Fò sí àkóónú

circa 800–400 BC

The Hebrew Prophets

God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.

3,706 ẹsẹ · 14 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Isaiah 16:11nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Ọkàn mi kérora fún Moabu gẹ́gẹ́ bí i dùùrù, àní tọkàntọkàn mi fún ìlú Kiri-Hareseti.

  2. Isaiah 16:12nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Nígbà tí Moabu farahàn ní ibi gíga rẹ̀, ó ṣe ara rẹ̀ ní wàhálà lásán; nígbà tí ó lọ sí ojúbọ rẹ̀ láti gbàdúrà òfo ni ó jásí.

  3. Isaiah 16:13nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ nípa Moabu.

  4. Isaiah 16:14nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Ṣùgbọ́n ní àkókò yìí Olúwa wí pé, “Láàrín ọdún mẹ́ta gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀fà tí ó wà lábẹ́ ìdè ọgbà rẹ̀ ti máa kà á, ògo Moabu àti àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn rẹ̀ ni a ó kẹ́gàn, àwọn tí ó sálà nínú rẹ̀ yóò kéré níye, wọn yóò sì jẹ́ akúrẹtẹ̀.”

  5. Isaiah 17:1nǹkan bí 741 ṣáájú Kristi

    Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Damasku: “Kíyèsi i, Damasku kò ní jẹ́ ìlú mọ́ ṣùgbọ́n yóò padà di ààtàn.

  6. Isaiah 17:2nǹkan bí 741 ṣáájú Kristi

    Àwọn ìlú Aroeri ni a ó kọ̀sílẹ̀ fún àwọn agbo ẹran tí yóò máa sùn síbẹ̀, láìsí ẹni tí yóò dẹ́rùbà wọ́n.

  7. Isaiah 17:3nǹkan bí 741 ṣáájú Kristi

    Ìlú olódi ni yóò pòórá kúrò ní Efraimu, àti agbára ọba kúrò ní Damasku; àwọn àṣẹ́kù Aramu yóò dá gẹ́gẹ́ bí ògo ti àwọn Israẹli,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

  8. Isaiah 17:4nǹkan bí 741 ṣáájú Kristi

    “Ní ọjọ́ náà ni ògo Jakọbu yóò sá; ọ̀rá ara rẹ̀ yóò ṣòfò dànù.

  9. Isaiah 17:5nǹkan bí 741 ṣáájú Kristi

    Yóò sì dàbí ìgbà tí olùkórè kó àwọn irúgbìn tí ó dúró jọ tí ó sì ń kórè irúgbìn pẹ̀lú apá rẹ̀— àti gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí ènìyàn pa ọkà ní àfonífojì ti Refaimu.

  10. Isaiah 17:6nǹkan bí 741 ṣáájú Kristi

    Síbẹ̀síbẹ̀ irúgbìn díẹ̀ yóò ṣẹ́kù, gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí a gbọn igi olifi, tí èso olifi méjì tàbí mẹ́ta ṣẹ́kù sórí ẹ̀ka tí ó ga jùlọ, mẹ́rin tàbí márùn-ún lórí ẹ̀ka tí ó so jù,” ni Olúwa wí, àní Ọlọ́run Israẹli.

  11. Isaiah 17:7nǹkan bí 741 ṣáájú Kristi

    Ní ọjọ́ náà, àwọn ènìyàn yóò gbójú sókè sí Ẹlẹ́dàá wọn, wọn yóò sì síjú wo Ẹni Mímọ́ Israẹli.

  12. Isaiah 17:8nǹkan bí 741 ṣáájú Kristi

    Wọn kò ní wo àwọn pẹpẹ mọ́, èyí tí í ṣe iṣẹ́ ọwọ́ wọn, wọn kò sì ní kọbi ara sí ère Aṣerah mọ́ tàbí pẹpẹ tùràrí tí ìka ọwọ́ wọn ti ṣe.

  13. Isaiah 17:9nǹkan bí 741 ṣáájú Kristi

    Ní ọjọ́ náà àwọn ìlú alágbára rẹ̀, yóò dàbí ẹ̀ka ìkọ̀sílẹ̀, àti ẹ̀ka téńté òkè tí wọ́n fi sílẹ̀ nítorí àwọn ọmọ Israẹli. Gbogbo wọn yóò sì di ahoro.

  14. Isaiah 17:10nǹkan bí 741 ṣáájú Kristi

    Nítorí ìwọ ti gbàgbé Ọlọ́run ìgbàlà rẹ; tí ìwọ kò sì náání àpáta ìgbàlà rẹ̀, nítorí náà ni ìwọ ti gbin ọ̀gbìn dáradára ìwọ sì tọ́ àjèjì ẹ̀ka sínú rẹ̀.

  15. Isaiah 17:11nǹkan bí 741 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà, bí ẹ tilẹ̀ mú àṣàyàn igi tí ẹ sì gbin àjàrà tí ó ti òkèrè wá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ tí ẹ kó wọn jáde ẹ mú wọn hù jáde, àti ní òwúrọ̀ tí ẹ gbìn wọ́n ẹ mú kí wọ́n rúdí, síbẹ̀síbẹ̀ ìkórè kò ní mú nǹkan wá ní ọjọ́ ààrùn àti ìrora tí kò gbóògùn.

  16. Isaiah 17:12nǹkan bí 741 ṣáájú Kristi

    Kíyèsi i, ìrunú àwọn orílẹ̀-èdè— wọ́n ń runú bí ìgbì Òkun! Kíyèsi i, rògbòdìyàn tí ogunlọ́gọ̀ ènìyàn wọ́n bú ramúramù gẹ́gẹ́ bí ariwo odò ńlá!

  17. Isaiah 17:13nǹkan bí 741 ṣáájú Kristi

    Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn ń bú ramúramù gẹ́gẹ́ bí ìrúmi odò, nígbà tí ó bá wọn wí wọ́n sálọ jìnnà réré, a tì wọ́n lọ gẹ́gẹ́ bí ìyàngbò ní orí òkè, àti gẹ́gẹ́ bí ewéko níwájú ìjì líle.

  18. Isaiah 17:14nǹkan bí 741 ṣáájú Kristi

    Ní aginjù, ìpayà òjijì! Kí ó tó di òwúrọ̀, a ò rí wọn mọ́! Èyí ni ìpín àwọn tí ó jí wa lẹ́rù, àti ìpín àwọn tí ó fi ogun kó wa.

  19. Isaiah 18:1nǹkan bí 714 ṣáájú Kristi

    Ègbé ni fún ilẹ̀ tí ó kún fún ariwo ìyẹ́ eṣú, ní àwọn ipadò Kuṣi,

  20. Isaiah 18:2nǹkan bí 714 ṣáájú Kristi

    tí ó rán àwọn ikọ̀ lórí Òkun lórí omi nínú ọkọ̀-ọpọ́n tí a fi eèsún papirusi ṣe. Ẹ lọ, ẹ̀yin ikọ̀ tí ó yára, sí àwọn ènìyàn gíga tí àwọ̀ ara wọn jọ̀lọ̀, sí àwọn ènìyàn tí a ń bẹ̀rù káàkiri, orílẹ̀-èdè aláfojúdi alájèjì èdè, tí odò pín ilẹ̀ rẹ̀ yẹ́lẹyẹ̀lẹ.

  21. Isaiah 18:3nǹkan bí 714 ṣáájú Kristi

    Gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ayé, tí ó ń gbé orílẹ̀ ayé, nígbà tí a bá gbé àsíá kan sókè lórí òkè, ẹ ó rí i, nígbà tí a bá fun fèrè kan ẹ ó gbọ́ ọ.

  22. Isaiah 18:4nǹkan bí 714 ṣáájú Kristi

    Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi: “Èmi yóò dákẹ́ jẹ́ẹ́, èmi yóò sì máa wo òréré láti ibùgbé e mi wá, gẹ́gẹ́ bí ooru gbígbóná nínú ìtànṣán oòrùn, gẹ́gẹ́ bí òjò-dídì ní àárín gbùngbùn ìkórè.”

  23. Isaiah 18:5nǹkan bí 714 ṣáájú Kristi

    Nítorí, kí ìkórè tó bẹ̀rẹ̀, nígbà tí ìrudí bá kún, nígbà tí ìtànná bá di èso àjàrà pípọ́n. Òun yóò sì fi dòjé rẹ́ ẹ̀ka tuntun, yóò sì mu kúrò, yóò sì gé ẹ̀ka lulẹ̀.

  24. Isaiah 18:6nǹkan bí 714 ṣáájú Kristi

    A ó fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn ẹyẹ òkè ńlá àti fún àwọn ẹranko búburú; àwọn ẹyẹ yóò fi wọ́n ṣe oúnjẹ nínú ẹ̀ẹ̀rùn àti àwọn ẹranko búburú nígbà òjò.

  25. Isaiah 18:7nǹkan bí 714 ṣáájú Kristi

    Ní àkókò náà ni a ó mú ẹ̀bùn wá fún Olúwa àwọn ọmọ-ogun láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn gíga tí ẹran-ara wọn jọ̀lọ̀, láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí a bẹ̀rù níbi gbogbo, orílẹ̀-èdè aláfojúdi àti alájèjì èdè, ilẹ̀ ẹni tí omi pín sí yẹ́lẹyẹ̀lẹ— a ó mú àwọn ẹ̀bùn náà wá sí òkè Sioni, ibi tí orúkọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun gbé wà.