Topheth
A tún mọ̀ ọ́n sí: Tophet
31.7600, 35.2200 Wo lórí Google Maps
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Topheth
Ó sì ba ohun mímọ́ Tofeti jẹ́, tí ó wà ní àfonífojì Beni-Hinnomu, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnìkan tí ó lè lò ó fún ẹbọ rírú fún ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tàbí ọmọ rẹ̀ obìnrin nínú iná sí Moleki.
Wọ́n ti kọ́ àwọn ibi gíga ti Tofeti ní àfonífojì Beni-Hinnomu láti sun àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn nínú iná èyí tí èmi kò pàṣẹ tí kò sì wá sí ọkàn mi.
Nítorí náà kíyèsára ọjọ́ ń bọ̀, ni Olúwa wí, nígbà tí àwọn ènìyàn kò ní pè é ní Tafeti tàbí àfonífojì ti Beni-Hinnomu; ṣùgbọ́n yóò ma jẹ àfonífojì ìparun, nítorí wọn yóò sin òkú sí Tofeti títí kò fi ní sí ààyè mọ́.
Nítorí náà ṣọ́ra ọjọ́ ń bọ̀ ni Olúwa wí nígbà tí àwọn ènìyàn kì yóò pe ibí ní Tofeti mọ́ tàbí àfonífojì ọmọ Hinnomu, ṣùgbọ́n àfonífojì Ìpakúpa.
Kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. Èmi a fọ́ orílẹ̀-èdè yìí àti ìlú yìí gẹ́gẹ́ bí ìkòkò amọ̀ yìí ṣe fọ́ tí kò sì ní sí àtúnṣe. Wọn a sì sin àwọn òkú sí Tofeti títí tí kò fi ní sí ààyè mọ́.
Èyí ni ohun tí èmi yóò ṣe sí ibí yìí àti àwọn tí ń gbé ní ibí yìí ni Olúwa wí. Èmi yóò mú ìlú yìí dàbí Tofeti.
Àwọn ilé tí ó wà ní Jerusalẹmu àti ti ọba ìlú Juda ni a ó sọ di àìmọ́ bí Tofeti, gbogbo ilé tí wọ́n ti ń sun tùràrí ni orí òrùlé sí gbogbo ogun ọ̀run, tí a sì ń rú ẹbọ mímu sí ọlọ́run mìíràn.’ ”
Jeremiah sì padà láti Tofeti níbi tí Olúwa rán an sí láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ó sì dúró ní gbangba tẹmpili Olúwa, ó sì sọ fún gbogbo ènìyàn pé,