Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Murder: Of saints, specially avenged
Àwọn ẹsẹ nípa Of saints, specially avenged
Ẹ yọ̀ ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀ nítorí òun yóò gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀; yóò sì gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá a rẹ̀ yóò sì ṣe ètùtù fún ilẹ̀ àti ènìyàn rẹ̀.
Kí ẹ̀yin lè jẹ̀bi gbogbo ẹ̀jẹ̀ àwọn olódodo tí ẹ ta sílẹ̀ ní ayé, láti ẹ̀jẹ̀ Abeli títí dé ẹ̀jẹ̀ Sekariah ọmọ Berekiah ẹni tí ẹ pa nínú tẹmpili láàrín ibi pẹpẹ àti ibi ti ẹ yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run.
“Yọ̀ lórí rẹ̀, ìwọ ọ̀run! Ẹ yọ̀, ẹ̀yin ènìyàn Ọlọ́run! Ẹ yọ̀, ẹ̀yin aposteli mímọ́ àti wòlíì! Nítorí Ọlọ́run ti gbẹ̀san yín lára rẹ̀ nítorí ìdájọ́ tí ó gbé ka orí rẹ.”
Àti nínú rẹ̀ ní a gbé ri ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì, àti ti àwọn ènìyàn mímọ́, àti ti gbogbo àwọn tí a pa lórí ilẹ̀ ayé.”