Fò sí àkóónú

circa 800–400 BC

The Hebrew Prophets

God speaks through Isaiah, Jeremiah, and the minor prophets—calling Israel to repentance and foretelling the coming Messiah.

3,706 ẹsẹ · 14 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti pète, ta ni yóò sì ká a lọ́wọ́ kò? Ọwọ́ọ rẹ ti nà jáde, ta ni ó sì le è fà á padà?

  2. Isaiah 14:28nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ yí wá ní ọdún tí ọba Ahasi kú.

  3. Isaiah 14:29nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Má ṣe yọ̀, gbogbo ẹ̀yin Filistia, pé ọ̀pá tí ó lù ọ́ ti dá; láti ibi gbòǹgbò ejò náà ni paramọ́lẹ̀ yóò ti hù jáde, èso rẹ̀ yóò sì jẹ́ oró ejò tí í jóni.

  4. Isaiah 14:30nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Ẹni tí ó kúṣẹ̀ẹ́ jù yóò ní pápá oko, àwọn aláìní yóò sì dùbúlẹ̀ láìléwu. Ṣùgbọ́n gbòǹgbò o rẹ̀ ni èmi ó fi ìyàn parun, yóò sì ké àwọn ẹni rẹ tí ó sálà kúrò.

  5. Isaiah 14:31nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Hu, ìwọ ẹnu-ọ̀nà! Kígbe, ìwọ ìlú! Yọ́ kúrò, gbogbo ẹ̀yin Filistia! Èéfín kurukuru kan ti àríwá wá, kò sì ṣí amóríbọ́ kan nínú ẹgbẹ́ wọn.

  6. Isaiah 14:32nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Kí ni ìdáhùn tí a ó fún agbẹnusọ orílẹ̀-èdè náà? “Olúwa ti fi ìdí Sioni kalẹ̀, àti nínú rẹ̀ ni àwọn ènìyàn rẹ̀ tí a ti pọ́n ọn lójú yóò ti rí ààbò o wọn.”

  7. Isaiah 15:1nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Moabu, a pa Ari run ní Moabu, òru kan ní a pa á run! A pa Kiri run ní Moabu, òru kan ní a pa á run!

  8. Isaiah 15:2nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Diboni gòkè lọ sí tẹmpili rẹ̀, sí àwọn ibi gíga rẹ̀ láti sọkún, Moabu pohùnréré lórí Nebo àti Medeba. Gbogbo orí ni a fá gbogbo irùngbọ̀n ni a gé dànù.

  9. Isaiah 15:3nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀ ní ojú òpópónà, ní àwọn òrùlé àti àwọn gbàgede ìlú. Wọ́n pohùnréré, wọ́n dọ̀bálẹ̀ pẹ̀lú ẹkún.

  10. Isaiah 15:4nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Heṣboni àti Eleale ké sóde, ohùn wọn ni a gbọ́ títí fi dé Jahasi. Nítorí náà ni àwọn ọmọ-ogun Moabu ṣe kígbe tí ọkàn wọn sì rẹ̀wẹ̀sì.

  11. Isaiah 15:5nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Ọkàn mi kígbe sókè lórí Moabu; àwọn ìsáǹsá rẹ sálà títí dé Soari, títí fi dé Eglati-Ṣeliṣi. Wọ́n gòkè lọ títí dé Luhiti wọ́n ń sọkún bí wọ́n ti ń lọ, ní òpópónà tí ó lọ sí Horonaimu wọ́n ń pohùnréré ìparun wọn.

  12. Isaiah 15:6nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Gbogbo omi Nimrimu ni ó ti gbẹ àwọn koríko sì ti gbẹ, gbogbo ewéko ti tán ewé tútù kankan kò sí mọ́.

  13. Isaiah 15:7nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Báyìí gbogbo ọrọ̀ tí wọ́n ti ní tí wọ́n sì tò jọ wọ́n ti kó wọn kọjá lọ lórí i gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ odò Poplari.

  14. Isaiah 15:8nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Gbohùngbohùn ń gba igbe wọn dé ìpẹ̀kun ilẹ̀ Moabu; ìpohùnréré wọn lọ títí dé Eglaimu, igbe ẹkún wọn ni a gbọ́ títí dé kànga Elimu.

  15. Isaiah 15:9nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Omi Dimoni kún fún ẹ̀jẹ̀, síbẹ̀ èmi ó tún mu ohun tí ó jù báyìí lọ wá sórí Dimoni— kìnnìún kan wá sórí àwọn ìsáǹsá Moabu àti lórí àwọn tí ó tún ṣẹ́kù sórí ilẹ̀ náà.

  16. Isaiah 16:1nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Fi ọ̀dọ́-àgùntàn ṣe ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí aláṣẹ ilẹ̀ náà, láti Sela, kọjá ní aginjù, lọ sí orí òkè ọ̀dọ́mọbìnrin Sioni.

  17. Isaiah 16:2nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Gẹ́gẹ́ bí alárìnkiri ẹyẹ tí a tì jáde kúrò nínú ìtẹ́, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwọn obìnrin Moabu ní àwọn ìwọdò Arnoni.

  18. Isaiah 16:3nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    “Fún wa ní ìmọ̀ràn ṣe ìpinnu fún wa. Jẹ́ kí òjìji rẹ dàbí òru, ní ọ̀sán gangan. Fi àwọn ìsáǹsá pamọ́, má ṣe fi àwọn aṣàtìpó han.

  19. Isaiah 16:4nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Jẹ́ kí àwọn ìsáǹsá Moabu gbé pẹ̀lú rẹ, jẹ́ ààbò fún wọn kúrò lọ́wọ́ ìparun.” Aninilára yóò wá sí òpin, ìparun yóò dáwọ́ dúró; òfinràn yóò pòórá kúrò lórí ilẹ̀.

  20. Isaiah 16:5nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Nínú ìfẹ́ a ó fi ìdí ìjọba kan múlẹ̀, ní òdodo ọkùnrin kan yóò jókòó lórí rẹ̀ ẹnìkan láti ilé Dafidi wá. Ẹni yóò ṣe ìdájọ́, yóò sì máa wá ìdájọ́, yóò sì máa yára wá ohun tí í ṣe òdodo.

  21. Isaiah 16:6nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Àwa ti gbọ́ nípa ìgbéraga Moabu, ìwọ̀sí ìgbéraga rẹ̀ àti fùlenge fùlenge, gààrù rẹ̀ àti àfojúdi rẹ̀, ṣùgbọ́n ìfọ́nnu rẹ̀ jẹ́ ìmúlẹ̀mófo.

  22. Isaiah 16:7nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà ni àwọn ará Moabu hu, wọ́n jùmọ̀ hu lórí Moabu. Sọkún kí o sì banújẹ́ fún àkàrà díndín Kiri-Hareseti.

  23. Isaiah 16:8nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Gbogbo pápá oko Heṣboni ti gbẹ, bákan náà ni àjàrà Sibma rí. Àwọn aláṣẹ àwọn orílẹ̀-èdè wọ́n tẹ àwọn àyànfẹ́ àjàrà mọ́lẹ̀, èyí tí ó ti fà dé Jaseri ó sì ti tàn dé agbègbè aginjù. Àwọn èhíhù rẹ̀ fọ́n jáde, ó sì lọ títí ó fi dé Òkun.

  24. Isaiah 16:9nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Nítorí náà mo sọkún, gẹ́gẹ́ bí Jaseri ṣe sọkún, fún àwọn àjàrà Sibma. Ìwọ Heṣboni, ìwọ Eleale, mo bomirin ọ́ pẹ̀lú omi ojú! Igbe ayọ̀ lórí àwọn èso pípọ́n rẹ àti lórí ìkórè èyí tí o ti mọ́wọ́ dúró.

  25. Isaiah 16:10nǹkan bí 726 ṣáájú Kristi

    Ayọ̀ àti ìdùnnú ni a ti mú kúrò nínú ọgbà-igi eléso rẹ; kò sí ẹnìkan tí ó kọrin tàbí kígbe nínú ọgbà àjàrà: ẹnikẹ́ni kò fún ọtí níbi ìfúntí, nítorí mo ti fi òpin sí gbogbo igbe.