Fò sí àkóónú

circa 1446–1406 BC

The Wilderness Years

Forty years of wandering in the desert test Israel's faith and prepare a new generation to enter the promised land.

2,247 ẹsẹ · 2 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Numeri 24:9nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Ó tẹríba ó sì dùbúlẹ̀ bí kìnnìún, bí abo kìnnìún: ta ni ó gbọdọ̀ jí wọn? “Ìbùkún ni fún ẹni tí ó bùkún fún ọ, kí ìfibú jẹ́ ti ẹni tí ó fi ọ́ bú!”

  2. Numeri 24:10nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni ìbínú Balaki sì dé sí Balaamu. Ó sì fi ọwọ́ lu ọwọ́ ó wí pé, “Mo pè ọ́ láti bú àwọn ọ̀tá mi ṣùgbọ́n o tún bùkún fún wọn nígbà mẹ́ta yìí.

  3. Numeri 24:11nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Nísinsin yìí sálọ sí ibùjókòó rẹ! Èmi ti rò láti sọ ọ́ di ẹni ńlá, ṣùgbọ́n Olúwa tí fà ọ́ sẹ́yìn láti gba èrè yìí.”

  4. Numeri 24:12nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Balaamu dá Balaki lóhùn, “Ǹjẹ́ èmi kò sọ fún àwọn ìránṣẹ́ tí o rán sí mi wí pé,

  5. Numeri 24:13nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    ‘Kódà bí Balaki bá fún mi ní ààfin rẹ̀ tí ó kún fún fàdákà àti wúrà, èmi kò le ṣe ohunkóhun lọ́wọ́ ara mi, yálà búburú tàbí rere, láti kọjá òfin Olúwa: ohun tí Olúwa bá wí ni èmi ó sọ’?

  6. Numeri 24:14nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Nísinsin yìí mò ń padà lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn mi, ṣùgbọ́n jẹ́ kí èmi kí ó kìlọ̀ fún ọ nítorí nǹkan tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí yóò ṣe sí àwọn ènìyàn rẹ ní ọjọ́ iwájú.”

  7. Numeri 24:15nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ òwe: “Òwe Balaamu ọmọ Beori, òwe ẹni tí ojú rẹ̀ ríran kedere,

  8. Numeri 24:16nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    ẹni tó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń wí, tí ó sì mọ ìmọ̀ Ọ̀gá-ògo, tí ó ríran láti ọ̀dọ̀ Olódùmarè, ẹni tí ó dọ̀bálẹ̀, tí ojú rẹ̀ sì ṣí:

  9. Numeri 24:17nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    “Mo rí i, ṣùgbọ́n kì í ṣe ìsinsin yìí. Mo kíyèsi, ṣùgbọ́n kò súnmọ́. Ìràwọ̀ kan yóò jáde láti ọ̀dọ̀ Jakọbu; yóò yọ jáde láti Israẹli. Yóò tẹ̀ fọ́ orí Moabu, yóò sì fọ́ agbárí gbogbo ọmọ Seti.

  10. Numeri 24:18nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Wọn yóò borí Edomu; yóò ṣẹ́gun Seiri ọ̀tá rẹ̀, ṣùgbọ́n Israẹli yóò dàgbà nínú agbára.

  11. Numeri 24:19nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Olórí yóò jáde láti Jakọbu yóò sì pa àwọn tó ṣẹ́kù nínú ìlú náà run.”

  12. Numeri 24:20nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Balaamu rí Amaleki ó sì bẹ̀rẹ̀ òwe: “Amaleki ni àkọ́kọ́ nínú àwọn orílẹ̀-èdè, ṣùgbọ́n yóò dahoro níkẹyìn.”

  13. Numeri 24:21nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ní ó rí ará Keni ó sì bẹ̀rẹ̀ òwe: “Ibùgbé rẹ ní ààbò, ìtẹ́ rẹ ni a tò sínú àpáta;

  14. Numeri 24:22nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    síbẹ̀ ẹ̀yin ará Keni ni yóò di píparun nígbà tí Asiria bá mú yín ní ìgbèkùn.”

  15. Numeri 24:23nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ òwe rẹ̀: “Háà, ta ni ó lè yè nígbà tí Ọlọ́run bá ṣe èyí?

  16. Numeri 24:24nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Ọkọ̀ yóò wá láti ibùdókọ̀ Kittimu; wọn yóò ṣẹ́gun Asiria àti Eberi, ṣùgbọ́n àwọn náà yóò di píparun.”

  17. Numeri 24:25nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Nígbà náà ni Balaamu dìde ó sì padà sí ilé rẹ̀, Balaki sì lọ ní ọ̀nà tirẹ̀.

  18. Numeri 25:1nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí àwọn Israẹli dúró ní Ṣittimu, àwọn ènìyàn sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àgbèrè pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin Moabu,

  19. Numeri 25:2nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    tí ó pè wọ́n sí ibi ẹbọ òrìṣà wọn. Àwọn ènìyàn náà jẹun wọ́n sì foríbalẹ̀ níwájú òrìṣà wọn.

  20. Numeri 25:3nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Báyìí ni Israẹli ṣe darapọ̀ mọ́ wọn tí wọ́n sì jọ ń sin Baali-Peori. Ìbínú Olúwa sì ru sí wọn.

  21. Numeri 25:4nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Olúwa sọ fún Mose pé, “Mú gbogbo àwọn olórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, pa wọ́n kí o sì fi wọ́n kọ́ sórí igi ní gbangba nínú oòrùn níwájú Olúwa, kí ìbínú Olúwa lè kúrò ní ọ̀dọ̀ Israẹli.”

  22. Numeri 25:5nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Mose sọ fún àwọn onídàájọ́ Israẹli, “Ẹnìkọ̀ọ̀kan yín gbọdọ̀ pa arákùnrin rẹ̀ èyí tí ó darapọ̀ ní fífi orí balẹ̀ fún Baali-Peori.”

  23. Numeri 25:6nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Nítòótọ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin Israẹli sì mú obìnrin Midiani wá síwájú ojú Mose àti gbogbo ìjọ ti Israẹli wọ́n sì ń sọkún ní àbáwọlé àgọ́ ìpàdé.

  24. Numeri 25:7nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí Finehasi, ọmọ Eleasari, ọmọ Aaroni, àlùfáà, rí èyí, ó fi ìjọ sílẹ̀, pẹ̀lú ọ̀kọ̀ ní ọwọ́ rẹ̀.

  25. Numeri 25:8nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Ó sì tẹ̀lé arákùnrin Israẹli yìí lọ sínú àgọ́. Ó sì fi ọ̀kọ̀ gún àwọn méjèèjì ní àgúnyọ láti ara ọkùnrin Israẹli àti sí ara obìnrin náà. Nígbà náà ni àjàkálẹ̀-ààrùn lórí àwọn ọmọ Israẹli sì dúró;