- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 1446–1406 BC
The Wilderness Years
Forty years of wandering in the desert test Israel's faith and prepare a new generation to enter the promised land.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Numeri 25:9nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
ṣùgbọ́n gbogbo àwọn tí ó kú nínú àjàkálẹ̀-ààrùn náà jẹ́ ẹgbàá méjìlá (24,000).
- Numeri 25:10nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Olúwa sì tún sọ fún Mose pé,
- Numeri 25:11nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
“Finehasi ọmọ Eleasari ọmọ Aaroni, àlùfáà, ti yí ìbínú mi padà kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli, nítorí tí ó ní ìtara bí èmi náà ti ní ìtara fún iyì mi láàrín wọn, kí ó lè jẹ́ pé èmi ló pa wọ́n run nínú ìtara mi sí wọn.
- Numeri 25:12nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Nítorí náà sọ fún un pé èmi ṣe májẹ̀mú àlàáfíà mi pẹ̀lú rẹ̀.
- Numeri 25:13nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Òun àti irú-ọmọ rẹ̀ yóò ní májẹ̀mú láéláé fún iṣẹ́ àlùfáà, nítorí pé ó ní ìtara fún Ọlọ́run rẹ̀ láti fi yẹ́ Ọlọ́run sí, ó sì ṣe ètùtù fún àwọn ọmọ Israẹli.”
- Numeri 25:14nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Orúkọ ọmọ Israẹli tí a pa pẹ̀lú obìnrin Midiani náà ni Simri, ọmọ Salu, olórí ilé kan nínú àwọn ọmọ Simeoni.
- Numeri 25:15nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Orúkọ ọmọbìnrin Midiani náà tí a pa ní Kosbi ọmọbìnrin Suri, tí ṣe olóyè àwọn ẹ̀yà kan nínú ìdílé kan ní Midiani.
- Numeri 25:16nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Olúwa sì tún sọ fún Mose pé,
- Numeri 25:17nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
“Ka àwọn ará Midiani sí ọ̀tá, kí o sì pa wọ́n,
- Numeri 25:18nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
nítorí pé wọ́n ṣe sí yín gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá nígbà tí wọ́n tàn yín nípa ìṣẹ̀lẹ̀ Peori, àti arábìnrin wọn Kosbi ọmọbìnrin ìjòyè Midiani kan, obìnrin tí a pa nígbà tí àjàkálẹ̀-ààrùn ṣẹlẹ̀ nítorí Peori.”
- Numeri 26:1nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Lẹ́yìn àjàkálẹ̀-ààrùn Olúwa sọ fún Mose àti Eleasari ọmọ Aaroni, àlùfáà pé,
- Numeri 26:2nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
“Ka iye gbogbo àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọ́n; láti ẹni ogun ọdún àti jù bẹ́ẹ̀ lọ tí ó lè jà lójú ogun ní Israẹli.”
- Numeri 26:3nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Lórí pẹ̀tẹ́lẹ̀ ti Moabu pẹ̀lú Jordani tí ó kọjá Jeriko, Mose àti Eleasari àlùfáà sọ̀rọ̀ pẹ̀lú wọn ó wí pé,
- Numeri 26:4nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
“Ka iye àwọn ọkùnrin tí ó jẹ́ ọmọ-ogun ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.” Èyí ni àwọn ọmọ Israẹli tí ó jáde láti Ejibiti wá.
- Numeri 26:5nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Àwọn ọmọ Reubeni, àkọ́bí ọmọkùnrin Israẹli, láti ẹni ti ìdílé Hanoku, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ìdílé Hanoku ti jáde wá, láti ìdílé Pallu, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ìdílé àwọn ọmọ Pallu ti jáde wá;
- Numeri 26:6nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
ti Hesroni, ìdílé àwọn ọmọ Hesroni; ti Karmi, ìdílé àwọn ọmọ Karmi.
- Numeri 26:7nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Reubeni; àwọn tí a sì kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlélógún ó lé lẹ́gbẹ̀sán ó dín àádọ́rin (43,730).
- Numeri 26:8nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Àwọn ọmọkùnrin Pallu ni Eliabu,
- Numeri 26:9nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
àwọn ọmọkùnrin Elifelehu ni Nemueli àti Eliabu, Datani àti Abiramu. Èyí ni Datani àti Abiramu náà tí wọ́n ní òkìkí nínú ìjọ tí ó jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ sí Mose àti Aaroni tí ó sì wà lára àwọn ẹgbẹ́ Kora nígbà tí wọ́n bá Olúwa jà.
- Numeri 26:10nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Ilẹ̀ sì la ẹnu rẹ̀, ó sì gbé wọn mì pọ̀ pẹ̀lú Kora, nígbà tí ẹgbẹ́ rẹ̀ kú níbi tí iná ti run àwọn àádọ́ta lé nígba (250) ọkùnrin. Tí wọ́n sì di àmì ìkìlọ̀.
- Numeri 26:11nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Àwọn ọmọ Kora, bí ó ti wù kí ó rí, wọn kò kú.
- Numeri 26:12nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Àwọn ọmọ ìran Simeoni bí ìdílé wọn: ti Nemueli, ìdílé Nemueli; ti Jamini, ìdílé Jamini; ti Jakini, ìdílé Jakini;
- Numeri 26:13nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
ti Sera, ìdílé Sera; tí Saulu, ìdílé Saulu.
- Numeri 26:14nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Simeoni, ẹgbẹ̀rún méjìlélógún ó lé igba (22,200) ọkùnrin.
- Numeri 26:15nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Àwọn ọmọ Gadi bí ìdílé wọn: ti Sefoni, ìdílé Sefoni; ti Haggi, ìdílé Haggi; ti Ṣuni, ìdílé Ṣuni;