circa 800–400 BC
The Hebrew Prophets
God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.
Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí
- Jeremiah 39:7nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Nígbà náà ni ó fọ́ ojú Sedekiah, ó sì dè é pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n láti gbé e lọ sí ilẹ̀ Babeli.
- Jeremiah 39:8nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Àwọn Babeli dáná sun ààfin ọba àti ilé àwọn ènìyàn, wọ́n sì wó odi Jerusalẹmu.
- Jeremiah 39:9nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Nebusaradani olórí àwọn ọmọ-ogun mú lọ sí ìgbèkùn Babeli pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó ṣẹ́kù nínú ìlú.
- Jeremiah 39:10nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n Nebusaradani olórí ogun fi àwọn aláìní sílẹ̀ ní Juda, àwọn tí kò ní ohun kankan ní àkókò náà, ó fún wọn ní ọgbà àjàrà àti oko.
- Jeremiah 39:11nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Nísinsin yìí, Nebukadnessari ọba àwọn Babeli pàṣẹ lórí Jeremiah, láti ọ̀dọ̀ Nebusaradani olórí ogun wá wí pé:
- Jeremiah 39:12nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
“Ẹ gbé e, kí ẹ sì bojútó o. Ẹ má ṣe ṣe ohun búburú fún un, ṣùgbọ́n ohunkóhun tó bá béèrè ni kí ẹ fi fún un.”
- Jeremiah 39:13nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ pẹ̀lú, Nebusaradani balógun ìṣọ́, àti Nebusaradani olórí ìwẹ̀fà, àti Nergali-Ṣareseri, olórí amòye àti gbogbo àwọn ìjòyè ọba Babeli,
- Jeremiah 39:14nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
ránṣẹ́ láti mú Jeremiah kúrò nínú túbú. Wọ́n gbé e lọ fún Gedaliah ọmọ Ahikamu ọmọ Ṣafani láti mú padà lọ sí ilé àti máa wà pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀.
- Jeremiah 39:15nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Nígbà tí Jeremiah wà nínú túbú, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ ọ́ wá wí pé:
- Jeremiah 39:16nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
“Lọ sọ fún Ebedimeleki ará Kuṣi, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí: Èmi ṣetán láti mú ọ̀rọ̀ mi ṣẹ lórí ìlú yìí nípa àjálù kì í ṣe àlàáfíà. Ní àkókò náà ni yóò ṣẹ lójú rẹ.
- Jeremiah 39:17nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n, Èmi yóò gbà ọ́ lọ́jọ́ náà ni Olúwa wí. A kò ní fi ọ́ lé ọwọ́ àwọn tí o bẹ̀rù.
- Jeremiah 39:18nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Èmi yóò gbà ọ́ là; o kò ní ṣubú láti ipa idà; ṣùgbọ́n ìwọ yóò sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ, nítorí pé ìwọ ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú mi, ni Olúwa wí.’ ”
- Jeremiah 40:1nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Ọ̀rọ̀ náà sì tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa lẹ́yìn tí Nebusaradani balógun àwọn ẹ̀ṣọ́ ti tú u sílẹ̀ ní Rama. Ó rí Jeremiah tí a fi ẹ̀wọ̀n dè láàrín gbogbo àwọn tí wọ́n mú ní Jerusalẹmu àti Juda. Wọ́n kó lọ sí ilẹ̀ àjèjì Babeli.
- Jeremiah 40:2nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Nígbà tí balógun ẹ̀ṣọ́ rí Jeremiah, ó sọ fún un wí pé, “Olúwa Ọlọ́run rẹ ni ó pàṣẹ ibí yìí fún mi.
- Jeremiah 40:3nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Nísinsin yìí, Olúwa ti mú un jáde; ó ti ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ pé òun yóò ṣe. Gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ nítorí wí pé ẹ̀yin ènìyàn ṣẹ̀ sí Olúwa, àti pé ẹ kò gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ̀.
- Jeremiah 40:4nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Ṣùgbọ́n, ní òní yìí mò ń tú ọ sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀wọ̀n tí ó wà ní ọwọ́ rẹ. Bí o bá fẹ́, tẹ̀lé mi ká lọ sí Babeli, èmi yóò sì bojútó ọ; ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá fẹ́, dúró síbí. Wò ó, gbogbo orílẹ̀-èdè wà níwájú rẹ, lọ sí ibikíbi tí ó bá tẹ́ ọ lọ́rùn.”
- Jeremiah 40:5nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Ẹ̀wẹ̀, kí ó tó di pé Jeremiah pẹ̀yìndà láti máa lọ, Nebusaradani fi kún un wí pé, “Padà tọ Gedaliah ọmọ Ahikamu lọ, ọmọ Ṣafani, ẹni tí ọba Babeli ti fi jẹ baálẹ̀ lórí ìlú Juda, kí o sì máa gbé ní àárín àwọn ènìyàn wọ̀nyí tàbí kí o máa lọ ibikíbi tí ó bá tọ́ ní ojú rẹ.” Nígbà náà ni balógun náà fún un ní oúnjẹ àti ẹ̀bùn, ó sì jẹ́ kí ó lọ.
- Jeremiah 40:6nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Báyìí ni Jeremiah lọ sí ọ̀dọ̀ Gedaliah ọmọkùnrin Ahikamu ní Mispa, ó sì dúró tì í láàrín àwọn ènìyàn tí ó ṣẹ́kù ní ilẹ̀ náà.
- Jeremiah 40:7nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Nígbà tí gbogbo àwọn olórí ogun àti àwọn ènìyàn tí wọ́n kù lórí orílẹ̀-èdè náà gbọ́ pé ọba Babeli ti yan Gedaliah ọmọkùnrin Ahikamu gẹ́gẹ́ bí baálẹ̀ ní ilẹ̀ náà; àti pé ó ti fi àwọn ọkùnrin, obìnrin àti ọmọdé tí wọ́n jẹ́ tálákà ní ilẹ̀ náà tí wọn kò kó lọ sí ilẹ̀ àjèjì sí ìkáwọ́ rẹ̀,
- Jeremiah 40:8nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Gedaliah ní Mispa; Iṣmaeli ọmọkùnrin Netaniah, Johanani àti Jonatani ọmọkùnrin ti Karea, Seraiah ọmọkùnrin Tanhumeti tí í ṣe ọmọkùnrin Efai ará Netofa àti Jesaniah ọmọkùnrin Maakati àti àwọn ènìyàn wọn.
- Jeremiah 40:9nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Gedaliah ọmọkùnrin Ahikamu, ọmọkùnrin ti Ṣafani ṣe ìbúra láti tún fi dá àwọn ènìyàn lójú pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù láti sin àwọn Babeli.” Ó sọ wí pé, “Gbé ilẹ̀ náà kí ẹ sì máa sin ọba Babeli, yóò sì dára fún un yín.
- Jeremiah 40:10nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Èmi fúnra mi yóò dúró ní Mispa láti ṣojú yín níwájú Babeli tí wọ́n tọ̀ wá wá. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni yóò máa kórè ọtí wáìnì, èso igi àti òróró; kí ẹ sì kó wọn sí inú àpò àpamọ́wọ́ yín; kí ẹ̀yin sì máa gbé ní ìlú tí ẹ ti gbà.”
- Jeremiah 40:11nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Nígbà tí gbogbo àwọn Juda ní Moabu, Ammoni, Edomu àti gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè gbọ́ pé ọba Babeli ti fi ohun tókù sílẹ̀ ní Juda, àti pé ó ti yan Gedaliah ọmọkùnrin Ahikamu ọmọkùnrin Ṣafani gẹ́gẹ́ bí gómìnà lórí wọn.
- Jeremiah 40:12nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Gbogbo wọn padà wá sí ilẹ̀ Juda sọ́dọ̀ Gedaliah ní Mispa láti orílẹ̀-èdè gbogbo tí a ti lé wọn sí. Wọ́n sì kórè ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọtí wáìnì àti èso igi.
- Jeremiah 40:13nǹkan bí 588 ṣáájú Kristi
Johanani ọmọkùnrin ti Karea àti gbogbo àwọn olórí ogun tí ó kù ní orílẹ̀-èdè sì tọ Gedaliah wá ní Mispa.