Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Murder

131 ẹsẹ · 88 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ṣùgbọ́n ẹ má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni nínú yín jìyà bí apànìyàn, tàbí bí olè, tàbí bí olùṣe búburú, tàbí bí ẹni tí ń tojú bọ̀ ọ̀ràn ẹlòmíràn.

  2. Ẹnikẹ́ni tí ó ba kórìíra arákùnrin rẹ̀ apànìyàn ni, ẹ̀yin sì mọ́ pé kò sí apànìyàn tí ó ni ìyè àìnípẹ̀kun láti máa gbé inú rẹ̀.

  3. Wọ́n kígbe ní ohùn rara, wí pé, “Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa Olódùmarè, ẹni mímọ́ àti olóòtítọ́ ìwọ kì yóò ṣe ìdájọ́ kí o sì gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ wa mọ́ lára àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé?”

  4. “Yọ̀ lórí rẹ̀, ìwọ ọ̀run! Ẹ yọ̀, ẹ̀yin ènìyàn Ọlọ́run! Ẹ yọ̀, ẹ̀yin aposteli mímọ́ àti wòlíì! Nítorí Ọlọ́run ti gbẹ̀san yín lára rẹ̀ nítorí ìdájọ́ tí ó gbé ka orí rẹ.”

  5. Àti nínú rẹ̀ ní a gbé ri ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì, àti ti àwọn ènìyàn mímọ́, àti ti gbogbo àwọn tí a pa lórí ilẹ̀ ayé.”

  6. Nítorí ni òde ni àwọn ajá gbé wà, àti àwọn oṣó, àti àwọn àgbèrè, àti àwọn apànìyàn, àti àwọn abọ̀rìṣà, àti olúkúlùkù ẹni tí ó fẹ́ràn èké tí ó sì ń hùwà èké.