- English
- King James KJV
- Complete Jewish CJB
- World English WEBM
- Berean Standard BSB
- American Standard ASV
- Geneva GNV
- Young's Literal YLT
- Douay-Rheims DRC
- International
- Shqip ALB
- العربية SVD
- বাংলা BN-IRV
- မြန်မာ Judson
- 简体文 CUV-S
- 繁體中文 CUV-T
- Čeština BKR
- Nederlands STVE
- Français LSG
- Deutsch SCH
- Ελληνικά Vamvas
- ગુજરાતી GU-IRV
- Hausa HCB
- עברית Hebrew
- हिन्दी HCV
- Magyar KAROLI
- Bahasa Indonesia INDO-TB
- Italiano Diodati
- 日本語 Kougo
- 한국어 Korean
- മലയാളം MAL
- मराठी MRCV
- Norsk DNB
- فارسی OPV
- Polski BG
- Português Almeida
- Română Cornilescu
- Русский Synodal
- Español RVG
- Kiswahili Neno
- Svenska SV1917
- Tagalog TAG-ADB
- தமிழ் TCV
- తెలుగు TSA
- ภาษาไทย THAI-KJV
- Українська Ohienko
- Tiếng Việt CADMAN
- Yorùbá YCB
circa 1446–1406 BC
The Wilderness Years
Forty years of wandering in the desert test Israel's faith and prepare a new generation to enter the promised land.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Numeri 23:14nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Ó sì lọ sí pápá Sofimu ní orí òkè Pisga, ó sì kọ́ pẹpẹ méje síbẹ̀ ó sì fi akọ màlúù àti àgbò kọ̀ọ̀kan rú ẹbọ lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.
- Numeri 23:15nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Balaamu ṣo fún Balaki pé, “Dúró níbí ti ẹbọ sísun rẹ nígbà tí mo bá lọ pàdé rẹ̀ níbẹ̀.”
- Numeri 23:16nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Olúwa pàdé Balaamu ó sì fi ọ̀rọ̀ sí ní ẹnu wí pé, “Padà lọ sí ọ̀dọ̀ Balaki kí o sì jíṣẹ́ fún un.”
- Numeri 23:17nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ó lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ó sì bá à tí ó dúró ti ẹbọ sísun rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìjòyè Moabu. Balaki sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni Olúwa wí?”
- Numeri 23:18nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ó bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ sísọ, “Dìde, Balaki; kí o sì gbọ́ mi ọmọ Sippori.
- Numeri 23:19nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Ọlọ́run kì í ṣe ènìyàn, tí yóò fi purọ́, tàbí ọmọ ènìyàn, tí ó lè yí ọkàn rẹ̀ padà. Ǹjẹ́ ó sọ̀rọ̀ kí ó má ṣe é? Ǹjẹ́ ó ti ṣèlérí kí ó má mu un ṣẹ?
- Numeri 23:20nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Èmi gba àṣẹ láti bùkún; Ó sì ti bùkún, èmi kò sì lè yípadà.
- Numeri 23:21nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
“Kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kankan nínú Jakọbu, kò sì rí búburú kankan nínú Israẹli. Olúwa Ọlọ́run wọn sì wà pẹ̀lú wọn. Ìhó ọba sì wà pẹ̀lú wọn.
- Numeri 23:22nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Ọlọ́run mú wọn jáde láti Ejibiti wá, wọ́n ní agbára màlúù ẹhànnà.
- Numeri 23:23nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Kò ní àfọ̀ṣẹ sí Jakọbu, tàbí àfọ̀ṣẹ sí àwọn Israẹli. Nísinsin yìí a ó sọ nípa ti Jakọbu àti Israẹli, ‘Wo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe!’
- Numeri 23:24nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Àwọn ènìyàn náà yóò dìde bí abo kìnnìún; wọ́n yóò sì gbé ara wọn sókè bí i kìnnìún òun kì yóò sì dùbúlẹ̀ títí yóò fi jẹ ohun ọdẹ títí yóò sì fi mu nínú ẹ̀jẹ̀ ohun pípa.”
- Numeri 23:25nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni Balaki wí fún Balaamu pé, “O kò kúkú fi wọ́n bú, bẹ́ẹ̀ ni o kò súre fún wọn rárá!”
- Numeri 23:26nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Balaamu dáhùn ó sì wí fún Balaki pé, “Ǹjẹ́ èmi kò ha ti wí fún ọ pé, gbogbo èyí tí Olúwa bá sọ, òun ni èmi yóò ṣe?”
- Numeri 23:27nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Nígbà náà Balaki sọ fún Balaamu pé, “Wá jẹ́ kí èmi kí ó mú ọ lọ sí ibòmíràn bóyá yóò tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn kí ó fi wọ́n bú láti ibẹ̀ lọ.”
- Numeri 23:28nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Balaki gbé Balaamu wá sí orí òkè Peori, tí ó kọjú sí aginjù.
- Numeri 23:29nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Balaamu sì wí fún Balaki pé, “Mọ pẹpẹ méje fún mi níbí kí o sì pèsè akọ màlúù àti àgbò fún mi.”
- Numeri 23:30nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Balaki sì ṣe bí Balaamu ti sọ fún un, ó sì gbé akọ màlúù kan àti àgbò lórí pẹpẹ kọ̀ọ̀kan.
- Numeri 24:1nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Nísinsin yìí nígbà tí Balaamu rí i wí pé ó tẹ́ Olúwa lọ́rùn láti bùkún àwọn Israẹli, kò lo ọ̀nà ìṣoṣó gẹ́gẹ́ bí ti ìgbà ìṣáájú, ṣùgbọ́n ó yí ojú rẹ̀ sí apá aginjù.
- Numeri 24:2nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Nígbà tí Balaamu wo ìta ó sì rí Israẹli tí wọ́n pàgọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn, Ẹ̀mí Ọlọ́run sì bà sórí rẹ̀
- Numeri 24:3nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀, “Àsọtẹ́lẹ̀ tí Balaamu ọmọ Beori, àsọtẹ́lẹ̀ ẹni tí ojú rẹ̀ ríran kedere,
- Numeri 24:4nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
àsọtẹ́lẹ̀ ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí ó ríran láti ọ̀dọ̀ Olódùmarè, ẹni tí ó dojúbolẹ̀, tí ojú rẹ̀ là kedere.
- Numeri 24:5nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
“Àgọ́ rẹ ti dára tó, ìwọ Jakọbu, àti ibùgbé rẹ, ìwọ Israẹli!
- Numeri 24:6nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
“Gẹ́gẹ́ bí àfonífojì tí ó tàn jáde, gẹ́gẹ́ bí ọgbà tí ó wà ní ẹ̀bá odò ńlá, gẹ́gẹ́ bí igi aloe tí Olúwa gbìn, gẹ́gẹ́ bí igi kedari tí ó wà lẹ́bàá odò.
- Numeri 24:7nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Omi yóò sàn láti inú garawa: èso wọn yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi. “Ọba wọn yóò ga ju Agagi lọ; ìjọba wọn yóò di gbígbéga.
- Numeri 24:8nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
“Ọlọ́run mú wọn jáde láti Ejibiti wá; wọ́n ní agbára gẹ́gẹ́ bí i ti àgbáǹréré. Wọ́n jẹ orílẹ̀-èdè tí ń ṣe ọ̀tá rẹ̀ run, wọ́n sì fọ́ egungun wọn sí túútúú; wọ́n ó sì fi ọfà wọn ta wọ́n ní àtapòyọ.