Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Murder: Requires blood for

3 ẹsẹ · 88 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Requires blood for

  1. Nítòótọ́ ẹ̀jẹ̀ yín, àní ẹ̀mí yín, ni èmi yóò sì béèrè; lọ́wọ́ gbogbo ẹranko ni èmí yóò béèrè rẹ̀, àti lọ́wọ́ ènìyàn, lọ́wọ́ arákùnrin olúkúlùkù ènìyàn ni èmi yóò béèrè ẹ̀mí ènìyàn.

  2. “ ‘Má ṣe sọ ilẹ̀ tí ẹ wà di àìmọ́. Ìtàjẹ̀ sílẹ̀ sọ ilẹ̀ náà di àìmọ́. Àtúnṣe kì yóò sí fún ilẹ̀ tí a ti ta ẹ̀jẹ̀ lé lórí, àyàfi ẹ̀jẹ̀ ẹni tí ó ta á sílẹ̀.

  3. Olúwa yóò sì san ẹ̀jẹ̀ tí ó ti ta sílẹ̀ padà fún un, nítorí tí ó kọlu ọkùnrin méjì, ó sì fi idà rẹ̀ pa wọ́n, Dafidi baba mi kò sì mọ̀. Àwọn méjèèjì ni Abneri ọmọ Neri olórí ogun Israẹli, àti Amasa ọmọ Jeteri olórí ogun Juda, wọ́n jẹ́ olódodo, wọ́n sì sàn ju òun fúnra rẹ̀ lọ.