Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Abraham

314 ẹsẹ · 39 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nítorí náà, Olúwa wí fún un pé, “Mú abo màlúù, ewúrẹ́ àti àgbò ọlọ́dún mẹ́ta mẹ́ta wá, àti àdàbà kan àti ọmọ ẹyẹlé kan.”

  2. Abramu sì mú gbogbo nǹkan wọ̀nyí wá, ó sì là wọ́n sí méjì méjì, ó sì fi ẹ̀là èkínní kọjú sí èkejì, ṣùgbọ́n kò la àwọn ẹyẹ ní tiwọn.

  3. Àwọn ẹyẹ igún sì ń wá sórí òkú ẹran náà, Abramu sì ń lé wọn.

  4. Bí oòrùn ti ń wọ̀, Abramu sùn lọ fọnfọn, òkùnkùn biribiri tí ó kún fún ẹ̀rù sì bò ó.

  5. Nígbà náà ni Olúwa wí fún Abramu pé, “Mọ èyí dájú pé, irú-ọmọ rẹ yóò ṣe àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì, wọn ó sì sọ wọn di ẹrú, wọn ó sì pọ́n wọn lójú fún irinwó (400) ọdún.

  6. Ṣùgbọ́n orílẹ̀-èdè náà tí wọn yóò máa sìn, ni èmi ó dá lẹ́jọ́, lẹ́yìn náà ni wọn ó sì jáde pẹ̀lú ọrọ̀ púpọ̀.

  7. Ṣùgbọ́n ìwọ yóò tọ àwọn baba rẹ lọ ni àlàáfíà, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ yóò sì di arúgbó kí a tó gbé ọ sin.

  8. Ní ìran kẹrin àwọn ìran rẹ yóò padà wá sí ibi. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ará Amori kò ì tí ì kún òsùwọ̀n.”

  9. Nígbà tí oòrùn wọ̀ tí ilẹ̀ sì ṣú, ìkòkò iná tí ń ṣèéfín àti ọwọ́ iná sì ń kọjá láàrín ẹ̀là ẹran náà.

  10. Ní ọjọ́ náà gan an ni Olúwa dá májẹ̀mú pẹ̀lú Abramu, ó sì wí pé, “Àwọn ìran rẹ ni èmi yóò fi ilẹ̀ yìí fún, láti odò Ejibiti dé odò ńlá Eufurate:

  11. ilẹ̀ àwọn ará Keni, àti ti ará Kenissiti, àti ará Kadmoni,

  12. àti ti ará Hiti, àti ti ará Peresi, àti ti ará Refaimu.

  13. Àti ti ará Amori, àti ti ará Kenaani, àti ti ará Girgaṣi àti ti ará Jebusi.”

  14. Lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá tí Abramu ti ń gbé ni Kenaani ni Sarai mú ọmọbìnrin, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ Hagari, tí í ṣe ará Ejibiti fún Abramu ọkọ rẹ̀ láti fi ṣe aya.

  15. Hagari sì bí ọmọkùnrin kan fún Abramu, Abramu sì pe orúkọ rẹ̀ ní Iṣmaeli.

  16. Abramu jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún nígbà tí Hagari bí Iṣmaeli fún un.

  17. Ní ìgbà tí Abramu di ẹni ọ̀kàndínlọ́gọ́rùn-ún ọdún, Olúwa farahàn án, ó sì wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run alágbára, máa rìn níwájú mi, kí o sì jẹ́ aláìlábùkù.

  18. Èmi yóò sì fi ìdí májẹ̀mú mi múlẹ̀ pẹ̀lú rẹ. Èmi yóò sì sọ ọ́ di púpọ̀ gidigidi.”

  19. Abramu sì dojúbolẹ̀, Ọlọ́run sì wí fún un pé.

  20. “Ní ti èmi, májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ nìyí. Ìwọ yóò di baba orílẹ̀-èdè púpọ̀.

  21. A kì yóò pe orúkọ rẹ̀ ní Abramu mọ́, bí kò ṣe Abrahamu, nítorí, mo ti sọ ọ́ di baba orílẹ̀-èdè púpọ̀.

  22. Èmi yóò mú ọ bí si lọ́pọ̀lọ́pọ̀, ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ni èmi yóò sì mú ti ara rẹ jáde wá, àwọn ọba pẹ̀lú yóò sì ti inú rẹ jáde.

  23. Èmi yóò sì gbé májẹ̀mú mi kalẹ̀ láàrín tèmi tìrẹ, ní májẹ̀mú ayérayé àti láàrín irú-ọmọ rẹ ní ìran-ìran wọn, láti máa ṣe Ọlọ́run rẹ àti ti irú-ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ.

  24. Gbogbo ilẹ̀ Kenaani níbi tí ìwọ ti ṣe àjèjì ni èmi yóò fi fún ọ àti fún irú-ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ láéláé. Èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn.”

  25. Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Abrahamu pé, “Ìwọ máa pa májẹ̀mú mi mọ́, ìwọ àti irú-ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ àti àwọn ìran tí ó ń bọ̀.