Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Afflictions and Adversities

526 ẹsẹ · 5 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Olúwa, gbọ́ ti aláìní, kì ó sì kọ àwọn ìgbèkùn sílẹ̀.

  2. Pẹ̀lúpẹ̀lú ìwọ ti mú mi rí ìdààmú, tí ó pọ̀ tí ó sì korò, ìwọ yóò tún sọ ayé mi jí ìwọ yóò sì tún mú mi sọ sókè láti ọ̀gbun ilẹ̀ wá. Ìwọ yóò sọ ọlá mi di púpọ̀.

  3. Ara mi àti ọkàn mi le è kùnà ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni agbára ẹ̀mí mi àti ìpín mi títí láé.

  4. ìbínú Ọlọ́run dìde sí wọn ó pa àwọn tí ó jùlọ nínú wọn, ó sì lu àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Israẹli bolẹ̀.

  5. Nínú gbogbo ìwọ̀nyí, wọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ síwájú; nínú gbogbo iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, wọ́n kò gbàgbọ́.

  6. O fi òpin sí ayé wọn nínú asán àti ọdún wọn nínú ìpayà.

  7. Nígbàkígbà tí Ọlọ́run bá pa wọ́n, wọn yóò wá a kiri; wọn yóò fi ìtara yípadà sí i.

  8. Ìwọ tí ó fi mí sí kòtò jíjìn, ní ibi ọ̀gbun tó ṣókùnkùn.

  9. Ìbínú rẹ ṣubú lé mi gidigidi; ìwọ ti fi àwọn ìjì rẹ borí mi.

  10. Ìbínú rẹ ti kọjá lára mi; ìbẹ̀rù rẹ ti gé mi kúrò.

  11. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìwọ ti ṣá tì, ìwọ sì kórìíra; ìwọ kún fún ìrunú sí ẹni àmì òróró rẹ.

  12. Ìwọ ti sọ májẹ̀mú ìránṣẹ́ rẹ di òfo; ìwọ tàbùkù adé rẹ nínú eruku.

  13. Ìwọ ti wó gbogbo àwọn odi rẹ̀ ìwọ sọ ibi gíga rẹ̀ di ahoro.

  14. Àwọn tí ń kọjá lọ fi ṣe ìjẹ; ó ti di ẹ̀gàn àwọn olùbágbé rẹ̀.

  15. Ìwọ ti gbé ọwọ́ ọ̀tún ọ̀tá rẹ̀ sókè; ìwọ mú gbogbo ọ̀tá rẹ̀ yọ̀.

  16. Pẹ̀lú, ìwọ ti yí ojú idà rẹ̀ padà, ìwọ kò sì dúró tì í nínú ogun.

  17. Ìwọ ti mú ògo rẹ̀ kùnà, ìwọ si wó ìtẹ́ rẹ̀ palẹ̀ sílẹ̀ẹ́lẹ̀.

  18. Ìwọ ti gé ọjọ́ èwe rẹ̀ kúrú; ìwọ sì fi ìtìjú bò ó.

  19. A pa wá run nípa ìbínú rẹ nípa ìbínú rẹ ara kò rọ̀ wá.

  20. Mú inú wa dùn bí ọjọ́ tí ìwọ ti pọ́n wa lójú, fún ọjọ́ púpọ̀ tí àwa ti rí wàhálà.

  21. Ìbùkún ni fún ènìyàn náà tí ìwọ bá wí, Olúwa, ẹni tí ìwọ kọ́ nínú òfin rẹ,

  22. Ìwọ gbà á kúrò nínú ọjọ́ ibi, títí a ó fi wa ihò sílẹ̀ fún ẹni búburú.

  23. Bí kò ṣe pé Olúwa fún mi ní ìrànlọ́wọ́, èmi fẹ́rẹ̀ máa gbé ní ilẹ̀ tí ó dákẹ́.

  24. Nígbà tí mo sọ pé, “Ẹsẹ̀ mi ń yọ̀”, Olúwa, ìfẹ́ rẹ̀ ni ó tì mí lẹ́yìn.

  25. Nígbà tí àníyàn ńlá wà nínú mi, ìtùnú rẹ̀ mú ayọ̀ sí ọkàn mi.