Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Murder

131 ẹsẹ · 88 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀, ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọ. Wọ́n fi wọ́n rú ẹbọ sí ère Kenaani, ilẹ̀ náà sì di àìmọ́ fún ẹ̀jẹ̀.

  2. Bí wọn bá wí pé, “Wá pẹ̀lú wa; jẹ́ kí á ba ní ibùba fún ẹ̀jẹ̀ ẹnìkan, jẹ́ kí á lúgọ ní ìkọ̀kọ̀ de aláìṣẹ̀ ní àìnídìí;

  3. Nítorí ẹsẹ̀ wọn ń sáré sí ẹ̀ṣẹ̀, wọ́n yára láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.

  4. Àwọn ohun mẹ́fà wà tí Olúwa kórìíra, ohun méje ní ó jẹ́ ìríra sí i,

  5. Ojú ìgbéraga, ahọ́n tó ń parọ́ ọwọ́ tí ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀,

  6. Nígbà tí ẹ bá tẹ́ ọwọ́ yín sókè ni àdúrà, Èmi yóò fi ojú mi pamọ́ fún un yín, kódà bí ẹ bá gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdúrà, Èmi kò ni tẹ́tí sí i. “Ọwọ́ yín kún fún ẹ̀jẹ̀.

  7. Wo bí ìlú òtítọ́ ṣe di àgbèrè! Ó ti kún fún ìdájọ́ òtítọ́ nígbà kan rí, òdodo ń gbé ibẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí, ṣùgbọ́n báyìí àwọn apànìyàn!

  8. Kíyèsi i, Olúwa ń jáde bọ̀ láti ibùgbé rẹ̀ láti jẹ àwọn ènìyàn ilẹ̀ ayé ní ìyà fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ayé yóò sì sọ àwọn ẹ̀jẹ̀ tí a ta sí orí rẹ̀; kì yóò sì fi àwọn tí a ti pa pamọ́ mọ́.

  9. Ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ yín ló ti yà yín kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run yín; ẹ̀ṣẹ̀ yín ti fi ojú u rẹ̀ pamọ́ fún un yín tó bẹ́ẹ̀ tí òun kò fi le gbọ́.

  10. Nítorí ọwọ́ yín di aláìmọ́ fún ẹ̀jẹ̀, àti ìka ọwọ́ yín fún ẹ̀bi. Ètè yín ń pa irọ́ púpọ̀, ahọ́n yín sì ń sọ̀rọ̀ nǹkan ibi.

  11. Lórí aṣọ rẹ ni wọ́n bá ẹ̀jẹ̀ àwọn tálákà aláìṣẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ kò ká wọn mọ́ níbi tí wọ́n ti ń rùn wọlé. Síbẹ̀ nínú gbogbo èyí

  12. Nítorí wọ́n ti gbàgbé mi, wọ́n sì ti sọ ibí di ilé fún òrìṣà àjèjì; wọ́n ti sun ẹbọ nínú rẹ̀ fún òrìṣà tí àwọn baba wọn tàbí tí ọba Juda kò mọ̀ rí, wọ́n ti fi ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ kún ilẹ̀ yìí.

  13. Wọ́n ti kọ́ ibi gíga fún Baali láti sun ọmọkùnrin wọn gẹ́gẹ́ bí ohun ẹbọ sísun sí Baali—èyí tí èmi kò pàṣẹ láti ṣe, tí èmi kò sì sọ, tàbí tí kò sì ru sókè láti inú ọkàn mi.

  14. Nítorí náà ṣọ́ra ọjọ́ ń bọ̀ ni Olúwa wí nígbà tí àwọn ènìyàn kì yóò pe ibí ní Tofeti mọ́ tàbí àfonífojì ọmọ Hinnomu, ṣùgbọ́n àfonífojì Ìpakúpa.

  15. “ ‘Ní ibí yìí ni èmi yóò ti pa èrò Juda àti Jerusalẹmu run. Èmí yóò mú wọn ṣubú nípa idà níwájú àwọn ọ̀tá wọn, lọ́wọ́ àwọn tí ó ń wá ẹ̀mí wọn. Èmi yóò sì fi òkú wọn ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹranko ilẹ̀.

  16. Èmi yóò sọ ìlú yìí di ahoro àti ohun ẹ̀gàn, gbogbo àwọn tí ń kọjá yóò bẹ̀rù wọn yóò sì máa fòyà nítorí gbogbo ọgbẹ́ rẹ̀.

  17. Èmi yóò mú kí wọ́n jẹ ẹran-ara ọmọ wọn ọkùnrin àti ẹran-ara ọmọ wọn obìnrin, ẹnìkínní yóò sì jẹ ẹran-ara ẹnìkejì, nígbà ìdótì àti ìhámọ́ láti ọwọ́ ọ̀tá wọn, àti àwọn tí ó ń wá ẹ̀mí wọn.’

  18. “Ṣùgbọ́n ojú rẹ àti ọkàn rẹ wà lára èrè àìṣòótọ́ láti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ìnilára àti ìlọ́nilọ́wọ́gbà.”

  19. Ẹ mọ̀ dájú pé tí ẹ bá pa mí, ẹ ó mú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ wá sórí ara yín, sórí ìlú yìí àti àwọn olùgbé inú rẹ̀; nítorí pé nítòótọ́ ni Olúwa ti rán mi láti sọ ọ̀rọ̀ yìí fún un yín.”

  20. Nígbà tí wọ́n dé ìlú náà; Iṣmaeli ọmọkùnrin Netaniah àti àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ pa wọ́n, wọ́n sì sọ òkú wọn sínú ihò kan.

  21. Èyí ṣẹlẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn wòlíì àti àìṣedéédéé àwọn olórí àlùfáà, tí ó ta ẹ̀jẹ̀ àwọn olódodo sílẹ̀ láàrín rẹ̀.

  22. Nísinsin yìí wọ́n ń rìn kiri ní òpópó bí ọkùnrin tí ó fọ́jú. Ẹ̀jẹ̀ ara wọn sọ wọ́n di àbàwọ́n tí kò sẹ́ni tó láyà láti fọwọ́ kan aṣọ wọn.

  23. Ẹ̀yin ti sọ òkú yín di púpọ̀ nínú ìlú yìí, òkú sì ti kún gbogbo ìgboro rẹ̀.

  24. Kí ó sì wí pé, ‘Èyí yìí ní ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Ìwọ ìlú ńlá tí ó mú ìparun wá sórí ara rẹ nípa títàjẹ̀sílẹ̀ ní àárín rẹ, tí ó sì ba ara rẹ̀ jẹ́ nípa ṣíṣe àwọn ère.

  25. Ìwọ ti jẹ̀bi nítorí ẹ̀jẹ̀ tí ìwọ ti ta sílẹ̀, àti pé àwọn ère tí ó ṣe tí bà ọ́ jẹ́. Ìwọ tí mú ọjọ́ rẹ súnmọ́ tòsí, ìparí àwọn ọdún rẹ sì ti dé. Nítorí náà èmi yóò fi ọ ṣe ohun ẹ̀gàn lójú àwọn orílẹ̀-èdè àti ohun ẹ̀sín lójú gbogbo ìlú.