Fò sí àkóónú

circa 1446 BC

Sinai & The Law

God meets Israel at Mount Sinai, reveals the Ten Commandments, and establishes the Tabernacle and the priestly covenant.

1,657 ẹsẹ · 2 ìwé tí a bo

Àwọn ẹsẹ láti sáà yìí

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Eksodu 36:32nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    márùn-ún fún àwọn tí ó wà ní ìhà kejì, márùn-ún fún pákó tí ó wà ní ìhà ìwọ̀-oòrùn ní ìkangun àgọ́ náà.

  2. Eksodu 36:33nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Wọ́n sì ṣe ọ̀pá àárín tí yóò fi jáde láti ìkangun dé ìkangun ní àárín àwọn pákó náà.

  3. Eksodu 36:34nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ó sì bo àwọn pákó pẹ̀lú wúrà, wọ́n sì ṣe àwọn òrùka wúrà láti gbá ọ̀pá náà mú. Wọ́n sì tún bo ọ̀pá náà pẹ̀lú wúrà.

  4. Eksodu 36:35nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ó ṣe aṣọ títa aláró, àti elése àlùkò, àti òdòdó, àti ọ̀gbọ̀ olókùn wẹ́wẹ́ tí í ṣe ọlọ́nà, tí òun ti àwọn kérúbù ni kí á ṣe é.

  5. Eksodu 36:36nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Wọ́n sì ṣe òpó igi ṣittimu mẹ́rin fún un wọ́n sì bò wọ́n pẹ̀lú wúrà. Wọ́n sì ṣe àwọn ìkọ́ wúrà fún wọn, wọ́n sì dá ihò ìtẹ̀bọ̀ fàdákà mẹ́rin mẹ́rin fún wọn.

  6. Eksodu 36:37nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Fún ẹnu-ọ̀nà àgọ́ náà wọ́n ṣe aṣọ títa ti aṣọ aláró, ti elése àlùkò, ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára tí a fi iṣẹ́ abẹ́rẹ́ ṣe;

  7. Eksodu 36:38nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ó sì ṣe òpó márùn-ún pẹ̀lú ìkọ́ wọn. Ó bo orí àwọn òpó náà àti ìgbànú wọn pẹ̀lú wúrà, ó sì fi idẹ ṣe ihò ìtẹ̀bọ̀ wọn márààrún.

  8. Eksodu 37:1nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Besaleli sì fi igi ṣittimu ṣe àpótí náà, ìgbọ̀nwọ́ méjì ààbọ̀ ni gígùn rẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ni fífẹ̀ rẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ni gíga rẹ̀.

  9. Eksodu 37:2nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ó sì fi ojúlówó wúrà bò ó ní inú àti ní òde, ó sì fi wúrà gbá etí rẹ̀ yíká.

  10. Eksodu 37:3nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ó sì da òrùka wúrà mẹ́rin fún, láti fi wọ́n sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ẹsẹ̀ rẹ̀, òrùka wúrà méjì yóò wà ní ẹ̀gbẹ́ kìn-ín-ní, òrùka wúrà méjì yóò wà ní ẹgbẹ́ kejì.

  11. Eksodu 37:4nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ó sì fi igi kasia ṣe ọ̀pá, ó sì fi wúrà bò wọ́n.

  12. Eksodu 37:5nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ó sì fi ọ̀pá náà bọ òrùka ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan àpótí ẹ̀rí náà láti fi gbé e.

  13. Eksodu 37:6nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ó fi ojúlówó wúrà ṣe ìtẹ́ àánú; ìgbọ̀nwọ́ méjì àti ààbọ̀ ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ní fífẹ̀.

  14. Eksodu 37:7nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ó sì ṣe kérúbù méjì láti inú wúrà tí a fi òòlù sí igun ìtẹ́ àánú náà.

  15. Eksodu 37:8nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ó ṣe kérúbù kan ní igun kìn-ín-ní, àti kérúbù kejì sí igun kejì; kí kérúbù náà jẹ́ irú kan náà ní igun méjèèjì pẹ̀lú ìbòrí wọn.

  16. Eksodu 37:9nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Àwọn kérúbù sì na ìyẹ́ apá wọn sókè, tí wọn yóò sì fi ìyẹ́ apá wọn ṣe ibòòji sí orí ìtẹ́ àánú. Àwọn kérúbù náà yóò kọ ojú sí ara wọn, wọn yóò máa wo ọ̀kánkán ìtẹ́.

  17. Eksodu 37:10nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ó ṣe tábìlì igi ṣittimu ìgbọ̀nwọ́ méjì ní gígùn, ìgbọ̀nwọ́ kan ní fífẹ̀, àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ní gíga.

  18. Eksodu 37:11nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ó sì fi ojúlówó wúrà bò ó, ó sì ṣe ìgbátí wúrà yí i ká.

  19. Eksodu 37:12nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ó sì ṣe etí kan ní ìbú àtẹ́lẹwọ́ sí i yíká, ó sì ṣe ìgbátí wúrà yí etí rẹ̀ ká.

  20. Eksodu 37:13nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ó sì da òrùka wúrà mẹ́rin fún tábìlì náà, ìwọ ó sì fi òrùka kọ̀ọ̀kan sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ó wà ní ẹsẹ̀ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin.

  21. Eksodu 37:14nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ní abẹ́ ìgbátí náà ni àwọn òrùka náà yóò wà, ààyè láti máa fi gbé tábìlì náà.

  22. Eksodu 37:15nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ó sì fi igi kasia ṣe àwọn ọ̀pá, ó sì fi wúrà bò wọ́n, láti máa fi wọ́n gbé tábìlì náà.

  23. Eksodu 37:16nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ó sì ṣe àwọn ohun èlò tí ó wà lórí tábìlì náà ní ojúlówó wúrà, abọ́ rẹ̀, àwo rẹ, àwokòtò rẹ̀ àti ìgò rẹ̀ fún dída ọrẹ mímu jáde.

  24. Eksodu 37:17nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ó sì ṣe ọ̀pá fìtílà náà ní ojúlówó wúrà, ó sì lù ú jáde, ọ̀pá rẹ̀, ìtànná ìfẹ́ rẹ̀, ìrudí rẹ àti agogo rẹ̀, wọ́n jẹ́ ọ̀kan náà.

  25. Eksodu 37:18nǹkan bí 1491 ṣáájú Kristi

    Ẹ̀ka mẹ́fà ni yóò yọ ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀pá fìtílà: mẹ́ta ní ẹ̀gbẹ́ kìn-ín-ní mẹ́ta ni ẹ̀gbẹ́ kejì.