Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Man

106 ẹsẹ · 114 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Èyí ni àkọsílẹ̀ ìran Adamu. Nígbà tí Ọlọ́run dá ènìyàn, ní àwòrán Ọlọ́run ni ó dá a.

  2. Àti akọ àti abo ni Ó dá wọn, ó sì súre fún wọn, ó sì pe orúkọ wọ́n ní Adamu ní ọjọ́ tí ó dá wọn.

  3. Ẹ̀rù yín yóò mú ojo wà lára gbogbo ẹranko àti gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run, àti gbogbo àwọn ẹ̀dá tí ń rìn nílẹ̀; àti gbogbo ẹja òkun; a fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́.

  4. Gbogbo ohun tó wà láààyè tí ó sì ń rìn, ni yóò jẹ́ oúnjẹ fún un yín, bí mo ṣe fi ewéko fún un yín náà ni mo fi ohun gbogbo fún un yín.

  5. Kíyèsi i, òun kò gbẹ́kẹ̀lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, nínú àwọn angẹli rẹ̀ ní ó sì rí ẹ̀ṣẹ̀.

  6. Mélòó mélòó àwọn tí ń gbé inú ilé amọ̀, ẹni tí ìpìlẹ̀ wọ́n jásí erùpẹ̀ tí yóò di rírun kòkòrò.

  7. A pa wọ́n run láàrín òwúrọ̀ àti àṣálẹ́ wọ́n sì parun títí láé, láìrí ẹni kà á sí.

  8. A kò ha ké okùn iye wọ́n kúrò bí? Wọ́n kú, àní láìlọ́gbọ́n?’

  9. Èmi yóò wí fún Ọlọ́run pé, má ṣe dá mi lẹ́bi; fihàn mí nítorí ìdí ohun tí ìwọ fi ń bá mi jà.

  10. Ó ha tọ́ tí ìwọ ìbá fi máa ni mí lára, tí ìwọ ìbá fi máa gan iṣẹ́ ọwọ́ rẹ, tí ìwọ yóò fi máa tàn ìmọ́lẹ̀ sí ìmọ̀ ènìyàn búburú?

  11. “Ọwọ́ rẹ ni ó mọ mi, tí ó sì da mi. Síbẹ̀ ìwọ tún yípadà láti jẹ mí run.

  12. Èmi bẹ̀ ọ́ rántí pé ìwọ ti mọ mí bí amọ̀. Ìwọ yóò ha sì tún mú mi padà lọ sínú erùpẹ̀?

  13. Ìwọ kò ha ti tú mí dà jáde bí i wàrà, ìwọ kò sì mú mí dìpọ̀ bí i wàràǹkàṣì?

  14. Ìwọ sá ti fi àwọ̀ ẹran-ara wọ̀ mí, ìwọ sì fi egungun àti iṣan ṣọgbà yí mi ká.

  15. “Ènìyàn lè è ṣe rere fún Ọlọ́run? Bí ọlọ́gbọ́n ti í ṣe rere fún ara rẹ̀?

  16. Ohun ayọ̀ ha ni fún Olódùmarè pé olódodo ni ìwọ? Tàbí èrè kí ni fún un ti ìwọ mú ọ̀nà rẹ̀ pé?

  17. “Yóò ha bá ọ wí bí, nítorí ìbẹ̀rù Ọlọ́run rẹ? Yóò ha bá ọ lọ sínú ìdájọ́ bí?

  18. Ìwà búburú rẹ kò ha tóbi, àti ẹ̀ṣẹ̀ rẹ láìníye?

  19. Èéha ti ṣe tí a ó fi dá ènìyàn láre lọ́dọ̀ Ọlọ́run? Tàbí ẹni tí a bí láti inú obìnrin wá yóò ha ṣe mọ́?

  20. Kíyèsi i, òṣùpá kò sì lè tàn ìmọ́lẹ̀, àní àwọn ìràwọ̀ kò mọ́lẹ̀ ní ojú rẹ̀,

  21. kí a má sọ ènìyàn tí i ṣe ìdin, àti ọmọ ènìyàn tí í ṣe kòkòrò!”

  22. “Ìwọ rò pé èyí ha tọ́, tí ìwọ wí pé, òdodo mi ni èyí níwájú Ọlọ́run?

  23. Nítorí tí ìwọ wí pé èrè kí ní yóò jásí fún ọ, tàbí èrè kí ni èmi yóò fi jẹ́ ju èrè ẹ̀ṣẹ̀ mi lọ.

  24. “Èmi ó dá ọ lóhùn àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ pẹ̀lú rẹ.

  25. Síjú wo ọ̀run; kí o rí i, kí ó sì bojú wo àwọsánmọ̀ tí ó ga jù ọ́ lọ.