Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Afflictions and Adversities

526 ẹsẹ · 5 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Hu, ìwọ ẹnu-ọ̀nà! Kígbe, ìwọ ìlú! Yọ́ kúrò, gbogbo ẹ̀yin Filistia! Èéfín kurukuru kan ti àríwá wá, kò sì ṣí amóríbọ́ kan nínú ẹgbẹ́ wọn.

  2. Kí ni ìdáhùn tí a ó fún agbẹnusọ orílẹ̀-èdè náà? “Olúwa ti fi ìdí Sioni kalẹ̀, àti nínú rẹ̀ ni àwọn ènìyàn rẹ̀ tí a ti pọ́n ọn lójú yóò ti rí ààbò o wọn.”

  3. Yóò sì jẹ́ àmì àti ẹ̀rí sí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní ilẹ̀ Ejibiti. Nígbà tí wọ́n bá ké pe Olúwa nítorí àwọn aninilára wọn, yóò rán olùgbàlà àti olùgbèjà kan sí wọn tí yóò sì gbà wọ́n sílẹ̀.

  4. Olúwa yóò fi àjàkálẹ̀-ààrùn kan bá Ejibiti jà; yóò bá wọn jà yóò sì tún wò wọ́n sàn. Wọn yóò yípadà sí Olúwa, Òun yóò sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn yóò sì wò wọ́n sàn.

  5. Ìwọ ti jẹ́ ààbò fún àwọn òtòṣì ààbò fún aláìní nínú ìpọ́njú rẹ̀ ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjì bòòji kúrò lọ́wọ́ ooru. Nítorí pé èémí àwọn ìkà dàbí ìjì tí ó bì lu ògiri

  6. Ọkàn mi ń pòùngbẹẹ̀ rẹ ní ọ̀gànjọ́ òru; ní òwúrọ̀ ni ẹ̀mí mi ń ṣàfẹ́rí rẹ. Nígbà tí ìdájọ́ rẹ bá sọ̀kalẹ̀ sórí ayé àwọn ènìyàn yóò kọ́ ìṣòdodo.

  7. Nítorí èyí báyìí ni ètùtù yóò ṣe wà fún ẹ̀ṣẹ̀ Jakọbu, èyí ni yóò sì jẹ́ èso kíkún ti ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ rẹ. Nígbà tí ó bá mú kí àwọn òkúta pẹpẹ dàbí òkúta ẹfun tí a fọ́ sí wẹ́wẹ́, kì yóò sí ère Aṣerah tàbí pẹpẹ tùràrí tí yóò wà ní ìdúró.

  8. Ẹ̀yin ènìyàn Sioni, tí ń gbé ní Jerusalẹmu, ìwọ kì yóò sọkún mọ́. Báwo ni àánú rẹ̀ yóò ti pọ̀ tó nígbà tí ìwọ bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́! Bí ó bá ti gbọ́, òun yóò dá ọ lóhùn.

  9. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa fún ọ ní àkàrà ìyà àti omi ìpọ́njú, àwọn olùkọ́ rẹ kì yóò fi ara sin mọ́; pẹ̀lú ojú rẹ ni ìwọ ó rí wọn.

  10. Ẹ tù ú nínú, ẹ tu ènìyàn mi nínú, ni Ọlọ́run yín wí.

  11. Sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ fún Jerusalẹmu kí o sì kéde fún un pé iṣẹ́ àṣekára rẹ̀ ti parí, pé à ti san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, pé ó ti rí i gbà láti ọwọ́ Olúwa ìlọ́po méjì fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

  12. Ó ń fi agbára fún àwọn aláàárẹ̀ ó sì fi kún agbára àwọn tí agara dá.

  13. Nítorí náà má bẹ̀rù, nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ; má ṣe jẹ́ kí àyà kí ó fò ọ́, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ. Èmi yóò fún ọ lókun èmi ó sì ràn ọ́ lọ́wọ́. Èmi ó gbé ọ ró pẹ̀lú ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi.

  14. Nítorí Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ, tí ó di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú tí ó sì sọ fún ọ pé, má ṣe bẹ̀rù; Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.

  15. Má ṣe bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu kòkòrò, ìwọ Israẹli kékeré, nítorí Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́,” ni Olúwa wí, olùdáǹdè rẹ, Ẹni Mímọ́ ti Israẹli.

  16. “Àwọn tálákà àti aláìní wá omi, ṣùgbọ́n kò sí; ahọ́n wọn gbẹ fún òǹgbẹ. Ṣùgbọ́n Èmi Olúwa yóò dá wọn lóhùn; Èmi, Ọlọ́run Israẹli, kì yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀.

  17. Koríko odò títẹ̀ kan ni òun kì yóò fọ́, àti òwú-fìtílà tí ń jó tan an lọ lòun kì yóò fẹ́ pa. Ní òdodo ni yóò mú ìdájọ́ wá;

  18. Nígbà tí ìwọ bá ń la omi kọjá, Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ; àti nígbà tí ìwọ bá ń la odò kọjá wọn kì yóò bò ọ́ mọ́lẹ̀. Nígbà tí ìwọ bá la iná kọjá, kò ní jó ọ; ahọ́n iná kò ní jó ọ lára.

  19. Mo dá ìmọ́lẹ̀, mo sì dá òkùnkùn, Mo mú àlàáfíà wá, Mo sì dá àjálù; Èmi Olúwa ni ó ṣe nǹkan wọ̀nyí.

  20. Ẹ hó fún ayọ̀, ẹyin ọ̀run; yọ̀, ìwọ ilẹ̀ ayé; bú sórin, ẹ̀yin òkè ńlá! Nítorí Olúwa tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú yóò sì ṣàánú fún àwọn ẹni tí a ń pọ́n lójú.

  21. Olúwa Olódùmarè ti fún mi ni ahọ́n tí a fi iṣẹ́ rán, láti mọ àwọn ọ̀rọ̀ tí ó lè gbé àwọn aláàárẹ̀ ró. O jí mi láràárọ̀, o jí etí mi láti gbọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí à ń kọ́.

  22. Nítorí Olúwa Olódùmarè ràn mí lọ́wọ́, a kì yóò dójútì mí. Nítorí náà ni mo ṣe gbé ojú mi ró bí òkúta akọ èmi sì mọ pé, ojú kò ní tì mí.

  23. Ẹni tí ó dá mi láre wà nítòsí. Ta ni ẹni náà tí yóò fẹ̀sùn kàn mí? Jẹ́ kí a kojú ara wa! Ta ni olùfisùn mi? Jẹ́ kí ó kò mí lójú!

  24. Olúwa Olódùmarè ni ó ń ràn mí lọ́wọ́. Ta ni ẹni náà tí yóò dá mi lẹ́bi? Gbogbo wọn yóò gbó bí aṣọ; kòkòrò ni yóò sì jẹ wọn run.

  25. Ta ni nínú yín tí ó bẹ̀rù Olúwa tí ó sì ń gbọ́rọ̀ sí ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́nu? Jẹ́ kí ẹni tí ń rìn ní òkùnkùn tí kò ní ìmọ́lẹ̀, kí ó gbẹ́kẹ̀lé orúkọ Olúwa kí o sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run rẹ̀.