Fò sí àkóónú

circa 1446–1406 BC

The Wilderness Years

Forty years of wandering in the desert test Israel's faith and prepare a new generation to enter the promised land.

2,247 ẹsẹ · 2 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Numeri 26:16nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    ti Osni, ìdílé Osni; ti Eri, ìdílé Eri;

  2. Numeri 26:17nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    ti Arodi, ìdílé Arodi; ti Areli, ìdílé Areli.

  3. Numeri 26:18nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Gadi tí iye wọn sì jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (40,500).

  4. Numeri 26:19nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọ Juda ni Eri àti Onani, ṣùgbọ́n Eri àti Onani kú ní ilẹ̀ Kenaani.

  5. Numeri 26:20nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Àti àwọn ọmọ Juda gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: ti Ṣela, ìdílé Ṣela; ti Peresi, ìdílé Peresi; ti Sera, ìdílé Sera.

  6. Numeri 26:21nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọ Peresi: ti Hesroni, ìdílé Hesroni; ti Hamulu, ìdílé Hamulu.

  7. Numeri 26:22nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Wọ̀nyí ni ìdílé Juda; gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá méjìdínlógójì ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (76,500).

  8. Numeri 26:23nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọ Isakari gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: ti Tola, ìdílé Tola; ti Pufa, ìdílé Pufa;

  9. Numeri 26:24nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    ti Jaṣubu, ìdílé Jaṣubu; ti Ṣimroni, ìdílé Ṣimroni.

  10. Numeri 26:25nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Wọ̀nyí ni ìdílé Isakari gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá méjìlélọ́gbọ̀n ó lé ọ̀ọ́dúnrún (64,300).

  11. Numeri 26:26nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọ Sebuluni gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: ti Seredi, ìdílé Seredi; ti Eloni, ìdílé Eloni; ti Jaleeli, ìdílé Jaleeli.

  12. Numeri 26:27nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Sebuluni gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn tí iye wọn sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ta ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (60,500).

  13. Numeri 26:28nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọ Josẹfu gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn; Manase àti Efraimu.

  14. Numeri 26:29nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọ Manase: ti Makiri, ìdílé Makiri (Makiri sì bí Gileadi); ti Gileadi, ìdílé àwọn ọmọ Gileadi.

  15. Numeri 26:30nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Gileadi: ti Ieseri, ìdílé Ieseri; ti Heleki, ìdílé Heleki

  16. Numeri 26:31nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    àti ti Asrieli, ìdílé Asrieli; àti ti Ṣekemu, ìdílé Ṣekemu;

  17. Numeri 26:32nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    àti Ṣemida, ìdílé àwọn ọmọ Ṣemida; àti ti Heferi, ìdílé àwọn ọmọ Heferi.

  18. Numeri 26:33nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    (Selofehadi ọmọ Heferi kò sì ni ọmọkùnrin, bí kò ṣe ọmọbìnrin; orúkọ àwọn ọmọbìnrin ni Mahila, Noa, àti Hogla, Milka àti Tirsa).

  19. Numeri 26:34nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Wọ̀nyí ni ìdílé Manase tí iye wọn sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (52,700).

  20. Numeri 26:35nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Efraimu gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: láti ọ̀dọ̀ Ṣutelahi, ìdílé àwọn ọmọ Ṣutelahi; ti Bekeri, ìdílé àwọn ọmọ Bekeri; ti Tahani, ìdílé àwọn ọmọ Tahani.

  21. Numeri 26:36nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Ṣutelahi: ti Erani, ìdílé àwọn ọmọ Erani.

  22. Numeri 26:37nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Efraimu, àwọn tí a kà nínú wọn sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlógún ó lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (32,500). Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Josẹfu gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn.

  23. Numeri 26:38nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọ Benjamini gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn nìyìí: tí Bela, ìdílé àwọn ọmọ Bela; ti Aṣbeli, ìdílé àwọn ọmọ Aṣbeli; ti Ahiramu, ìdílé àwọn ọmọ Ahiramu;

  24. Numeri 26:39nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    ti Ṣufamu, ìdílé àwọn ọmọ Ṣufamu; ti Hufamu, ìdílé àwọn ọmọ Hufamu.

  25. Numeri 26:40nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi

    Àwọn ọmọ Bela ní ipasẹ̀ Ardi àti Naamani nìyìí: ti Ardi, ìdílé àwọn ọmọ Ardi; ti Naamani, ìdílé àwọn ọmọ Naamani.