circa 1446–1406 BC
The Wilderness Years
Forty years of wandering in the desert test Israel's faith and prepare a new generation to enter the promised land.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Numeri 26:41nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Benjamini; gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn; àti àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá méjìlélógún ó lé ẹgbẹ̀jọ (45,600).
- Numeri 26:42nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Dani gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: ti Ṣuhamu, ìdílé àwọn ọmọ Ṣuhamu. Wọ̀nyí ni ìdílé Dani gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn.
- Numeri 26:43nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Gbogbo ìdílé àwọn ọmọ Ṣuhamu, gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá méjìlélọ́gbọ̀n ó lé irinwó (64,400).
- Numeri 26:44nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Ti àwọn ọmọ Aṣeri gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: ti Imina, ìdílé àwọn ọmọ Imina; ti Iṣfi, ìdílé àwọn ọmọ Iṣfi; ti Beriah, ìdílé àwọn ọmọ Berii.
- Numeri 26:45nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Ti àwọn ọmọ Beriah: ti Heberi, ìdílé àwọn ọmọ Heberi; ti Malkieli, ìdílé àwọn ọmọ Malkieli.
- Numeri 26:46nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
(Orúkọ ọmọ Aṣeri obìnrin nì jẹ́ Sera.)
- Numeri 26:47nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Aṣeri gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ó lé egbèje (53,400).
- Numeri 26:48nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Ti àwọn ọmọ Naftali gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: ti Jasieli, ìdílé àwọn ọmọ Jaseeli: ti Guni, ìdílé àwọn ọmọ Guni;
- Numeri 26:49nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
ti Jeseri, ìdílé àwọn ọmọ Jeṣeri; ti Ṣillemu, ìdílé àwọn ọmọ Ṣillemu.
- Numeri 26:50nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Wọ̀nyí ni ìdílé ti Naftali gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn, àwọn tí a kà nínú wọn jẹ́ ẹgbàá méjìlélógún ó lé egbèje (45,400).
- Numeri 26:51nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Àpapọ̀ iye tí a kà nínú àwọn ọmọ Israẹli jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó lé ẹgbẹ̀sán dín làádọ́rin (601,730).
- Numeri 26:52nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Olúwa sọ fún Mose pé,
- Numeri 26:53nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
“Ilẹ̀ náà gbọdọ̀ jẹ́ pínpín fún wọn gẹ́gẹ́ bí ogún wọn gẹ́gẹ́ bí iye orúkọ wọn.
- Numeri 26:54nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Fún àwọn ọ̀pọ̀ ni kí ìwọ ó fún ní ogún ìlú púpọ̀ àti fún àwọn tí ó kéré ni kí ìwọ ó fi kékeré fún, ẹnìkọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ gba ogún ìbí tirẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí a kọ.
- Numeri 26:55nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Rí dájú pé ilẹ̀ yìí gbọdọ̀ jẹ́ fífi ìbò pín gẹ́gẹ́ bí wọn sì ti pọ̀ tó. Gẹ́gẹ́ bí orúkọ ẹ̀yà àwọn baba wọn ni kí wọn kí ó ni í.
- Numeri 26:56nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Olúkúlùkù ogún ìní ni a gbọdọ̀ fi ìbò pín gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti pọ̀ tó láàrín ńlá àti kékeré.”
- Numeri 26:57nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Lefi tí a kà nínú wọn gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn: ti Gerṣoni, ìdílé àwọn ọmọ Gerṣoni; ti Kohati, ìdílé àwọn ọmọ Kohati; ti Merari, ìdílé àwọn ọmọ Merari.
- Numeri 26:58nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Wọ̀nyí ni ìdílé àwọn ọmọ Lefi; ìdílé àwọn ọmọ Libni, ìdílé àwọn ọmọ Hebroni, ìdílé àwọn ọmọ Mahili, ìdílé àwọn ọmọ Muṣi, ìdílé àwọn ọmọ Kora. (Kohati ni baba Amramu,
- Numeri 26:59nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
orúkọ aya Amramu sì ń jẹ́ Jokebedi, ọmọbìnrin Lefi, tí ìyá rẹ̀ bí fún Lefi ní Ejibiti. Òun sì bí Aaroni, Mose, àti Miriamu arábìnrin wọn fún Amramu.
- Numeri 26:60nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Aaroni ni baba Nadabu àti Abihu, Eleasari àti Itamari.
- Numeri 26:61nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n Nadabu àti Abihu kú, nígbà tí wọ́n rú ẹbọ níwájú Olúwa nígbà tí wọ́n mú iná àjèjì wá.)
- Numeri 26:62nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Gbogbo àwọn ọmọkùnrin Lefi láti oṣù kan àti ju bẹ́ẹ̀ lọ ẹgbẹ̀rún méjìlélógún ó lé lẹ́gbẹ̀rún (23,000). Wọn kò ka wọ́n mọ́ àwọn ọmọ Israẹli tókù nítorí tí wọ́n kò gba ogún ìní lára wọn.
- Numeri 26:63nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Àwọn wọ̀nyí ni Mose àti Eleasari àlùfáà kà nígbà tí wọ́n ka àwọn ọmọ Israẹli ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu lẹ́bàá odò Jordani létí Jeriko.
- Numeri 26:64nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Kò sí ẹnìkan nínú àwọn tí Mose àti Aaroni àlùfáà kà nígbà tí wọ́n ka àwọn ọmọ Israẹli ní aginjù Sinai.
- Numeri 26:65nǹkan bí 1452 ṣáájú Kristi
Nítorí Olúwa ti sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kíkú ni wọn yóò kú sí aginjù, kò sì sí ẹnìkankan nínú wọn tí kò kú àfi Kalebu ọmọ Jefunne, àti Joṣua ọmọ Nuni.