọmọkùnrin rẹ̀ Adrameleki àti Ṣareseri gé e lulẹ̀ pẹ̀lú idà, wọ́n sì sálọ sí ilẹ̀ Ararati Esarhadoni ọmọkùnrin rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

  18. Pẹ̀lúpẹ̀lú, Manase pẹ̀lú ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ púpọ̀ tí ó kún Jerusalẹmu láti ìkangun dé ìkangun ní ẹ̀gbẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti mú Juda ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni, kí wọ́n lè ṣe ohun búburú ní ojú Olúwa.

  19. Ní ọjọ́ kan mo lọ sí ilé Ṣemaiah ọmọ Delaiah, ọmọ Mehetabeeli, ẹni tí a há mọ́ sínú ilé rẹ̀. Ó wí pé, “Jẹ́ kí a pàdé ní ilé Ọlọ́run nínú tẹmpili, kí o sì jẹ́ kí a pa àwọn ìlẹ̀kùn tẹmpili dé, nítorí àwọn ènìyàn ń bọ̀ láti pa ọ́, ní òru ni wọn yóò wá láti pa ọ́.”

  20. Apànìyàn a dìde ní àfẹ̀mọ́júmọ́, a sì pa tálákà àti aláìní, àti ní òru a di olè.

  21. Nítorí ẹni tí ó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ rántí; òun kò kọ ẹkún àwọn tí a pọ́n lójú.

  22. Ó lúgọ ní bùba nítòsí ìletò. Ò gọ níbi ìkọ̀kọ̀ láti pa aláìṣẹ̀. Ojú rẹ̀ ń ṣọ́ àwọn tálákà ní ìkọ̀kọ̀.

  23. Ó ba ní ní bùba bí i kìnnìún nínú pàǹtí; Ó ba ní bùba láti mú àwọn aláìní ìrànwọ́; ó mú àwọn aláìlólùrànlọ́wọ́, ó sì wọ́ wọn lọ sínú àwọ̀n rẹ̀.

  24. Ó ba, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀; kí tálákà ba à le bọ́ sí ọwọ́ agbára rẹ̀.

  25. Gbà mí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀, Ọlọ́run, ìwọ Ọlọ́run ìgbàlà mi, ahọ́n mi yóò sì máa kọrin òdodo rẹ kíkan.